Gbígba àláfíà àti ìṣọ̀kan láàyè láàárín ọmọ Yorùbá ló lè mú wa borí ìpèníjà Naijiria – Ooni Ile Ife

Aworan Ooni of Ile Ife
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi ti gba gbogbo ọmọ Yoruba ni imọran lati gba alaafia ati ìṣọ̀kan laaye ki iṣoro to n doju kọ Naijiria ko dohun igbagbe.

Lasiko ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ to waye lọjọ Abameta ni Ooni ti sọrọ naa.

Ọba Adeyeye Ogunwusi ni o ṣe pataki fun ọmọ Yoruba lati gbe aṣa ati ẹṣin adayeba lárugẹ, e yii yoo le ran wa lọwọ lati gba alaafia ati ìṣọ̀kan laaye ni Naijiria ati ni gbogbo agbaye.

Maa ma wa si ọdun Ọlọjọ lati gbe aṣa larugẹ - Gomina Adeleke

Nigba ti Gomina Ademola Adeleke n sọrọ nibi ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ naa, o bere fun alaafia nipinlẹ Ọsun.

Gomina Ademola Adeleke wa ṣeleri wi pe, oun yoo maa yọju sibi ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ lati le tun gbe asa ati ẹṣin ilẹ Yoruba lárugẹ.

Oladotun Hassan, ẹni to jẹ Aarẹ fun itesiwaju Yoruba agbaye naa ti bere fun ìṣọ̀kan ọmọ Yoruba lati le bori ilakoja to le ti ọmọ orile-ede Naijiria dojú kọ lasiko yii.

Hassan tun bere fun ifowosowopo Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lati le ri wi pe o gbe Naijiria kuro ninu wahala.

Ki ni pataki ọdun Ọlọjọ?

Aworan

Ifagbenusola Atanda, ẹni to jẹ aṣiwaju awo agbaye sọ pataki ati bi ọdun Ọlọjọ ṣe bẹrẹ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọdun Ọlọjọ jẹ ọdun abalaye, bẹẹ si ni o jẹ ọdun ti Yoruba gbagbọ wí pe o jẹ ọjọ idupẹ fun gbogbo ọmọ Oduduwa lapapọ.

Bakan naa ni wọn fi ọdun Ọlọjọ ṣe iranti akọni ti wọn n pe orúkọ rẹ ni Ogun to jẹ olulana ati ọkan lara ọmọ Oduduwa.

Ọdun Ọlọjọ ti bẹrẹ lati igba ti aye ti bẹrẹ, bẹẹ si ni Olodumare bẹrẹ aye ni Ile Ife.

Ọdun Ọlọjọ jẹ ọdun ti wọn n fi da aṣa Yoruba pada ati lati fi da isọkàn pada si aarin ọmọ Yoruba lapapọ.

O tun jẹ ọdun ti o yẹ ki gbogbo ọmọ bibi ilẹ Yoruba ko mọ riri oun ti Olodumare se fun gbogbo ọmọ Yoruba.