Ò ṣeé ṣe kí òṣùpá míì yọ lójú sánmọ̀ láìpẹ́ - Àwọn onímọ̀ ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Maddie Molloy
- Role, BBC Climate & Science
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Ẹ gbaradi fun ohun iyalẹnu nibi to ti ṣee ṣe ki oṣupa kekere mi yọ loju sanmọ laipẹ.
Osupa Asteroid ni a le pe oṣupa kekere.
Alejo aaye yii yoo wa ni ayika bẹrẹ lati ọjọ kọkandinlọgbọn Oṣu Kẹsan fun ọpọ oṣu diẹ ṣaaju ki o to parẹ kuro loju sanmọ lẹẹkansi.
Sugbọn, o dun ni pupọ pe oṣupa keji yoo kere pupọ, ti oju lasan ko si ni le ri ayafi ti eeyan ba lo ẹrọ a gbe nnkan sun mọ ẹni.
Oṣupa kekere yii ni ajọ NASA kọkọ ṣawari ni ọjọ keje oṣu kẹjọ.
Oṣupa kerere Asteriod yii ni awọn omimọ Sayẹnsi n pe ni 2024 PTS, to wa lati Arjuna asteroid, nibi ti ọpọ apata pọ si.
Dokita Jenniefer Millard, on imọ nipa Asteroid sọ fun BBC pe oṣupa kekere naa yoo bọ soju samọ ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹsan an, ti wọn si gbagbọ pe o kuro ni ọjọ kẹdọgbọn oṣu kọkanla.
Oṣupa yii lo kere ni mita mẹwaa, to si kere, ti ko to oṣupa ti a mọ tẹlẹ ati bi o ṣe kere yii, oju lasan ko ri oṣupa naa.
Ki se igba akọkọ ri irufẹ oṣupa yoo jade sita, ti igbagbọ si wa pe ọpọ irufẹ oṣupaa bẹ lo ti jade ti ẹnikẹni ko mọ.
Ma se ba inu jẹ ti o ko ba ri oṣupa, igbagbọ wa pe oṣupa naa yoo tun pada ni ọdun 2055















