"Mo gbàdúrà pé kí n jẹ́ ẹlẹ́mìí gígùn, kí ń le è máa ṣe àwọn nǹkan mèremère ní orúkọ bàbá mi" - Rukayat Gawat

Aworan Rukayat Gawat

Oríṣun àwòrán, Rukayat Gawat/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Akọrin ẹmi musulumi Rukayat Gawat Oyefeso tó di olóògbé sọ oriṣiiriṣii ọ̀rọ̀ ṣaájú nípa bàbá rẹ̀ láì mọ̀ pé kò ní pẹ́ tóun náà fi máa dágbere fáyé.

Rukaya sọ nínú fídíò kan tó fi léde lójú òpó Instagram rẹ̀ pé lásìkò tí òun fẹ́ kírun lọ́jọ́ Kẹwàá, oṣù Keje ọdún 2012 ni wọ́n pe oun pé wọn kò rí bàbá òun di awati.

Ó fi kun pé àwọn èèyàn pé nọ́ḿbà bàbá òun títí àmọ́ àlọ ni àwọn rí tí àwọn kò rí àbọ̀ rẹ̀.

Ó sọ pé lẹ́yìn ọdún mẹ́rin tí àwọn kò rí bàbá òun, ni àwọn ṣe àdúrà fidau fún ní ìlànà ẹ̀sìn Islam.

“Ní ọdọọdún ni mo máa ń ṣe ìtọrẹ àánú fún àwọn opó àti aláìní ni orúkọ Baba mi.”

Ó ní òun ti pinnu pé ní gbogbo ọdún, tí Ọlọ́run bá dá ẹ̀mí òun sí, tí ẹ̀mí òun bá gùn, ní òun yóò máa ṣe nǹkan ní orúkọ Baba òun

Ó ní òun gbàdúrà ṣe òun ní ẹlẹ́mìí gígùn kí òun lè máa ṣe àwọn nǹkan mèremère ní orúkọ rẹ̀.

Ó jọ pé bàbá mi ti mọ́ pe òun máa di àwátì lọ́dún méjìlá sẹ́yìn torí àwọn ìṣesí rẹ̀ mú ìfura lọ́wọ́ - Rukayat Gawat

Rukayat Gawat

Oríṣun àwòrán, iamrukayatgawat/Instagram

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Kẹsàn-án ọdún 2024 ni ìròyìn ikú gbajúmọ̀ akọrin ẹ̀mí ẹ̀sìn Islam, Alhaja Rukayat Gawat Osifeso gbòde.

Níṣe ni ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ akọrin náà gbọgbẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà táwọn èèyàn sì ń kọminú lórí ohun tó ṣokùnfà ikú òjijì ọ̀hún.

Ní ìlú Ijebu Ayepe ní ìpínlẹ̀ Ogun tó jẹ́ ìlú ọkọ Rukayat Gawat ni wọ́n sin òkú rẹ̀ sí lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun kan náà.

Rukayat Gawat Osifeso di gbajúmọ̀ akọrin ẹ̀mí ẹ̀sìn Islam lẹ́yìn àwo orin tó ṣe fun bàbá rẹ̀, Alhaji Rasak Aremu Gawat nígbà tó ṣàdédé di àwátì lọ́jọ́ Kẹwàá, oṣù Keje, ọdún 2012.

Nígbà tó ń kópa lórí ètò Gbajúmọ̀ tí Doyin Kukoyi jẹ́ olóòtù rẹ̀ lọ́dún 2016, Rukayat ṣàlàyé bó ṣe bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé rẹ̀ pẹ̀lú bàbá rẹ̀ ní Lagos Island, ìpínlẹ̀ Eko.

Ó ní láti ọdún 1993 tí òun wọ ilé ẹ̀kọ́ girama ni òun ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kọrin níbi àwọn ètò ìjọ ẹ̀sìn Islam káàkiri kó tó di wí pé òun mú orin níṣẹ́ lẹ́yìn tí òun parí ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì.

Ó ṣàlàyé pé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ “Mass Communication” ni òun kà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Olabisi Onabanjo tó wà ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Ó sọ pé lọ́pọ̀ ìgbà tí òun bá fẹ́ gbé orin jáde ní òun máa ń ronú nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ, tí òun yóò sì fi gbé orin jáde.

Akọrin náà ni òun máa ń fẹ́ràn láti fi orin kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n ba à lè rí nǹkan mú nínú rẹ̀.

'Ó jọ pé bàbá mi ti mọ̀ nnkan máa ṣe òun kó tó di àwátì'

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bí bàbá rẹ̀ ṣe di àwátì, Rukayat Gawat Osifeso ní ó jọ wí pé bàbá òun ti mọ̀ pé nǹkan máa ṣẹlẹ̀ sí òun àmọ́ tí kò lè sọ nǹkan náà.

Ó ṣàlàyé pé láti ìgbà tí òun ti fẹ́ ṣe ìgbéyàwó lọ́jọ́ kìíní oṣù Kẹta, ọdún 2012 ni òun ti ń rí àwọn ìṣeṣí tó mú ìfura dání lára bàbá òun àmọ́ tí òun kò ka àwọn nǹkan náà kún.

Akọrin náà ní bàbá òun pọn ọ́n ní dandan fún òun pé ọjọ́bọ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ ni kí òun ṣe ìgbéyàwó.

“Bàbá mi pè mí ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ẹtì, tó jẹ́ ọjọ́ kejì tí mo ṣe ìgbéyàwó pé àwọn kò fẹ́ ki máa jáde títí tí mà á fi bímọ nítorí mó fi oyún ṣe ìgbéyàwó ni.

“Mi ò ti ẹ̀ ka ọ̀rọ̀ náà kún rárá nítorí èmi náà fẹ́ fi àkókò náà sinmi àmọ́ nígbà tí mo bímọ tán, àwọn ni ẹni àkọ́kọ́ tí mo kọ́kọ́ pé.

“Bàbá mi sọ pé tí mi ò bá ṣe nǹkan mìíràn mi láyé mi, mo dúpẹ́ pé Rukayat bímọ lójú ẹ̀mí mi.”

Ó ní òun kò ka ọ̀rọ̀ náà kún rárá nítorí òun kò ro aburú ro bàbá òun.

Rukayat ní lọ́jọ́ tí àwọn ń ṣe ìsọmọlórúkọ ni bàbá òun sọ ọmọ ní oríkì rẹ̀ gan-an.

“Bàbá mi fún Imam Ebute Metta ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún náírà pé kí wọ́n sọ ọmọ mi ní Aremu.

“Ó sọ fún àwọn Alfa náà pé tí ọmọ mi bá ti dàgbà, kí wọn sọ fún un pé bàbá ìyá rẹ̀ ló sọ ọ́ ní Aremu.”

“Imam Ebute Metta fèsì padà fún bàbá mi pé Alhaji Gawat, ẹ̀yin náà lẹ má sọ fún àmọ́ ó ní tí a bá ṣì wà, Ọlọ́run a wò ó.”

Rukayat Gawat Osifeso ní àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni òun wá ń rántí lẹ́yìn tí bàbá òun di àwátì.

Rukayat Gawat Osifeso

Oríṣun àwòrán, iamrukayatgawat/Instagram

"Mo gbàdúrà pé kí n jẹ́ ẹlẹ́mìí gígùn, kí ń le è máa ṣe àwọn nǹkan mèremère ní orúkọ bàbá mi"

Rukayat Gawat Oyefeso ní lásìkò tí òun fẹ́ kírun lọ́jọ́ Kẹwàá, oṣù Keje ọdún 2012 ni wọ́n pe oun pé wọn kò rí bàbá òun.

Ó fi kun pé àwọn pé nọ́ḿbà bàbá òun títí àmọ́ àlọ ni àwọn rí tí àwọn kò rí àbọ̀ rẹ̀.

Ó sọ pé lẹ́yìn ọdún mẹ́rin tí àwọn kò rí bàbá òun, ni àwọn ṣe àdúrà fidau fún ní ìlànà ẹ̀sìn Islam.

“Ní ọdọọdún ni mo máa ń ṣe ìtọrẹ àánú fún àwọn opó àti aláìní ni orúkọ Baba mi.”

Ó ní òun ti pinnu pé ní gbogbo ọdún, tí Ọlọ́run bá dá ẹ̀mí òun sí, tí ẹ̀mí òun bá gùn, ní òun yóò máa ṣe nǹkan ní orúkọ Baba òun

Ó ní òun gbàdúrà ṣe òun ní ẹlẹ́mìí gígùn kí òun lè máa ṣe àwọn nǹkan mèremère ní orúkọ rẹ̀.