Àwọn olùgbé Lebanon ń sá kiri torí ìkọlù Israel, bí èèyàn tó kú ṣe di 550

Oṣiṣẹ ajọ alaabo ilu n fọwọ kan obinrin to sa kuro ni Lebanon lati tu u ninu .

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Ọkan lara awọn eeyan to sa kuro lagbegbe Guusu Lebanon wa si Beirut ni obinrin to duro ti mọto yii.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Kaakiri ilẹ Lebanon bayii, awọn idile n ko gbogbo ẹru wọn, wọn n sa gba apa Ariwa lọ ninu ọkọ̀ ati alupupu, bi ikọ ologun Israel ṣe n kọlu wọn. Ikọlu naa ni wọn lo ni i ṣe pẹlu awọn ọmọ Lebanon ti wọn jẹ Shia, Hezbollah.

Awọn kan ninu awọn olugbe agbegbe naa sọ pe awọn ologun Isreali ti fi atẹjiṣẹ ikilọ ranṣẹ si awọn tẹlẹ, bẹẹ ni wọn si tun kilọ naa pẹlu lilo ohun (Voice recording), eyi ti wọn fi ni kawọn kuro lagbegbe ti Iran n ṣatilẹyin fun.

Zahra Sawli, akẹkọọ ni Guusu Nabatie,sọ fun BBC pe ikọlu ọhun lagbara gan-an ni.

" Mo ji si ibugbamu ado oloro laago mẹfa aarọ. Nigba ti yoo fi di ọsan, o tun ti lagbara si i , mo si ri ọpọlọpọ ado oloro lagbegbe mi.

" Mo kan n gburoo bi wọn ṣe n fọ ọlọkan-o-jọkan igo ni."

Ṣugbọn bi iro ibẹru naa ṣe n dun to, Zahra ati awọn ti wọn jọ wa ko kuro nile. Wọn ko to bẹẹ .

"Nibo ni aa ba lọ? Ọpọ eeyan lo ti ha si aarin ọna ti wọn ko ribi sa si . Ọpọ awọn ọrẹ mi ni wọn ṣi wa lọna, ọna ti di pa nitori ọpọ eeyan to kun titi, ti wọn n wa ọna lati sa lọ.''

Bẹẹ ni Zahra wi.

Nigba ti yoo fi di ọwọ ọsan, sunkẹẹrẹ-fakẹẹrẹ ti gba gbogbo awọn ọna to wọ Ariwa Beirut, wọn ti di pa pẹlu awọn ọkọ rẹpẹtẹ ti wọn n lọ si olu ilu. Ona olopo mẹfa to jẹ marosẹ di pata, o di sunkẹẹrẹ-fakẹẹrẹ.

Bakan naa ni a ri awọn eeyan ti wọn n fi ẹsẹ rin lẹba okun, lapaa Guusu ilu Tyre, bẹẹ ni eruku n sọ lala loke latari awọn ado oloro.

BBC ba idile ẹlẹni marun-un to gun ọkada kan ṣoṣo de Beirut sọrọ .

Lati abule kan ni Guusu ni wọn ti lọ si Ariwa Tripoli, o ti rẹ wọn gidi.

"Ki lẹ fẹẹ ka sọ? A fi ka sa asala fun ẹmi wa naa ni'' Bẹẹ ni baba awọn idile ẹlẹni marun-un naa wi fun BBC.

Idile ẹlẹni marun-un to gun ọkada kan ṣoṣo lati sa asala fun ẹmi wọn.

Oríṣun àwòrán, Hassan Harfoush

Àkọlé àwòrán, "Ki lẹ fẹẹ ka sọ? Afi ka sa asala fun ẹmi wa naa ni," Olori ẹbi ẹlẹni marun-un to wa ọkada yii lo sọ bẹẹ fun BBC.

Ìpè àti àtẹ̀jíṣẹ́ ìjayà ń mú kí áwọn òbí mú ọmọ wọn kúrò nílé ìwé

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba ti yoo fi di irọlẹ ọjọ Aje, ajọ eleto ilera Lebanon kede pe eeyan 492 ni wọn ti pa, o si ti le ni 1,600 to ti farapa latari ikọlu Isreali to n mu awọn eeyan sa kiri bayii ni Lebanon.

Ikọ ọmọ ogun Israel; Israel Defense Forces (IDF) sọ pe o ti to1,100 ibugbamu to ti waye laarin wakati mẹrinlelogun.

Lara rẹ ni eyi to waye ni Guusu Beirut, eyi ti awọn IDF sọ pe nitori ọga ologun Hezbollah kan ti wọn fẹẹ pa ni.

Ni Beirut naa, ibẹrubojo gbalẹ kan ni. Niṣe lawọn eeyan n de lati olu ilu pẹlu mọto ti wọn so ẹru wọn mọ oke rẹ kitikiti, bẹẹ lawọn eeyan to wa nigboro paapaa n sa gba ibo mi-in lọ.

Ilẹ Israel ti kilọ fun awọn eeyan lati kuro lawọn agbegbe to ni Hezbollah n ko nnkan ija pamọ si, ṣugbọn o tun fi atẹjiṣẹ ranṣẹ sawọn eeyan ni Beirut, lai wo ti agbara Hezbolaah, titi kan Hamra, iyẹn agbegbe kan to kun fun ileeṣẹ ijọba, ile ifowopamọ ati awọn yunifasiti.

Kia lawọn obi n sare lọ sileewe lati mu awọn ọmọ wọn kuro, nigba ti wọn tun bẹrẹ si i gba ikilọ miran pe ki wọn kuro lagbegbe ọhun.

Baba kan, Issa, to lọọ mu ọmọ rẹ nileewe, ṣalaye fun ẹka iroyin Reuters pe,

"Niṣe ni wọn n pe gbogbo eeyan lori foonu, ti wọn n dunkooko mọ wa. Iyẹn ni mo ṣee waa mu ọmọkunrin mi kuro nileewe, a o mọ ohun to le ṣẹlẹ rara"

Issa lo sọ bẹẹ.

Awon eeyan yii n ko ẹru wọn bi wọn ṣe n kuro leti okun ilu Tyre, eyi to jẹ ilu nla ni Guusu Lebanon, nigba ti ikọlu de lọjọ Aje.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awon eeyan yii n ko ẹru wọn bi wọn ṣe n kuro leti okun ilu Tyre, eyi to jẹ ilu nla ni Guusu Lebanon, nigba ti ikọlu de lọjọ Aje.

'Ààbò kò sí níbikíbi ní Lebanon mọ́'

Mohammed, ọkunrin ọmọ Palestine kan ti a ba pade loju ọna pẹlu iyawo rẹ, nigba ti wọn n sa kuro ni Beirut, sọ fun BBC pe ko si aabo nibikibi ni Lebanon mọ.

Nigba ti a beere pe ṣe yoo duro ni olu ilu naa, Mohammed dahun pe, "Ni Lebanon, ko sibi ti aabo wa mọ, awọn Israel n sọ pe gbogbo agbegbe lawọn yoo jẹrun. Ni bayii, wọn ti n dunkooko mọ agbegbe ti a wa yii naa, nibo waa ni ka lọ?"

" Ẹrun ba mi, mi o mọ nnkan ti mo maa ṣe. Ironu iṣẹ,tabi ti pe ki n maa lọ sile ko tiẹ si lọkan mi, mi o mọ ohun to yẹ ki n ṣe."

Wọn ti pa awọn ileewe da si ibugbe ni kia.

Ikọ iroyin BBC de kilaasi ileewe kan ni ileewe ijọba to wa ni Bir Hasan, Iwọ-Oorun Beirut, lọjọ Aje, wọn n tun un ṣe lọwọ lati pa a da si ibugbe awọn eeyan to sa wa sibẹ ni.

Awọn eeyan naa sa wa lati ori oke Bekaa, to jẹ ibudo alagbara Hezbollah, ni Ariwa -Ila-Oorun Lebanon.

Wọn ti ko ibusun sawọn yara ikawe naa, awọn oṣiṣẹ ibẹ si sọ pe gbogbo ibẹ ni wọn yoo ti gba tan nigba ti yoo ba fi di irọlẹ ọjọ naa.

Awọn ọkọ̀ n to lati ra epo ni Beirut.

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Awọn ọkọ̀ n to lati ra epo ni Beirut.

Wọ́n pàṣẹ fún àwọn ọsibítù láti fagilé iṣẹ́ abẹ

Lọjọ Aje, wọn paṣẹ fun awọn ileewosan ni Lebanon pe kawọn dokita fagile iṣẹ abẹ to ba ṣee sun siwaju.

Eyi ri bẹẹ latari bawọn dokita ṣe ko si itọju awọn to farapa ti wọn n gbe wa sileewosan.

Ṣugbọn pẹlu bi idaamu ṣe gbalẹ kan ni Beirut to, awọn eeyan kan ṣi n sọ pe awọn ko nibi kankan lati sa lọ.

Wọn ni awọn yoo duro koju rẹ niluu awọn ni.

"Bi ogun gidi ba bẹrẹ, o yẹ ka duro bii ọmọ Lebanon ni, lai fi ti oṣelu ṣe. Nitori lopin gbogbo ẹ, ilu wa ni wọn fẹẹ fi ado oloro sọ di korofo"

Ọkunrin kan lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.

Bẹẹ ni awọn miran si ti gba kamu lori rogbodiyan to n ṣẹlẹ naa.

"Bi wọn ba ni ogun lawọn fẹ, ki la le ṣe? Wọn ṣigun le wa lori ni, a o si le ṣe nnkan kan si i"

Ọkunrin oniṣọọbu kan, Mohammed Sibai, lo ṣalaye bayii fun ẹka iroyin Reuters.

Mohammed, ẹni ọdun mẹtadinlọgọta (57) to n gbe ni Dahieyh, Guusu Beirut-ti i ṣe ibugbe agbara Hezbollah, sọ fun BBC pe gbogbo ogun loun ti koju, ọdun 1975 lo ni oun ti n foju wina ogun bọ, oun ko si ba ogun lọ.

"Mo ti bori ogun gbogbo to ti n ṣoju mi bọ lati 1975, fun idi eyi, o ti mọ mi lar.

"Emi o ni i kuro nibi, mo maa wa nile mi ni"

Bayii ni Mohammed wi.