Ìgbélé ọlọ́jọ́ méje fọ́dún Ọlọ́jọ́ ni màá fi ṣìpẹ̀ sáwọn Alálẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ Yorùbá àti ọrọ̀ ajé tó dagun - Ooni Ife

Oríṣun àwòrán, Otunba Moses Olafare
Ọọni Ile-Ifẹ,Ọba Adeyeye Ogunwusi, ti rọ awọn ọmọ Naijiria lati ṣe suuru fun Aarẹ Bọla Tinubu lori atunto ọrọ aje orilẹede yii to n ṣe.
Ọọni sọrọ yii lati fi ṣami ibẹrẹ ọdun Ọlọjọ to maa n waye lọdọọdun, niluu Ile-Ifẹ.
Ọdun ọlọjọ ọdun yii ti Ọọni yoo fi wa ni igbele fun ọjọ meje gbako, ti bẹrẹ lọjọ Aje, ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹsan-an ọdun 2024.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lasiko to fẹẹ wọ iyẹwu igbele naa, Ọọni ṣapejuwe ọdun Ọlọjọ bii eyi ti oun fi maa n ba Olodumare sọrọ nikọkọ.
O ni igbele ọjọ meje naa loun yoo tun fi ba awọn alalẹ sọrọ pẹlu lori iran Yoruba ati gbogbo eniyan lapapọ.
Ọọni sọ pe oun yoo ṣipẹ fun Olodumare lori ọrọ aje ati gbogbo nnkan ti ko fi ara rọ ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Ooni Ogunwusi's palace
‘’Nǹkan le púpọ̀ lásìkó yii, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ká ṣe sùúrù’’
Ọọni Adeyeye Ogunwusi ninu ọrọ rẹ, sọ pe, ‘’nnkan le pupọ fun awọn eeyan lasiko yii.
‘’Mo fẹẹ wure fun gbogbo eeyan, mo si fẹẹ parọwa, paapaa si awọn ọdọ lati ṣe suuru, ka ma baa f’ọwọ ara wa ba orilẹede wa jẹ.
‘’ Mo mọ pe awọn eeyan n koju inira lasiko yii, ṣugbọn lẹyin ọdun Ọlọjọ yii, gbogbo iṣoro to n koju wa lo maa dopin.
‘’Mo fẹẹ fi asiko yii bẹ Ẹlẹdaa lati da si iṣoro ọrọ aje to n koju Naijiria.’’
Bẹẹ ni Ọọni Ogunwusi wi.
KÍ ni Ọọ̀ni yóò máa ṣe lásìkò ìgbélé náà?

Oríṣun àwòrán, Ooni Ogunwusi's palace
Igbele ọjọ meje ti Ọọni yoo wa, yoo kun fun idakẹjẹjẹ, ìmọra ati ajọṣe pẹlu awọn ẹmi airi.
Awọn eeyan to ti n ba ọba ṣe ni gbogbo igba tẹlẹ ko ni i ni anfaani iru rẹ lasiko yii.
Ninu igbele yii ni Ọọni yoo ti tọrọ fun iran Yoruba ati Naijiria lapapọ
Ọdun Ọlọjọ ti 2024 yii ni ẹlẹẹkẹsan-an iru rẹ ti Ọọni Adeyeye Ogunwusi yoo ṣe lori apeere.
Satide, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹsan-an yii ni Ọọni yoo tun foju ba ode pada lẹyin igbele naa.
Nigba naa ni yoo de Ade Arè ti i ṣe ade iṣẹmbaye ti Ọọni maa n de lẹẹkan lọdun, lati ṣami ọjọ akọkọ ọmọ eniyan loke eepẹ.














