Àwọn èrè tó wà nínú àtúnṣe ọrọ̀ ajé tí mò ń ṣe, yóò f’ojú hàn láìpẹ́ - Tinubu

Aworan Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, @Nigerian Presidency

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lẹẹkan si i, Aarẹ Bola Tinubu ti fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe ko ni i pẹ mọ ti wọn yoo fi maa jẹ anfaani to wa ninu atunṣe ọrọ aje ti ijọba oun gunle.

Aarẹ Tinubu tun sọrọ idaniloju yii lọjọ Aje, ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹsan-an ọdun 2024, nibi ipade ọlọdọọdun awọn akọṣemọṣẹ oluṣiro owo (Chartered Accountants) nipinlẹ Rivers.

Tinubu sọ pe oju to n pọn awọn ọmọ Naijiria lasiko yii, latari owo iranwọ ori epo ti iṣakoso oun yọ kuro ko ni i pẹẹ so eso rere.

"Laarin asiko diẹ tijọba Tinubu de, iṣẹ nla to n ṣe ti foju han lẹka ọgbin, imọ ẹrọ ati ẹka agbara"

Didi Esther Walson-Jack, olori awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ lorilẹede yii, to gba ẹnu Aarẹ Tinubu sọrọ ṣalaye pe, laarin asiko diẹ ti Tinubu de, iṣẹ nla to n ṣe ti foju han lẹka ọgbin, imọ ẹrọ ati ẹka agbara.

‘’ A fẹẹ tete ro ọrọ aje ti ko fẹsẹ mulẹ ta a ba yẹn lagbara la ṣe gbe awọn igbesẹ ti ko dẹrun’’

‘’ A ti ṣe awọn ipinnu kan ti ko dẹrun, awọn bii owo iranwo epo ti a yọ ati atunṣe owo naira.

‘’A mọ inira nla ti ipinnu wa yii n mu ba awọn araalu, ṣugbọn o da wa loju pe ọrọ aje wa yoo yipada, awọn ọmọ Naijiria yoo si bẹrẹ si i jẹ anfaani naa laipẹ rara.”

Ẹ o ranti pe ọpọ igba ni Aarẹ Tinubu ti ni ki awọn ọmọ Naijiria fi ọkan balẹ lori ohun gbogbo to wọn gogo.

Aipẹ yii lo si ni oun ko tori owo gba ipo aarẹ Naijiria, bi ko ṣe lati tun ohun to ti bajẹ ninu ọrọ aje ilu naa ṣe.