Ìdí rèé tí ìjọba fi gbọdọ̀ yọ owó ìrànwọ́ orí epo pátápátá - Dangote

Aworan Aarẹ Bola Tinubu ati Aliko Dangote

Oríṣun àwòrán, Presidency/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbajugbaja oniṣowo ọmọ Naijiria, Alhaji Aliko Dangote, ti kepe pe ijọba apapọ ni lati yọ owo iranwọ ori epo bẹntiroolu patapata.

Dangote, ẹni to bẹrẹ si ni ta epo bentiroolu lati ileeṣẹ ifọpọ rẹ to wa nipinlẹ Eko loṣu Kẹsan an yii sọ pe, yiyọ owo iranwọ ori epo patapata yoo jẹ ki ijọba mọ iye epo bẹntiroolu ti araalu n lo lojumọ ni Naijiria.

Dangote fidi ọrọ yii mulẹ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin Bloomberg niluu New York lorilẹede Amẹrika.

Oniṣowo naa sọ pe ọrọ owo iranwọ lori nkan ti araalu ilu n lo maa n saba mu ikanra dani.

‘’Awọn eeyan saba maa n gbowo le nkan ti ijọba ba ti n san owo iranwọ lori rẹ.

Eyi si tumọ si pe ijọba yoo maa san owo mii ti ko yẹ ki o san,'' Dangote lo sọ bẹẹ.

"Ibudo ifọpo mi yoo ṣe iranwọ fun ijọba lati mọ iye epo tawọn eeyan n lo lojumọ"

Dangote tẹsiwaju pe ''asiko to dara niyi fun ijọba lati fopin si sisan owo iranwọ lori epo.

Amọ, ileeṣẹ ifọpo mi yoo ṣe iranwọ fun ijọba lati mọ iye epo tawọn eeyan n lo lojumọ.

Awọn kan ni ọgọta miliọnu lita epo bẹntiroolu lawọn eeyan n lo lojumọ lorilẹede Naijiria.

Awọn mii sọ pe iye epo ti araalu n lo ko to bẹẹ, ṣugbọn ti a ba wo o bayii pẹlu epo to n jade lati ileeṣẹ ifọpo Dangote, a le ka iye epo tawọn tanka n gbe lojumọ.

A si maa gbiyanju lati mojuto gbogbo awọn tanka to n gbepo lati ọdọ wa ki wọn ma ba gbe e gba ibomiran lọ."

''Asiko to dara niyi fun ijọba lati fopin si sisan owo iranwọ ori epo''

Gbajumọ olokoowo naa salaye pe igbesẹ naa yoo ṣe iranwọ fun ijọba lati fi owo to ba rogun pamọ, lai ṣe atunwi asan, asiko niyi fun ijọba lati yọ owo iranwọ ori epo patapata.

Dangote ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe gẹgẹ bi oniṣowo kii ṣe ojuṣe ileeṣẹ oun lati yọ owo iranwọ ori epo bi ko ṣe ojuṣe ti ijọba.

Lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Karun un ọdun 2023 to jẹ ọjọ ifilọlẹ ijọba rẹ ni Aarẹ Bola Tinubu kede wi pe ijọba ti yọ owo iranwọ ori epo bẹntiroolu kuro.

Igbesẹ yii lo ṣokunfa ọwọngogo nnkan lorilẹede Naijiria eyi to jẹ kawọn araalu ṣe ifẹhonuhan.

Lẹyin naa ni ijọba tun bẹrẹ tun sanwo lori epo papaa julọ pẹlu ọwọngogo nkan to n buru sii.

Tita epo bẹntiroolu si Naijiria yoo jẹ ki owo Naira gbe pẹẹli si - Dangote

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Dangote fikun ọrọ rẹ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu Bloomberg wi pe ida 40% ọja pasipaarọ owo ni Naijiria ni okowo epo nikan ko.

O ni bi ileeṣẹ ifọpo Dangote ti bẹrẹ si ni ta epo bẹntiroolu fun NNPCL lati ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹsan an yii yoo ṣe iranwọ fun owo naira lati lagbara sii.

Nigba ti o n sọrọ lori ede-ai-yede to waye laarin ileeṣẹ Dangote ati ileeṣẹ epo rọbi Naijiria, NNPCL, Dangote ṣalaye pe ẹdinwo wa lori epo ti NNPCL ra lati ileeṣẹ ifọpo Dangote ti a ba woo pẹlu epo ti NNPLC n gbe wọle lati oke okun.

Ṣugbọn o ni iye kan naa ni NNPCL n ta epo sita bo tilẹ jẹ owo epo ti o ra lati ileeṣẹ ifọpo Dangote din si eyi ti o gbe wọle lati oke okun.

Dangote tun ṣalaye wi pe o ṣee ṣe ki ileeṣẹ ifọpo oun bẹrẹ si ni maa ta epo rọbi ninu Kẹwaa to n bọ yii.

O ni ileeṣẹ ifọpo Dangote yoo maa ta epo rọbi ni owo naira lẹyin to ba ri ra a tan ni owo naira bakan naa.

‘’To ba jẹ wi pe $80 ni wọn n ta agba epo kan, ileeṣẹ wa yoo san owo naira ti a ba fẹnuko si.

Bayii ni a ṣe maa ta epo rọbi si Naijria eyi ti yoo si tun jẹ ki owo naiara gberu sii.

A si n sọrọ lọwọ lori adehun ti o gbọdọ waye ki karakata epo rọbi naa le gberasọ.