Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn tí àjọ elétò ìdìbò KWSIEC kéde pé APC jáwé olúborí ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ Kwara

Aworan ibi ti rogbodiyan ti waye niluu Ilorin
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọgọọrọ awọn olufẹhonuhan ti ọpọ fura si pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Kwara ni wọn ti ṣe iwọde lọ si Ileesẹ ajọ eleto idibo ipinlẹ naa KWSIEC.

Ohun ti wọn n sọ ni pe esi ibo ti ajọ naa kede ko tẹ awọn lọrun, pe o ni makaruru ninu.

Saaju ni ajọ KWSIEC kede pe ẹgbẹ oselu APC lo jawe olubori ni gbogbo ijọba ibilẹ mẹrindinlogun ati wọọdu 193 to wa ni ipinlẹ naa.

Ohun ti a ri ni pe ko si osisẹ ajọ naa lọfiisi nigba ti a de ibẹ sugbọn awọn agbofinro wa nibẹ lati daabo bo ọfiisi naa.

Ṣadeedee ni awọn kan bẹrẹ si n ko taya sita, ti wọn si n dana sun un.

Arakunrin kan to n lọ jẹjẹ lori ọkada fara ka sa iṣẹlẹ naa, wọn wọ ọ sọ kalẹ wọn si lu u lalubami.

Bi wọn ṣe n lu u lo n sa, ti wọn si n tẹ le e ko to di pe o raye sa wọ inu ọgba Ileesẹ ajọ naa.

Ariwo ti wọn n pa bi wọn ṣe n lu u ni pe ọkunrin naa jẹ ókan lara awọn osisẹ ajọ KWSIEC ti wọn ni wọn se mago-mago fun ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo to waye.

Akọrọyin kan ti oun naa wa nibi iṣẹlẹ ọhun sa asala fun ẹmi rẹ.

Ọrọ di bo o lọ ya n mi lọfiisi ajọ eleto idibo KWSIEC

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọkunrin ti orukọ rẹ n jẹ Ibrahim Suberu, ṣalaye pe "mo jẹ osisẹ ijọba, mi kii se osisẹ ajọ KWSIEC, koda mi kii ṣe oloselu.

"Bọrọ ṣe jẹ ni wi pe, mo lọ ra ọja ni Shoprite, mo si n pada lọ sile mi lori ọkada ni mo ti ri awọn janduku yii, ti wọn n sun taya lori titi.

"Ohun ti mo kan sọ ni wi pe, ki lo de ti ẹ ba ọna jẹ? Bayii ni wọn ṣe wọ mi kuro lori ọkada ti wọn bẹrẹ si n lu mi.''

Ọgbẹni Suberu ni ''ki n to sẹju pẹ, mo ti ri ero pupọ lori mi, bi awọn kan ṣe n fun mi ni ipa, lawọn kan run mi ni igi, awọn alabara ati ẹsẹ ko niye.

"Wọn yi mi mọ inu gọta, mo tun dide, wọn ti n gbe taya si mi lọrun ki wọn sana sii, sugbọn mo tun yọra mi gba.

Mo sa wọ inu ọkọ awọn ọlọpaa sugbọn wọn lu mi wọ bẹ, awọn ọlọpaa o ri nkankan ṣe.

"Mi o mọ bi Ọlọrun se ran mi lọwọ lati sa kuro laarin wọn ti mo sa wọ inu ọgba Ileesẹ ajọ KWSIEC, wọn o lawọn o tẹle mi sugbọn awọn ọlọpaa ti ilẹkun.

Ọkunrin naa sọ pe oun o le pe iyawo oun lati sọ ohun tọju oun ri ko ma ba daku tori o wa ninu oyun.

"Mi o ri eru eyi ri laye mi, sugbọn mo dupẹ lọwọ Ọlọrun to ko mi yọ.''

Bi ọkunrin naa se n sọrọ naa lo n pe dokita rẹ, tori o ti rẹ ẹ.

APC jáwé olúborí gbogbo ìbò ìjọba ìbílẹ̀ 16, wọ́ọ̀dù 193 ní ìpínlẹ̀ Kwara

Awọn oludibo ni ipinlẹ Kwara

Ajọ eleto idibo ipinlẹ Kwara, Kwara State Independent Electoral Commission, (KWSIEC) ti kede pe ẹgbẹ APC lo jawe olubori nibi ibo ijọba ibilẹ to waye ni ipinlẹ ọun ni ana ọjọ kọkanlelogun osu kẹsan-an, ọdun 2024.

Ikede yi waye ninu atẹjade ti alaga ajọ ọun, Okanla Baba fi lede lẹyin ti wọn ka ibo naa tan.

Eto idibo naa lo waye kakiri wọọdu 193, ni ijọba ibilẹ 16 to wa ni ipinlẹ Kwara

Awọn ẹgbẹ marun-un ti wọn dije ninu idibo naa ni ẹgbẹ APC, APM, PDP, SDP, ati Accord.

Ninu ikede rẹ, Ọkanla Baba sọ pe lẹyin ti awọn farabalẹ ka awọn iwe idibo naa, ẹgbẹ APC lo jawe olubori gbogbo ibo alaga ijọba ibilẹ ati ibo alaga wọọdu (councilor) 193 to wa ni ipinlẹ Kwara.

O wa dupẹ lọwọ awọn ẹgbẹ to dije ọun fun gbigba alafia laaye ti eto idibo naa si lọ ni irọwọrọsẹ.

Bakanna lo kan sara si awọn oludibo fun titu yaya jade lati dibo fun oludije ti ọkan wọn fẹ.

Ẹwẹ, Okanla Baba gbosuba kare fun awọn agbofinro lori igbaradi ati ijafafa wọn lati ri pe ko si rogndiyan.

Wayi o, awọn ọmọ ẹgbẹ PDP n fapa janu lori esi idibo naa, wi pe ẹgbẹ awọn lawọn gbegba oroke.

BBC Yoruba gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ naa n gbaradi bayi lati se iwọde ifẹhonuhan lori esi idibo naa.

Aworan Gomina AbdulRaman AbdulRaqak

Bayi ni awọn esi idibo naa se lọ gẹgẹ bi ajọ KWSIEC ṣe fi lede

Ifelodun LG

APC 22524

PDP 2727

APM 482

OYUN LG

APC 12159

PDP 356

APM 386

Oke Ero LG

APC 7472

PDP 1168

APM 224

ISIN LG

APC 8173

PDP 1165

APM 77

EDU LG

APC 23963

PDP 3851

APM 424

Patigi LG

APC 14,119

PDP 2,939

APM 806

MORO

APC 14,555

PDP 1670

APM 117

ASA LG

APC 15,024

PDP 2638

APM 41

ILORIN SOUTH LG

APC 20,207

PDP 2,072

APM 226

SDP 621

Baruten LG

APC 38,549

PDP 1335

APM 665

Ilorin East

Apc 20883

Pdp 5383

Sdp 475

Apm 835

Kaima

Apc 23,029

Pdp 1737

Apm 59

Ekiti LGA

Apc 8707

Pdp 907

Apm 966

Offa

Accord 1919

APC 22,400

Pdp 1586

Apm 636

Sdp 391

Ilorin west

Apc 50128

Pdp 4202

Apm 1882

Irepodun

Apc 14010

Pdp 2106

Apm 559

Sdp 239