Wo àwọn èsì ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Edo tí àjọ INEC ti kéde

Oríṣun àwòrán, INEC
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Lẹyin tawọn eeyan ipinlẹ Edo ti dibo tan lati yan ẹni ti yoo tukọ ipinlẹ naa gẹgẹ bi gomina fun ọdun mẹrin to n bọ, ajọ eleto idibo INEC ti bẹrẹ si ni gbe esi ibo naa jade bayii.
Oludije sipo gomina mẹtadinlogun ninu eyi ti ọkan lara wọn jẹ obinrin lo kopa ninu eto idibo naa lati di gomina ipinlẹ Edo.
Ṣaaju ni ajọ INEC kede wi pe oludibo ti wọn le ni miliọnu meji lo gba kaadi idibo wọn lati kopa ninu eto idibo naa.








