Kí ni àrùn Diphtheria tó pa ọmọdé méje, tí ọ̀pọ̀ sì wà nílé ìwòsàn?

Awọn ọmọde to wa nile iwosan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Arun kan ti wọn n pe ni Diphtheria ti ran ọmọde meje sọrun ọsangangan ni abule Mbuuto to wa nijọba ibilẹ Aboe Mbaise nipinlẹ Imo.

Aimọye awọn ọmọde si lo ti ko arun naa, ti wọn si n gba itọju lọwọ nile iwosan kan ninu ilu naa.

Kanselọ feto ilera ni Abô Mbaise, Ugochukwu Umunnakwe, salaye pe abule Mbútú Nweorie ni wọn ti kọkọ kofiri arun naa.

O ni se ni awọn ọmọde n ku lọwọọwọn nilu naa, ti oun si ke gbajare tọ ijọba lọ.

"Bi gomina se gbọ, lo fi isẹlẹ naa to ajọ eleto ilera lagbaye (WHO) leti ati ileesẹ eleto ilera nipa arun naa to n waye lagbegbe wọn.

Wọn ti wa, ti wọn si gba ẹjẹ awọn ọmọ to ni aisan naa fun ayẹwo.

Esi ayẹwo naa si fihan pe lootọ, arun Diphtheria ni awọn ọmọde naa ni." Umunnakwe lo salaye bẹẹ.

Abẹrẹ diphtheria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nkan to yẹ ki o mọ nipa Diphtheria

Aarun diphtheria jẹ oriṣi kokoro aifojuri ‘bacteria’ to ma n kọlu eroja (mucous membranes) to n daabo bo imú ati ọ̀fun.

Lootọ ni oogun oyinbo ma n wo diphtheria, ṣugbọn to ba ti pọ ju ninu ara, o le ba ọkàn, kindinrin ati ọpọlọ jẹ.

Koda pẹlu itọju, aarun naa ṣi le pa eeyan, paapaa awọn ọmọde.

Kilo n fa diphtheria?

Oriṣi kokoro aifojuri ‘Corynebacterium diphtheria’ lo n fa a . Kokoro aifojuri naa yoo ma a pọ si ni ọna ọfun tabi ni awọ ara.

Ti ẹni to ni aarun diphtheria ba sín tabi hu ikọ sinu afẹfẹ, ẹni to ba sunmọ ọ tabi kọja lasiko naa le fa C. diphtheria si imu. Ọna kan pataki ti diphtheria fi ma n di ajakalẹ re e , paapaa ni ayika ti eero ba pọ si.

Eeyan tun le ko aarun yii, to ba fi ọwọ kan awọn ohun elo bi aṣọ inuwọ, ati awọn nkan mii, ti ẹni to ni aarun diphtheria lo nitori pe o ṣe e ṣe ki aarun naa ti sa pamọ si wọn lara.

Yatọ si ọna ọfun, diphtheria tun le farahan ni awọ ara.

Iru eyi ma n fa irora ninu ara, ara wiwu ati ara pipọn.

Botilẹ jẹ pe ko wọpọ niru agbegbe bi Naijiria, o le ṣẹlẹ laarin awọn eeyan ti imọ toto wọn ko ba dara to, tabi awọn to n gbe ni ibi ti eero ti pọ ju bo ṣe yẹ.

Awọn ami ti diphtheria ma n fihan ninu ara:

Laarin ọjọ meji si marun-un, ni aarun diphtheria ma n farahan to ba ti wọ ara.

Lara awọn ami naa si ni:

  • Egbo ni ọna ọfun
  • Ọrun yoo wú
  • Idiwọ si eemi tabi ki eeyan o ma a mi lakọ-lakọ
  • Ikun imu yoo ma jade lai dawọ duro
  • Ara gbigbona ati otutu
  • Aarẹ yoo mu ara
  • Kẹlẹbẹ to ni awọ eeru yoo bo ọfun

Bakan naa lo ṣe e ṣe ki ẹni to ni diphtheria, ma ri ami kankan – iru awọn eeyan bayii lo ma n ṣaba pin aarun naa kiri, lai ṣe pe awọn funra wọn dubulẹ aisan.