Ariwo sọ lórí bí sọ́jà obìnrin tí wọn fẹ́sùn kàn pé ó jí $50,000, owó ìyàwó ọ̀gá rẹ̀, ṣe dèrò àtìmọ́lé

Awọm ọmọ ologun Naijiria

Oríṣun àwòrán, @Nigeria Army

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọmogun oriilẹ Naijiria ti ju ọmọ ologun obinrin kan, Cpl. Amina Maidoki, si ahamọ lori ẹsun wi pe o jale.

Adele agbẹnusọ fun ileeṣẹ ologun, Appolonia Anele, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade ti o fi sita lọjọ Iṣẹgun.

Ọmogun Maidoki ẹni ọdun mẹẹdọgbọn to ṣiṣẹ gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ ADC pẹlu Salamatu Faruk Yahaya to jẹ iyawo olori ọmogun oriilẹ tẹlẹri, Ọgagun fẹyinti Faruk Yahaya, ni a gbọ pe obinrin naa fẹsun kan wi pe o ji $50,000 nile oun niluu Abuja.

Iroyin fi idi rẹ mulẹ wi pe o ti to ọsẹ mẹfa bayii ti sọja obinrin naa ti wa ni atimọle ileeṣẹ ologun.

Ọgbẹni Anele ni awọn alakalẹ ofin wa to n sọ nipa ihuwasi awọn ọmogun lẹnu iṣẹ.

Ileeṣẹ ọmogun sọrọ lori idi to fi ju sọja obinrin si atimọle

Ileeṣẹ ọmogun ti sọ idi ti sọja obinrin to ṣe ADC iyawo olori ologun oriilẹ tẹlẹri, Ọgagun fẹyinti Faruk Yahaya si atimọle.

Adele alukoro ileeṣẹ ọmogun, Anele sọ pe ''bi Maidoki ṣe wa ni atimọle ko lodi sofin ninu iṣẹ ologun.

O yẹ kawọn eeyan mọ pe ko si nnkan to jọ titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ ninu iṣẹ ologun.

A maa n tẹle ofin, gbogbo ọmogun ti wọn ba fẹsun kan ni ofin fun un lanfaani lati sọ ti ẹnu rẹ.

Iwadii si n lọ lọwọ lori ẹsun ti wọn fi kan ọmogun Maidoki, ileeṣẹ ologun ko si ni tẹ ẹtọ rẹ mọlẹ.

Koda, Maidoki n gba itọju gidi ni atimọle ti o wa gẹgẹ bi ileeṣẹ ologun ṣe alakalẹ rẹ.''

Anele fikun ọrọ rẹ pe irọ to jinna si ootọ ni ọrọ tawọn eeyan n gbe kiri pe ọna ti ko ba ofin mu ni ileeṣẹ ologun fi ju ọmogun naa si ahamọ.

O ni awọn eeyan naa n sọrọ yii lati ṣi araalu lọna lori ọrun ọhun ni.

Anele rọ araalu lati kọ eti ikun si nnkan tawọn eeyan naa n gbe kiri lori ọrọ ọhun.

Adele alukoro ileeṣẹ ologun ko ṣai fidi rẹ mulẹ ileeṣẹ ọmogun mọ pe ọrọ naa n kọ ẹbi Maidoki lominu.

Amọ, Anele sọ pe ko si ẹni to ga ju ofin lọ papaa julọ ninu iṣẹ ologun.

O ni ileeṣẹ ologun yoo maa fi ohun to ba ṣẹlẹ lori obinrin sọja to araalu leti laipẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post