Ǹ jẹ́ ìyànsípò láì ṣègbè lẹ́yìn ẹ̀yà kan kò máa d'ohun ìgbàgbé ní Naijiria báyìí?

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
- Author, Mansur Abubakar
- Role, BBC News, Abuja
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti sọ pe ijọba Aarẹ Bola Tinubu ko tẹle eto iyanisipo pẹlu alakalẹ oniruuru ẹsin ati ẹya to wa ni Naijiria.
Iyipapa ẹya ati ẹsin ti ṣakoba sẹyin fun orilẹede Naijiria.
Gbogbo ẹkun to wa lorilẹede Naijiria ni ijọba ti maa n yan awọn minisita sipo.
Kii ṣe nnkan tuntun ni kawọn eeyan maa sọ nipa iyansipo ti aarẹ ba ṣe ni Naijiria, ṣugbọn ọpọ eeyan lo ti sọ pe Aarẹ Tinubu yan ọpọ eeyan to jẹ Yoruba, ẹya rẹ sipo ju awọn ẹya mii lọ.
Ijọpa apapọ si ti dawọn iru eeyan bẹẹ lohun pe ọrọ ko ri bẹẹ rara.
Ẹya to le ni 250 to wa ni Naijiria nigba ti Yoruba, Hausa-Fulani ati Igbo jẹ ẹya mẹta to pọ julọ.
Ọpọ alatako lo ti sọ pe Tinubu ko tẹle alakalẹ nigba to fi musulumi lati ẹkun ariwa Naijiria ṣe igbakeji rẹ ninu eto idibo aarẹ ọdun 2023.
Lati ọdun 1999 ti Naijiria ti pada si ijọba awarawa ni ẹgbẹ oṣelu to ba n ṣejọba ti maa n fa musulumi ati ẹlẹsin onigbagbọ kalẹ fun ipo aarẹ ati igbakeji tori awọn ẹlẹsin meji yii lo pọju ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Bo tilẹ jẹ pe ipo ti aarẹ maa n yan awọn eeyan si pọ, ṣugbọn onimọ kan nipa eto oṣelu, Lawal Lawal, sọ pe ipo mẹjọ kan wa to ṣe koko.
Awọn ipo mẹjọ ọhun niyii:
Ọga Banki apapọ Naijiria, CBN
Ọga agba Ileeṣẹ ifọporọbi Naijiria, NNPC
Ọga agba ọlọpaa
Olori ọmogun
Ọga agba ileeṣẹ aṣọbode
Ọga agba ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ
Ọga agba ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ
Ọga agba ajọ to pawo wọle
Awọn mẹjọ yii ṣe pataki, wọn si ṣe koko fun eto inawo ati aabo orilẹede.
Titi ti o fi di oṣu Kẹrin ọdun yii, gbogbo awọn to wa lawọn ipo mẹjọ yii lo jẹ ẹya Yoruba.
Ọpọ eeyan lo tun bẹrẹ sii sọrọ nigba ti Tinubu yan Bayo Ojulari sipo ọga agba ajọ NNPC, eyi to fi rọpo Mele Kyari to wa lati ẹkun ariwa to wa nipo naa tẹlẹ.
Ọrọ ko ri bayii ṣaaju akoko ijọba Tinubu, tori kii ṣe ẹya Yoruba lo di gbogbo awọn yii mu.
Lasiko ijọba Aarẹ Goodluck Jonathan laarin ọdun 2010 si 2023, ẹya Fulani meji, Hausa meji, Atyap kan, Igbo kan, Yoruba kan ati eeyan kan ni Calabar lo di awọn ipo mẹjọ naa mu.
Lasiko Aarẹ Muhammadu Buhari laarin 2015 si 2023, ẹya Hausa mẹta, Kanuri meji, Yoruba kan ati Nupe kan lo di awọn ipo mẹjọ naa mu.
Amọ, ọpọ eeyan lo maa n ri awọn ẹya Hausa, Kanuri ati Nupe gẹgẹ bi awọn eeyan ẹkun ariwa Naijiria.
Eyi lo jẹ ki ọpọ eeyan maa sọ pe Buhari ṣegbe lẹyin ẹkun ariwa pẹlu iyanisipo to ṣe.
Ọpọ lo ti n sọ pe nnkan ti Buhari ṣe ni Tinubu naa tẹle, amọ, ẹya Yoruba ni gbogbo awọn eeyan mẹjọ ti aarẹ yan sawọn ipo yii eleyii ti ko tii ṣẹlẹ ri.
Ọjọgbọn onimọ nipa itan, Tijjani Naniya sọ fun BBC pe ''mi o le ranti aarẹ Naijiria to yan ẹya kan ṣoṣo sawọn ipo nla nla bayii.
Ohun to n ba mi lẹru ni pe ti aarẹ mii ti yoo jẹ lẹyin Tinubu naa ba yan awọn eeyan ẹya rẹ sawọn ipo yii, eyi yoo mu adinku ba igbagbọ awọn eeyan ninu ijọba awarawa.''
Ọpọ awọn eeyan ti wọn jẹ ẹya Hausa ati Fulani lo ti n kọminu lori ọrọ yii lati igba ti Tinubu ti gbe igbesẹ yii.
Awọn eeyan lati ẹkun ariwa ni gbogbo awọn ti Tiunubu yan sipo ọga agba ileeṣẹ ifọporọbi NNPC, ileeṣẹ ọlọpaa, ajọ aṣọbode ati EFCC rọpo.
Iyọnipo Abdulrasheed Bawa to jẹ Hausa nipo ọga agba EFCC lọdun 2023 lẹyin ọdun meji ti wọn yan an sipo naa fa awuyewuye laarin ọpọ eeyan.
Wọn mu Bawal, wọn si fẹsun aṣilo ọfiisi kan an, lẹyin naa ni wọn ti i mọle fun ọgọrun ọjọ ki wọn to fi silẹ.
Ọpọ lo gbagbọ pe wọn ṣe nnkan ti wọn ṣe fun Bawal ki Ola Olukayode to jẹ Yoruba le rọpo rẹ.
Isah Habibu to jẹ onimọ nipa ọrọ to n lọ sọ pe ''o yẹ ki aarẹ mọ pe ọkan lara awọn ẹya to wa ni Naijiria ni Yoruba jẹ, tori naa, o ni lati maa yan awọn eeyan sipo lati inu gbogbo ẹya to wa ni orilẹede yii.''
Amọ, agbẹnusọ aarẹ Tinubu ti sọ pe aarẹ ko figba kan bọ ọkan pẹlu gbogbo iyanisipo ti o ṣe ninu ijọba rẹ.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Oludamọran aarẹ lori eto iroyin, Sunday Dare, ṣalaye pe eeyan mọkanlelaadọrin lati ẹkun ariwa ni Tinubu yan sipo nigba ti aarẹ yan eeyan mẹtalelọgọta sipo lati ẹkun guusu orilẹede Naijiria.
Ọrọ yii ti Dare fi soju opo X rẹ lọjọ kẹsan an oṣu Kẹrin ọdun yii ni o pada yọ kuro nibẹ lẹyin tawọn eeyan tọka si ọpọ aṣiṣe ninu alaye rẹ.
O ni oun yoo fi nnkan mii lede ṣugbọn ko tii ṣe bẹẹ lẹyin ọsẹ mẹfa to ti yọ eyi to fi sibẹ tẹlẹ kuro.
Sẹnẹtọ Ali Ndume to jẹ ọmọ ẹgbẹ APC kan naa pẹlu Tinubu ti koro oju si iyanisipo Aarẹ Tinubu.
Ndume ni iyansipo Tinubu fi sibikan ju ibikan lọ, o sọ pe eyi tako eto fifun araalu ni ireti ọtun ti ijọba Tinubu ṣeleri fawọn araalu.
Oludamọran aarẹ mii lori eto iroyin, Daniel Bwala, naa sọ pe awọn ipo kan ko ṣe pataki ju omiran lọ.
Bwala ni ohun toun mọ daju ni pe Aarẹ Tinubu tẹle iwe ofin Naijiria nipa iyanisipo rẹ, ati pe iwe ofin yii ko la a kalẹ wi pe irufẹ awọn ipo kan gbọdọ wa lati awọn apa ibikan ni Naijiria.
Bwala sọ pe ''gbogbo ipo ti aarẹ n yan awọn eeyan si lo ṣe pataki, lati ẹkun ariwa ila oorun ni oludamọran aarẹ lori eto abo ti wa, olori ọmogun si wa lati ẹkun ariwa guusu, nigba ti akọwe ijọba apapọ wa lati apa ariwa aarin gbungbun Naijiria.
Ọfiisi akọwe ijọba apapọ to n ṣakoso eto ijọba naa sọ ninu atẹjade to fi sita lọjọ kejila oṣu Kẹrin wi pe Tinubu ko ṣegbẹ lẹyin ẹya kankan ninu awọn iyansipo ti o ṣe.
Onimọ nipa eto oṣelu, Lawal, sọ pe o yẹ ki Tinubu yan awọn eeyan to koju oṣunwọn sawọn ipo to ṣe pataki lai fi ti ẹya ṣe.
O sọ pe nnkan ti Aarẹ Tinubu n ṣe gan an niyii.
Ọgbẹni Lawal sọ pe asiko ti to fun orilẹede Naijiria lati maa yan awọn eeyan sipo lai fi ẹya ṣe.
Ọjọgbọn Naniya sọ pe akoko kan n bọ tawọn ọmọ Naijiria ko ni maa ro nipa ẹlẹya mẹya mọ, amọ, o ni akoko naa si jinna.
O ni eyi le ṣẹlẹ lẹyin ti aarẹ bii mẹrin ti ko ṣegbe lẹyin ẹya kankan ninu iyansipo rẹ ati gbigbe iṣẹ fawọn eeyan lati ṣe ba ti jẹ.
Ọjọgbọn Naniya ni eyi le waye ṣugbọn awọn olori to dara lo le ṣe bẹẹ.















