Àwọn olólùfẹ́ ẹgbẹ́ àgbábọ́ọ̀lù Liverpool tó ń ṣàjọyọ̀ gbígba ife ẹ̀yẹ Premier League ko àgbákò ìjàmbá, àádọ́ta farapa

Awọn ọmọde at'agba farapa yanayana lẹyin ti awakọ kan ṣadeede ya wọ aarin ero ti wọn n dawọọ idunnu ife Premier League ti ẹgbẹ agbabọọlu gba ni saa bọọlu to ṣẹṣẹ pari yii.
Ọmọde mẹrin lo wa ninu aadọta eeyan to ṣee ṣe nibi t'awọn ololufẹ Liverpool ti wọn ti n yọ ayọ ami ẹyẹ Premier League ti ẹgbẹ agbabọọlu naa gba lalẹ ana ọjọ Aje lẹyìn ti awakọ naa ya wọ aarin wọn.
Ko din ni eeyan mẹtadinlogun ti wọn sare gbe lọ ile iwosan, ti awọn meji si farapa gan an.
Ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun Merseyside ti mu ọkunrin kan ọmọ ilẹ Gẹẹsi ti wọn sọ pe oun lo wa ọkọ naa.
Awọn ọlọpaa ko wo iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii iṣẹlẹ awọn agbesunmọmi to maa n fi ẹmi awọn eeyan ṣofo.
Olori ijọba ilu Liverpool, Steve Rotheram sọ fun BBC wi pe iṣẹlẹ laabi yii lo ba ajọyọ tawọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool n ṣe lọjọ Aje naa jẹ.
Ọgbẹni Rotheram ni awọn ọlọpaa yoo ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ nibi ti ọrọ de duro bayii.
O-ṣoju-mi-koro ṣalaye bi iṣẹlẹ ọhun ti waye
Akọroyin BBC, Connor Phillips, n ṣe faaji nile ọti kan ti ko jinna sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye nigba ti awakọ ọhun ya wọ aarin ero lopopona Water Street.
Phillips ni oun ko kọkọ mọ nnkan to n ṣẹlẹ, afi igba toun gbọ iroyin nipa isẹlẹ naa lori ẹrọ amohunmaworan.
''Bayii ni a rin lọ sibẹ ti a si ri nnkan to ṣẹlẹ gan an nibi tawọn ololufẹ Liverpool ti n dunnu ife ẹyẹ Premier League ti wọn gba.''
Phillips sọ pe lọgan ni gbogbo nnkan yi pada lẹyin tawọn eeyan bẹrẹ sii gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun.
Akọroyin BBC ni ''ni ṣe ni nnkan naa ṣẹlẹ lojiji, bayii ni ọpọ eeyan bẹrẹ si ni sa lọ sibi tẹlẹfisan lati wo nnkan to sẹlẹ ni Water Street ti wọn si n kaanu awọn to fara kaasa nibi iṣẹlẹ naa.''















