Kí ló mú èrò ọkọ̀ fẹ́ ṣílẹ̀kùn bàálù lórí afẹ́fẹ́?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkan ninu awọn ero ọkọ baaluu kan to n lọ si Texas lati Tokyo ti huwa to mu iyanu wa, ọkunrin naa fẹẹ ṣilẹkun ọkọ ofurufu lori afẹfẹ ni.
Ọkọ All Nippon Airways (ANA), ti iṣẹlẹ naa ṣẹ si, yara balẹ lojiji (emergency landing) si papakọ ofurufu Seattle-Tacoma International Airport.
Awọn ọlọpaa agbegbe naa ṣalaye pe ọjọ Abamẹta ni wọn fi iṣẹlẹ naa to awọn leti.
Iroyin sọ pe ero ọkọ ọhun ko fi gbogbo ara gbadun. Wọn ni kinni kan n da a laamu to mu ko huwa to lodi to si tun lewu naa.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, ileewosan ni wọn sare gbe e lọ lẹyin ti baaluu naa balẹ tan.
Boya wọn yoo si mu un tabi ba a ṣe ẹjọ lori iṣẹlẹ naa ko ti I fidi mulẹ rara.
Ninu ọrọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu yii, wọn ni aabo awọn ero ọkọ lo jẹ awọn logun ju ohunkohun lọ.
Koda, wọn tun le ero ọkọ yii mi-in jade nigba ti baaluu naa balẹ si Seattle, wọn ni iwa toun naa hu ko bọ si i.
Eyi kọ ni igba akọkọ ti iru iṣẹlẹ yii yoo waye
Loṣu Kẹrin, ero ọkọ kan naa gbiyanju lati ṣilẹkun ọkọ lasiko ti baaluu n lọ lati Melbourne si Australia.
Bakan naa lo ri loṣu Kọkanla ọdun to kọja, ọkunrin kan gbiyanju laaarin irinajo lati ṣilẹkun ọkọ ofurufu ilẹ America kan.
Awọn ero ọkọ naa lo dena rẹ, wọn so o mọlẹ ko ma baa mu ero ọkan rẹ ṣẹ ni.
Ni 2023, ninu oṣu Kọkanla, ero ọkan kan ṣilẹkun lojiji, awọn mẹsan-an ninu baaluu naa lo si balẹ sileewosan nitori eyi.
Baaluu naa pada balẹ si papakọ ofurufu South Korea kan.














