Wàhálà ńlá bá àwọn onílé àti oníléeṣẹ́ tí kò san owó ilẹ̀ fún ìjọba l‘Abuja

Oríṣun àwòrán, Others
Lẹyin sisọ kọkọrọ si ẹnu ọpọ ile ati ileeṣẹ niluu Abuja lọjọ Aje, ijọba apapọ ti fun awọn to kọle si ilu Abuja ti wọn ko sanwo ilẹ fun dukia wọn ni gbedeke ọjọ mẹrinla lati san owo yii tabi ki wọn foju wina ofin.
Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu da si ọrọ naa.
Eyi lo jẹ yọ ninu atẹjade kan ti Lere Olayinka, Oluranlọwọ fun Aarẹ Bola Tinubu ati Nyesom Wike, minisita fun olu ilu Abuja buwọlu fun awọn akọrin.
Atẹjade naa ni awọn dukia to wa ni agbegbe Central Area yoo san milọnu marun un naira owo itanran pẹlu owo dukia ti wọn jẹ.
Awọn to wa ni Maitama, Asokoro, Wuse II, ati Guzape yoo san milọnu mẹta gẹgẹ bii owo itanran mọ owo ti wọn jẹ ijọba.
Bakan naa ni awọn to wa ni Wuse I, Garki I ati Garki II yoo san milọnu meji naira pẹlu owo ti wọn jẹ.
Atẹjade ọhun tẹsiwaju pe awọn eeyan to ra dukia lati ọwọ eeyan mii sugbọn ti wọn kọ lati forukọ silẹ nipa gbigba iwe to yẹ ni ọjọ mẹrinla pere lati ṣe bẹ ni ẹka ijọba to n ri si ọrọ ilẹ ni olu ilu Abuja.
Eyi ko yọ awọn ti ko ti gba tabi san owo anfani lati ni ilẹ "Right of Occupancy (R-of-O)" ati iwe ẹri lati ni ilẹ "Certificate of Occupancy (C-of-O)"
Minisita fun olu ilu Abuja, Nyesome Wike wa rọ awọn olugbe ilu Abuja lati ri daju pe wọn san owo to jẹ ti ẹtọ ijọba lasiko to ba yẹ lati tunbọ fun ijọba ni anfani lati ma ṣe awọn iṣẹ idagbasoke ti yoo ṣe anfani fun araalu.

Oríṣun àwòrán, Others
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?
Ijọba apapọ bẹrẹ si ni ma sọ kọkọrọ si dukia to le din diẹ ni ẹgbẹrun marun un ni ọjọ Aje fun bi wọn ṣe kuna lati owo to yẹ laaarin ọdun mẹwaa si ọdun mẹtalelogoji.
Ọpọ awọn dukia yii lo jẹ ti ijọba, ileeṣẹ aladani ati dukia eeyan kan soso.
Ọkan lara dukia ti ọrọ kan ni Wadata Plaza to jẹ ibi ti olu ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP wa niluu Abuja.
PDP ti wa bu ẹnu atẹlu igbesẹ yii.















