Fásitì Ibadan pohùndà lórí àdíkùn tí wọ́n mú bá iye ọjọ́ tí àwon òṣìṣẹ́ yóò máa fi lọ ibi isẹ́

Yunifasiti Ibadan

Fasiti ilẹ ibadan ti kede wi pe ki gboogbo oṣiṣẹ ile ẹkọ giga naa pada si bi wọn ṣe n ṣiṣẹ wọn tẹlẹ ni gbogbo ọjọ ọsẹ, bẹrẹ lati ọjọ Aje, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹjọ ọdun yii.

Ikede naa ti alamojuto ifọrukọsilẹ ati akọwe igbimọ ile ẹkọ giga naa, G.O. Saliu buwọlu l'Ọjọru ni wọn fun ni nọmba akọsilẹ: 4647.

Ni bii ọsẹ kan sẹyin ni fasiti ilẹ Ibadan kọwẹ ranṣẹ si awọn oṣiṣẹ ti o jẹ olukọ wi pe igbimọ ile ẹkọ giga naa ti din iye ọjọ ti wọn o fi maa wa si ibi iṣẹ ku si ọjọ mẹta pere.

Igbesẹ naa ggẹ bi wọn ti wi jẹ igbiyanju lati mu nnkan dẹrun fun wọn lasiko ti gbogbo ọmọ Naijiria n kerora nitori ayọkuro owo iranwọ ori epo bẹntiro.

Inu ọgba fasiti Ibadan
Inu ọgba fasiti Ibadan

BBC Yoruba kan si awọn akẹkọọ ile ẹkọ giga naa lẹyin ti wọn ṣe ikede adinku ọjọ iṣẹ, lara wọn si fi ero wọn han wi pe ko ni bojumu ki ile ẹkọ giga naa fi gbogbo imọ to yẹ ki awọn akẹkọọ ni ninu kilaasi ikẹkọọ dun wọn nipasẹ adinku ti ile ẹkọ giga naa mu ba ọjọ iṣẹ fun awọn olukọ.

Ninu ikede ti ile ẹkọ giga naa ṣe l'Ọjọru, wọn ni, "Lẹyin ayẹwo finnifinni ti a ṣe lori bi nnkan ṣe ri lọwọlọwọ bayii, awọn alakoso fasiti yii ti pinnu lati ṣe atungbeyẹwo eto iṣẹ ṣiṣe, ki a si pada si bi a ṣe n ṣiṣẹ tẹlẹ.

A ke si awọn oṣiṣẹ lati pada si ẹnu iṣẹ gẹgẹ bi o ṣe wa tẹlẹ bẹrẹ lati ọjọ Aje, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 2023.

A rọ gbogbo oṣiṣẹ lati fi oye gbe gbogbo ohun ti o n ṣẹlẹ lọwọlọwọ bayii, gẹgẹ bi a ṣe n reti idasi ijọba lori inira to n ba gbogbo eniyan finra."

Lati igba ti aarẹ tuntun lorilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti kede iyọkuro owo iranwọ ori epo bẹntiro ni awọn ijọba ipinlẹ ti n ṣe agbekale ọkan-o-jọkan eto ti yoo mu ara dẹ araalu.

Fasiti ilẹ Ibadan jẹ ọkan lara awọn ile ẹkọ giga akọkọ ti yọọ gbe igbesẹ lati mu nnkan dẹrun nipa mimu adinku ba iye ọjọ ti awọn oṣiṣẹ fi n lọ si ibi iṣẹ, ṣugbọn laarin ọsẹ kan ni wọn tun yi ipinnu wọn pada.