Akẹ́kọ̀ọ́ fásitì FUTA jáde láyé, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fárígá, wọ́n ní àìbìkítà àwọn aláṣẹ ló ṣokùnfà ikú rẹ̀

Aworan Akẹkọọ naa

Oríṣun àwòrán, others/OSRC

Akẹkọọ onipele karun un kan ni ile ẹkọ giga fasiti imọ ẹrọ FUTA nilu Akurẹ jade laye ni afẹmọjumọ ọjọ Ẹti ọjọ karundinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 2023.

Ohun ti a gbọ ni wi pe wọn gbe akẹkọọ naa Ayọmide Akeredolu digbadigba lọ si ile iwosan fasiti naa fun itọju amọṣa awọn akẹgbẹ rẹ ni ko tete ri itọju to yẹ.

Wọn ni akẹkọọ naa gbẹmi mi nigba ti wọn n gbe e lọ si ile iwosan nla UNIMED nilu Akurẹ lẹyin ti wọn gbe e kuro ni ile iwosan fasiti FUTA.

Awọn akẹkọọ di opopna marosẹ Ilesha si Akurẹ pa

Ni igba ti ilẹ yoo fi mọ, awọn akẹkọọ fasiti naa ti bẹrẹ si nii fi ẹhonu han lori.

Gbogbo ọna to wọ fasiti naa ni wọn ti pa.

Bakan naa ni wọn tun gbegi di opopona marosẹ Ilesha si Akurẹ eyi to gba iwaju ile ẹkọ fasiti naa kọja.

Ọpọlọpọ awọn arinrinajo to n gba Akurẹ lọ si apa oke ọya ati ẹkun ila oorun orilẹede Naijiria ni wọn ha si ọna lowurọ ọjọ Ẹti nitori aisi aye ati kọja.

Awọn ọkọ to n rajo ko le ri ọna kọja

Oríṣun àwòrán, osrc

Awọn akẹkọọ fasiti FUTA naa n pe fun ikọwefiposilẹ adari ileewosan fasiti naa.

Wọn ni ọpọ awọn to wa ni ile iwosan naa ni ko kun oju iwọn ati wi pe awọn ohun elo itọju alaisan to wa nibẹ ni wọn rekọja iwulo wọn.

Awọn akẹkọọ fasiti FUTA to n ṣe iwọde ọhun ṣalaye pe akẹkọọ marun un lo ti ku laarin oṣu karun un si asiko yii nitori ohun ti wọn pe ni iwa aibikita awọn oṣiṣẹ ile iwosan fasiti naa atawọn alakoso fasiti ọhun.

Oku rẹ ni wọn gbe de ile iwosan – Alukoro FUTA

Awọn akẹkọọ taku si oju popo

Oríṣun àwòrán, osrc

Amọṣa, awọn alaṣẹ fasiti naa, ti sọ pe lootọ iṣẹlẹ to ba ni ninu jẹ ni iku akẹkọọ naa jẹ ṣugbọn o ti dakẹ ki wọn to gbe e de ile iwosan fasiti naa.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ileẹkọ fasiti naa, Adegbenro Adebanjo, awọn alaṣẹ fasiti FUTA ṣalaye pe aisan ojiji kan lo de ba akẹkọọ naa, to si ṣa dede ṣubu ni ileegbe awọn akẹkọọ fasiti naa, ti gbogbo akitiyan lati ra ẹmi rẹ pada si ja si pabo.

“Nnkan bii agogo mẹsan an ku iṣẹju mẹwaa ni wọn gbe e de ile iwosan fasiti FUTA lalẹ Ọjọbọ. Ṣugbọn oku ni wọn gbe e de ibẹ.”

Atẹjade naa ni gbogbo akitiyan lati doola ẹmi rẹ lo ja si otubantẹ.