Ọba ìlú Akure gbéńá wojú gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo nítorí ọdún Aheregbe

Oríṣun àwòrán, Akeredolu/Deji Akure
Wọn ti ṣe ayẹyẹ ọdun Aheregbe lonii niluu Akure, to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo, gẹgẹ bo ṣe maa n waye lọdọdun.
Ọdun naa jẹ ọkan pataki lara awọn ọdun iṣembaye to maa n waye niluu Akure, ninu eyii ti aṣa to rọ mọ ọdun naa ko faye gba ki ẹnikẹni ṣi ṣọọbu tabi ile itaja rẹ.
Ṣaaju ni Deji ti ilu Akure, Ọba Aladetoyinbo Aladelusi, ti kọkọ paṣe pe ki ẹnikẹni ma ṣi ṣọọbu lasiko ọdun naa amọ ijọba ipinlẹ Ondo pa aṣẹ naa da.
Deji Akure paṣẹ ki wọn ma ṣi ọja
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Deji ilu Akure, Micheal Adeye fi sita lo ti sọ pe gbogbo ọja gbọdọ wa ni titi pa lọjọ Ẹti,
ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023, titi ti ayẹyẹ ọdun naa yoo fi pari.
Inu atẹjade ọhun ni Deji ti rọ awọn iyalọja atawọn ababalaje ki wọn maṣẹ kọti ikun si aṣẹ ọhun.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, kii ṣe gbogbo oniṣowo ni ọrọ naa kan nitori aye wa fun abala awọn oniṣowo kan lati ṣi ṣọọbu wọn.
O ni “awọn to n ta oogun lanfani lati ṣi ṣọọbu wọn lasiko ọdun naa, bakan naa ni ọdun ọhun ko sọ pe ki ẹnikẹni tabi ọkọ ma rin loju popo.”
Ẹnikẹni ko gbọdọ ti ṣọọbu pa nitori ọdun kankan – Ijọba Ondo
Ẹwẹ, lẹyin atẹjade agbẹnusọ Deji yii ni ijọba ipinlẹ Ondo tako ọrọ naa, to si sọ pe o jẹ titẹ ẹtọ araalu mọlẹ.
Ninu atẹjade tirẹ, kọmiṣọna fun eto iroyin nipinlẹ Ondo, Bamidele Ademola-Olateju sọ pe Deji ko laṣẹ lati ni ki araalu kankan ma ṣi ṣọọbu wọn tabi ta ọja.

Oríṣun àwòrán, OSRC TV
Ademola-Olateju pe akiyesi Deji si ipinnu ijọba ipinlẹ naa kan to waye lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022, nibi to ti sọ pe ko si ẹni to lagbara lati sọ pe ki awọn iyalọja gbe ṣọọbu wọn ti pa lai gba aṣẹ lọwọ gomina.
O ni “awọn araalu gbọdọ mọ pe to ba jẹ pe wọn gba aṣẹ lati ti ṣọọbu gan, awọn ṣọọbu ti wọn yoo ti yoo jẹ awọn to wa ninu ọja Ọba niluu Akure.”

Oríṣun àwòrán, OSRC TV
“A rọ baba wa, Deji ti ilu Akure ko bọwọ fun aṣẹ ijọba, ko si jawọ ninu awọn igbesẹ ti yoo maa ni awọn araalu lara.”
“A rọ awọn olugbe ilu Akure ki wọn maa ba owo wọn lọ lọjọ Ẹti gẹgẹ bii ominira ti ofin fun wọn, ko si ẹnikẹni tii yoo ti ṣọọbu tabi ọja kankan, bẹẹ si ni ko si ẹnikẹni ti yoo fi ipa mu ẹnikẹni lati ti ṣọọbu rẹ.

Oríṣun àwòrán, OSRC TV
Ki ni awọn araalu ṣe?
Lẹyin gbogbo atẹjade Deji ati ikilọ ijọba, a ṣawari pe awọn araalu tẹlẹ aṣẹ Deji lati ma ṣi ṣọọbu wọn.
Akọroyin ileeṣẹ iroyin ijọba ipinlẹ Ondo, OSRC, to bọ saarin igboro ilu Akure jabọ pe ọpọlọpọ awọn ṣọọbu lo wa ni titi pa laarin ilu naa gẹgẹ bii aṣẹ ti Deji pa ṣaaju.
Amọ ṣa, nigba ti yoo fi di ọwọ ọsan, wọn ṣi ọja Isinkan, ti awọn eeyan si bẹrẹ si n ba owo wọn lọ nibẹ.












