Ìjọba ti ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ 500 tó ń ṣiṣẹ́ lọ́nà àìtọ́ pa

Ijọba orilẹ ede Cameroon ti ti ile ẹkọ to to 494 to jẹ ti aladani ti wọn n ṣiṣẹ ni ọna to lodi si ilana ìjọba pa.
Igbesẹ yii lo waye ni o ku ọsẹ meji ti saa ile ẹkọ tuntun yoo bẹrẹ, ti wọn si tun foju sọna lati ti awọn ile ẹkọ ni ẹkun mẹfa ninu mẹwaa to wa ni orilẹ ede naa.
Gẹgẹ bi minisita fun eto ẹkọ, Laurent Serge Etoundi Ngoa ṣe sọ pupọ ninu awọn ile ẹkọ yìí ni wọn ko gba aṣẹ lọwọ ijọba, ti awọn miiran si kọ lati ṣatunyẹwo fun iwe aṣẹ ti ìjọba fun wọn.
Bakan naa lo tun bu ẹnu atẹ lu bi awọn ile ẹkọ kan ṣe n kọ ile ẹkọ si agbegbe ti ko bojumu fun eto ẹkọ.
Titi awọn ile ẹkọ pa ṣaaju ki saa eto ẹkọ to bẹrẹ ko jẹ nnkan tuntun lorilẹ ede Cameroon sugbọn ọpọ tí bu ẹnu atẹ lu bi ìjọba ṣe kuna lati maa ṣe amojuto bi awọn eeyan to n ṣe idasilẹ ile ẹkọ yoo ṣe maa tẹle ofin eto ẹkọ.
Idanilẹkọọ yoo bẹrẹ lọjọ kẹrin oṣu kẹsan, ti awọn ile ẹkọ ti ìjọba fofin de ba kuna lati ṣe ohun to tọ, ìjọba ko ni ṣi ile ẹkọ naa.








