Kí ló mú ‘Olóṣó’ àti ‘Aṣẹ́wó’ ya wọ ibùdó akọ̀ròyìn l‘Ogun, tí ariwo fi sọ?

Oríṣun àwòrán, Others
Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe lati bi ọdun mẹrin si marun-un sẹyin, ni oriṣiriṣi faaji aramanda ti n ṣẹlẹ ninu ọgba awọn akọroyin to wa ni Iwe-Irohin, Oke-Ilewo niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun.
Faaji to n ṣan lojoojumọ nibudo awọn akọroyin yii si lo mu kawọn ọlọmọge l‘Ogun maa lo anfaani rẹ lati ṣiṣẹ aṣẹwo wọn.
Amọ Yoruba ni ‘Ma fi oko mi sọna’, ọjọ kan soso ni eeyan n kọ ọ, idi si ree tẹgbẹ NUJ naa fi ṣe ikilọ nla fun gbogbo awọn olowo Nabi naa lati fi ọgba wọn silẹ lai fi akoko ṣofo.
"Awọn takọ-tabo n ba ara wọn lopọ nita gbangba laitiju ninu ọgba awa akọroyin, a ko fẹ iru iwa yii mọ"
Ẹgbẹ akọroyin, ẹka ti ipinlẹ Ogun, wa fọnmu lori bawọn ọdọbinrin, ti wọn ko n'iṣẹ meji ju iṣẹ aṣẹwo ati oloṣo lọ, se maa n ya wa si ibudo wọn.
Ninu atẹjade kan ti alaga ati akọwe tuntun fẹgbẹ naa, ti wọn ṣẹṣẹ bura fun laipẹ yii, Comrade Wale Ọlanrewaju ati Comrade Bunmi Adigun fi ranṣẹ si BBC YORUBA ni ikilọ naa ti jẹyọ.
Awọn asaaju ẹgbẹ akọroyin mejeeji naa ni awọn ko le laju silẹ mọ, maa wo iwa adojutini naa, ko maa gbilẹ si.
"Lati nnkan bi aago meje irọle, titi di oru ọjọ keji, ojoojumọ la gbọ pe faaji fi n ṣẹlẹ ninu ọgba awa akọroyin naa.
Bakan naa ni takọ-tabo yoo si maa bara wọn lajọṣepọ nita gbangba lai tiju."
"Awọn Amookunṣeka tun n lo anfaani gbigba iwa buruku yii laaye, lati maa ṣe ipade ikọkọ ninu ọgba wa"
Awọn iwa adojutini yii ni awọn oloye tuntun ẹgbẹ naa ni ko tẹ awọn lọrun, ti wọn fi ni awọn ko le gba iwa naa laaye mọ, ti ayipada rere si gbọdọ ba ẹgbẹ bayii.
Wọn ni o ṣe ni laanu wi pe inu ọgba ileeṣẹ akọroyin, to yẹ ko jẹ awokọṣe f'awọn araalu, ni awọn kan wa sọ di ile aṣẹwo ati oloṣo.
Wọn ni "ti onikaluku si n huwa to wu u, eyi ti a ko le gboju fo da mọ."
Bakan naa ni wọn ni awọn amookunṣeka tun n lo anfaani ti wọn fi gba awọn iwa buruku yii laaye, lati maa ṣe ipade ikọkọ wọn nibẹ.
Wọn wa fi ogun rẹ gbari pe opin ti de ba gbogbo iwa buruku naa lai fi akoko ṣofo.
Atẹjade naa sọ siwaju pe, gbogbo awọn iwa adojutini to n ba orukọ ẹgbẹ akọroyin jẹ kaakiri igboro, l'awọn ko nii gba laaye mọ.
Wọn wa sekilọ fun gbogbo awọn to n lọwọ si iwa ibajẹ naa lati dẹkun rẹ loju ẹsẹ.
"A ko ni gba asa mimu siga, egboogi oloro, ati rinrin gberegbere layika wa laaye mọ"
Alaga ati akọwe ẹgbẹ NUJ nipinlẹ Ogun tun jẹ ko di mimọ pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ ninu ọgba wọn to n huwa aṣẹwo, oloṣo tabi oniruuru iwa adojutini mii, ni yoo foju winna ofin.
NUJ Ogun ni oun ti fi isẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa at'awọn agbofinro nipinlẹ naa leti, to fi mọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo mii.
Siwaju sii, ẹgbẹ akọroyin naa ni oun ko tun ni gba asa mimu siga, egboogi oloro, ati rinrin gberegbere layika ọgba oun laaye mọ.
"Omi tuntun ti ru, iṣakoso to mọ ipa ti ẹgbẹ naa n ko ninu eto idagbasoke ilu ati orileede, ti gbajọba."
"Awọn eeyan to ba nilo iranlọwọ nipa igbesẹ ofin nikan la gba laaye lati sunmọ wa"
NUJ Ogun tẹsiwaju pe "Ile iwe-Iroyin kii ṣe agbegbe fun iṣẹ aṣewo ati oloṣo, tabi ọgba fun iwa ọdaran, bi ko ṣe ibi ti iwa ọmọluabi ti wa.
A wa ti f'ẹnuko wipe a nilo lati gba ileeṣẹ wa lọwọ awọn alailojuti ati iwa aibofinmu ti awọn kan ti a ko mọ n hu.
A si ti ṣetan lati jẹ ki gbogbo aye mọ pe, ọgba awa akọroyin kii ṣe ibi ti gbogbo eeyan le maa wa lati jokoo si.
Awọn eeyan to ba nilo iranlọwọ nipa igbesẹ ofin nikan soso laa gba laaye lati sunmọ ibẹ."
















