Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ yé é jápa, ẹ dúró, kí ẹ tún Nàíjíríà ṣe - Oyedepo pàrọwà

Oríṣun àwòrán, Others
Alufaa agba fun ijọ Winners ati ile isẹ iransẹ Living Faith, Biṣọọbu David Oyedepo ti ke pe ijọba apapọ lati pe se ohun to tọ fawọn araalu, lọna ati da gbogbo ikolọ Naijiria pada.
Oyedepo pa arọwa yii nigba to n ba ileeṣẹ akoroyinjọ NAN sọrọ niluu Ota, nipinlẹ Ogun.
O ni o ṣe pataki pe ki awọn eeyan duro si Naijiria, ki wọn si fọwọsowọpọ lati tun orilẹede yii ṣe.
O fikun pe o ṣe koko ki ijọba apapọ pese orisirisi ọna abayọ fun awọn ọdọ lati dẹkun bii pupọ wọn ṣe n sare lati kuro lorilẹede yii lọ soke okun.
“Gbogbo wa ni lati duro si orilẹede Naijiria lati da ogo orilẹede naa pada.
“Awọn obi ni lati tun awọn ọmọ kọ nitori kikuro lorilẹede ko ki n ṣe ohun to dara rara.
“Pupọ awọn ọmọ yii ni ko ri ibi lọ ni oke okun ti wọn wa, ti wọn ko si le wa si ile nitori itiju.
“Gbogbo wa ni a ni isẹ lati ṣe lati da ikolọ orilẹede yii pada.”















