Ọba Ebira gba ìwé ìbáwí torí kò yọjú láti gbàlejò Buhari

Oríṣun àwòrán, Ebirareporters.com
Ijọba ipinlẹ Kogi ti kọwe wa wi tẹnu rẹ si oriade tilu Ebira, Ohinoyi ti ilẹ Ebira, Ọba Ado Ibahim fun bo ṣe kuna lati fi ara han nibi ayẹyẹ igbalejo aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari lasiko abẹwo rẹ si ipinlẹ naa.
Ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kejila ọdun 2022 ni aarẹ Buhari bẹ ipinlẹ Kogi wo nibi to ti ṣi awọn iṣẹ akanṣe kan nibẹ.
Gbogbo awọn eekan nipinlẹ Kogi titi kan awọn lọbalọba lo peju lati yẹ aarẹ si, ti wọn si kii kaabọ.
Amọ ṣa, ko si ẹnikẹni to ri Ohinoyi ọba ilẹ Ebira ninu ipejọpọ naa.
Eyi gan an lo wa mu ki ijọba ipinlẹ naa kọwe si Ọbalaye ilu Ebira pe ko wa ṣe alaye ara rẹ, lori idi ti ko fi farahan fun ayẹyẹ naa.
Ẹsun wo ni ijọba fi n kan Ohinoyi, Ọba ilẹ Ebira?
Ninu lẹta kan ti oludari ọrọ oye jijẹ nijọba ipinlẹ naa, Ẹnimọla Ẹniọla buwọlu, ijọba ipinlẹ Kogi fi ẹsun kan ọba ilẹ Ebira naa pe iwa to hu jọ ẹṣẹ amọọmọda.
O ni “eleyii to lee ko ipinlẹ Kogi ati ilẹ Ebira sinu gbaga to lewu gidigidi.”
Ijọba ipinlẹ naa ni o ti n di lemọlemọ rẹ ati wi pe “iru iwa bẹẹ ko tọna rara fun ọbalaye ti o di iru ipo nla bẹẹ mu.”
Lẹta naa wa ṣakawe iwa ọbalaye naa gẹgẹ bi eyi to ko abuku ba ipo aarẹ Naijiria ati gomina ipinlẹ Kogi.
“Ihuwasi rẹ yii jẹ iwa aifinipeni si aarẹ, gomina ipinlẹ Kogi ati gbogbo awọn eeyan ilẹ Ebira.
Iwa yii si mu ọpọlọpọ ewu dani fun aabo ipinlẹ yii ati fifi ipilẹ ti ko tọ lelẹ fun ẹka lọbalọba ni ipinlẹ yii.”

Oríṣun àwòrán, Aworan iwe naa
"Ohinoyi tilu Ebira yoo foju ba iwaju igbimọ ti yoo gbe awijare gbogbo to ba kọ gẹgẹ bi esi yẹwo"
Gbedeke wakati mejidinlaadọta tii ṣe ọjọ meji pere ni ijọba ipinlẹ Kogi fun ọbalaye naa, lati fi ṣalaye ara rẹ, bibẹẹkọ igbesẹ ibawi yoo kan an lara.
Iwe naa jẹ ko di mimọ pe Kabiyesi Ohinoyi tilu Ebira yoo ṣi foju ba iwaju igbimọ ti yoo gbe awijare gbogbo to ba kọ gẹgẹ bi esi yẹwo.
Awọn ọta idagbasoke ati oloṣelu arijẹnidi madaru lo wa nidi ado oloro to bu laafin Ohinoyi – ijọba ipinlẹ Kogi
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe iṣẹlẹ ibugbamu kan waye ni owurọ ọjọ abẹwo aarẹ Buhari sipinlẹ Kogi.
Ibugbamu yii la gb pe o mu ẹmi eeyan mẹta lọ, ti ọpọ miran si fi ara ṣeṣe.
Niwaju aafin Azad ti Ohinoyi ti ilẹ Ebira ni ibugbamu naa ti waye, nigba to ku nnkan bii wakati kan ki aarẹ gunlẹ si agbegbe naa lati ṣi awọn akanṣe iṣẹ aṣepari kan nibẹ.
Ijọba ipinlẹ naa ni awọn “ọta idagbasoke” ati awọn “arijẹ nidi madaru oloṣelu” lo wa nidi iṣẹlẹ ibugbamu ọhun.
Amọ ṣa o, a ko tii le sọ boya eyi lo ṣokunfa bi Ohinoyi ko ṣe le ri aye yọju si aarẹ Buhari lasiko abẹwo naa.
Bakan naa ni ko tii si ẹni lee sọ boya kabiyesi Ohinoyi ti ilẹ Ebira ti fesi si iwe wa wi tẹnu rẹ naa.
Bẹẹ si tun ni ko si ẹni lee sọ ni pato esi ti oriade naa fun ijọba ipinlẹ Kogi bayii.
















