"Mo wà lára èrò rélùwéè tí agbébọn jí gbé àmọ́ mo jàjàbọ́ ní alẹ́"

Oríṣun àwòrán, Collage
Oriade ilu ti awọn agbebọn ti kọlu ero reluwe nipinlẹ Edo, Enogie ti Igbueben, ọba Ehizojie Eluojierior, ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu to waye ni ibudokọ reluwe naa ni Ọjọ Satide.
Ọba Eluojierior, gẹgẹ bi iwe iroyin Punch ti gbe jade, ni awọn araalu naa ṣi wa ninu ipo ibanujẹ ati ipaya lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye.
O ni ọpọ igba ni ikọlu awọn agbebọn ti waye yii, amọ ti awọn eniyan ko kọbi ara si, ki o to di iru iṣẹlẹ ijinigbe bayii.
"Awọn agbebọn fẹ ji awọn eniyan gbe lọ ni ipinlẹ Delta naa, amọ ti ko ṣeeṣe fun wọn.’’
Oriadfe naa tẹsiwaju pe "N ṣe ni gbogbo ilu Igueben pa lọlọ, ti awọn figilante, ọlọpaa ati awọn ọdẹ ibilẹ si n ṣiṣẹ lati doola ẹmi awọn eniyan"
‘’Wọn lọ sinu igbo, ti wọn si bẹrẹ si ni wa awọn eniyan titi di owuro Ọjọ Isinmi.’’
‘’Mo gbọ wi pe wọn gbiyanju lati ji awọn eniyan gbe lọ ni ipinlẹ Delta naa, amọ ti ko ṣeeṣe fun wọn.’’
‘’O ya gbogbo wa lẹnu iṣẹlẹ to waye naa ti wọn si yinbọn lu awọn eniyan , ki wọn to ji wọn gbe lọ.’’
Ọba naa fikun un pe awọn ẹṣọ alaabo n ṣiṣẹ karakara lati doola ẹmi awọn eniyan to wa ni ahamọ awọn ajinigbe naa.
Bakan naa lo ni o da awọn eniyan loju pe awọn agbebọn ati ajinigbe naa yoo kan si awọn mọlẹbi awọn eeyan ti wọn ji gbe ọhun laipẹ, nitori naa ki wọn fi ọkan balẹ.
O tun fikun un pe igbiyanju si tẹsiwaju lati doola ẹmi awọn eniyan ti wọn jigbe.
‘’Obinrin to moribọ lasiko ikọlu agbebọn nibudokọ reluwe ṣalaye oun ti oju rẹ ri’’
Adari ẹgbẹ ọdọ to wa fun isejọba rere ati idajọ ododo ni awujọ fun agbegbe Esan, (Esan Youth for Good Governance and Social Justice), Benson Odia, ni obinrin kan to moribọ ninu ikọlu naa ti salaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye ati bi o ṣe jajabọ ninu isẹlẹ naa.
Obinrin naa lo ni oṣiṣẹ ileeṣẹ irinna oju irin naa wa lara awọn ti wọn ji gbe.
O fikun un pe iṣẹlẹ naa ti da wahala ati rogbodiyan silẹ fun awọn ara ilu.
O ni iṣẹlẹ naa waye ni nkan bi aago mẹrin irọlẹ lasiko ti awọn eniyan n gbiyanju lati wọ ọkọ oju irin lọ si Warri ni ipinlẹ Delta.
‘’Ni ọjọ buruku eṣu gbomi mu yii ni awọn eniyan to fẹ wọ ọkọ oju irin naa ti duro wamu wamu, ki awọn ajingbe naa to bẹrẹ si ni yinbọn lakọ-lakọ.
Awọn ti wọn ji gbe naa pọ, to fi mọ awọn oṣiṣẹ ati awọn arinrinajo.
Ni nkan bi aago mẹjọ alẹ ni obinrin naa jajọbọ, to si ba ara rẹ ni agbegbe Esan, ki awọn mọlẹbi rẹ to wa doola ẹmi rẹ.
‘’O ti di lemolemọ ki awọn ajinigbe maa ṣọṣẹ ni agbegbe naa.’’
Odia ni kii ṣe igba akọkọ ni yii ti awọn ajinigbe yoo ma ṣekọlu ni agbegbe naa.
O ni o ti di ohun itiju lati rin irinajo loju popo nitori awọn ajinigbe.
Bakan naa lo ni oun ko le sọ iru ẹya ti awọn ajinigbe naa ti wa, boya ọmọ Naijiria ni wọn tabi alejo.
O fikun un pe awọn yoo kesi ijọba ibilẹ ati ijọba apapọ lati wa da ibudoko awọn ọmọ ogun silẹ ni ilẹ Isan lati le da abo bo awọn araalu.
Àjọ reluwé ti ibùdókọ̀ ojú irin pa lẹ́yìn ìkọlù agbébọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to ṣamojuto irinna oju irin lorilẹede Naijiria, NRC ti sọ agadagodo sẹnu ọna ibudokọ oju irin Igueben nipinlẹ Edo pa.
Ajọ reluwe lorilẹede Naijiria ni eyi di dandan pẹlu ipenija ọrọ aabo to n waye nibẹ.
Iṣẹlẹ ikọlu awọn agbebọn naa lo waye ni ibudokọ oju irin ọhun, nibi ti wọn ti ji ọgọọrọ ero lọ, tawọn miran si fi ara gba ọgbẹ.
Isẹlẹ naa lo waye lai tii pe ọdun kan ti awọn agbebọn kọlu ọkọ oju irin to n lọ silu Kaduna lati Abuja.
A ko mọ igba ta si ibudokọ reluwe ti ikọlu ti waye ni Igueben pada - NRC
Ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 2022 ni isẹlẹ oju irin Abuja si Kaduna waye ninu eyi ti awọn arinrinajo mẹrinla ti ku, ti wọn si tun ji marundinlaadọrin miran gbe.
Ajọ reluwe Naijiria kede pe awọn ko lee sọ bayii, deede igba ti wọn yoo ṣi ibudokọ reluwe naa pada.
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Edo ti kede pe awọn ajinigbe ti ji ẹgbẹlẹgbẹ ero to fẹ wọ ọkọ oju irin gbe ni ibudokọ reluwe igueben nipinlẹ Edo lọ silu Warri, to wa nipinlẹ Delta.
Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo, Chidi Nwabuzor salaye pe irọlẹ ọjọ Satide ọjọ Keje osu Kinni ọdun 2023 ni isẹlẹ naa waye.
Atẹjade kan to fi sita lẹyin isẹlẹ naa salaye pe ọpọ ero reluwe naa lo fi ara gba ọgbẹ ọta ibọn nigba ti awọn ajinigbe naa, to gbe ibọn AK 47 lọwọ ya bo ibudo reluwe naa.
Ileesẹ ọlọpaa Edo fikun pe se ni awọn ajinigbe naa n yinbọn laibikita soju afẹfẹ, ki wọn to ji awọ arinrinajo naa gbe lọ sinu igbo nla kan.
“Ọpọ awọn ero ti ajinigbe gbe salọ ni ọgbẹ ọta ibọn wa lara wọn, ọga ọlọpa fun ẹkun Igueben atawọn eeyan rẹ si ti se abẹwo sibi isẹlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, NRC
"Awa ọlọpaa, ọdẹ ibilẹ, fijilante atawọn osisẹ alaabo tijọba Edo ti n wa ero ti agbegbọn gbe lọ ninu igbo"
Koda, awọn osisẹ alaabo fun ijọba ipinlẹ Edo, awọn fijilante, ọdẹ ibilẹ atawọn ọlọpaa si lo wa nibudo reluwe naa lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn ero reluwe naa.
A ti bẹrẹ si ni gbọn gbogbo igbo to wa lagbegbe naa wo finni-finni lati doola ẹmi awọn eeyan ti ajinigbe naa gbe lọ, ta si tun ri awọn ajinigbe naa mu.”
Bẹẹ ba gbagbe, igba akọkọ kọ ree ti awọn ajinigbe yoo ji ero gbe lọ ninu ọkọ reluwe, ti wọn yoo si tun pa ọpọ eeyan nigba ti awọn miran yoo fi ara gba ọgbẹ.
Iru isẹlẹ yii ti waye lọjọ Kejidinlọgbọn osu kẹta ọdun 2022 loju irin reluwe Abuja si Kaduna ninu eyi ti eeyan mẹrinla ti ku, ti agbebọn si ji eeyan mẹtalelọgọta gbe lọ.
















