Wọ́n rán EFCC láti wádìí mi tórí bàlúù ti mo rà - Adeboye

Oríṣun àwòrán, RCCG
Pasitọ agba ni ijọ The Redeemed Christian Church of God, RCCG lagbaye, Pasitọ Enoch Adeboye ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri pẹlu ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ atawọn iwa aitọ miran lorilẹede Naijiria, EFCC nitori baluu aladani to ra lọdun diẹ sẹyin.
Bi ẹ ko ba gbagbe pe lọdun 2015, ni eekan iranṣẹ Ọlọrun yii ra baluu tuntun Gulfstream G550 kan fun isẹ iransẹ rẹ.
Amọ se ni igbesẹ rira baluu naa fa ọpọlọpọ awuyewuye paapaa lori ayelujara nigba ti awọn eeyan kan n bu ẹnu atẹ lu u pe oun pẹlu ti darapọ mọ awọn pasitọ to n rẹ ọmọ ijọ jẹ.
Sugbọn Pasitọ Adeboye wa ṣalaye lori isẹlẹ naa ninu iwaasu rẹ nibi iṣọ oru oloṣooṣu ‘Holy Ghost service’ akọkọ ti ijọ naa ṣe lọdun 2023.
Adeboye fawọn olujọsin pe gbogbo iwe aṣuwọn owo oun ati ti ijọ RCCG ni ajọ EFCC gbọn yẹbẹyẹbẹ lasiko naa, lati tanna wadii aṣemaṣe gbogbo to lee suyọ nipasẹ baluu to ra naa.

Oríṣun àwòrán, RCCG
"Ariwo lori baalu rira naa mu idaamu ba ọkan mi amọ Ọlọrun ni ki n de fila mawobẹ"
Daddy G.O, gẹgẹ bi ọpọ ṣe maa n pe iranṣẹ Ọlọrun naa, ṣalaye pe ariwo ati awọn ọrọ alufansa to tọ baluu rira naa lẹyin, mu ọpọ idamu ba ọkan oun ki Ọlọrun to fi oun lọkan balẹ pe ki oun de fila mawobẹ lori ẹnu ọmọ araye.
“Lọdun diẹ sẹyin ti Ọlọrun pese baluu fun wa, oniruuru ariwo lo ti ẹyin rẹ jade. Ọpọ eeyan lo n tabuku mi lọtun ati losi.
Wọn tilẹ ran ajọ EFCC si mi lati wa ṣe iwadii ibi ti mo ti ri owo ra baluu.”
Baba Adeboye ṣalaye siwaju sii pe kii ṣe tori irinajo afẹ loun ṣe ra baluu bikoṣe nitori pe iṣẹ iranṣẹ ti Ọlọrun gbe le oun lọwọ ti fẹju si i.
O ni ko si si bi oun ṣe lee moju to o nipasẹ wiwọ baluu ero, eyi lo mu ki oun ra baalu aladani.
‘Awọn alainiṣẹ nikan lo lee raye ati maa lọ sibi ipade ipolongo awọn oloṣelu’
Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, alufaa Adeboye sọ pe asiko oṣelu ni orilẹede Naijiria wa bayii, ti ọpọ awọn oloṣelu si n kaakiri lati beere fun ibo araalu.
Amọṣa, o ni lọpọ igba ti oun ba ri obitibiti ero nibi awọn ibudo ipolongo ibo, ọkan oun maa n poruru ni.
Daddy G.O ni ohun to maa n sọ si oun lọkan ni pe awọn ti ko niṣẹ, lo n fara han lawọn ibudo ipolongo ibo wọnyii.
“Bi mo ba ri awọn ọpọ ero ti wọn n ko ara jọ pọ, bi mo ba si wo wọn daadaa, awọn ọdọ ni mo maa n ri to pọ julọ nibẹ.
Bi mo ba ti ri ẹgbẹlẹgbẹ awọn ọdọ yii, ohun to maa n wa si mi lọkan ni pe afi alainiṣẹ ẹda lo le maa lọ si awọn eto ipolongo ibo wọnyii.
Lẹyin idibo, ki ni yoo kan wọn tabi tọ si wọn?

Oríṣun àwòrán, RCCG
‘Woli to ba sọ pe ẹni bayi ni yoo bori ibo 2023 n tan yin jẹ ni’
Eekan iranṣẹ Ọlọrun naa tun tẹsiwaju pe ọpọ eeyan lo ti n bi oun pe ki ni Ọlọrun sọ nipa eto idibo apapọ Naijiria ti yoo waye lọdun 2023.
Amọṣa, Adeboye ni Ọlọrun ko tii sọ ohunkohun fun oun nipa rẹ.
O ni awọn wolii kan ti n sọ asọtẹlẹ loriṣiriṣi nipa eto idibo ọdun yii ṣugbọn ahunjọ ọrọ lasan ni.
O ni ohun ti oun le sọ bayii ni ki awọn ọmọ Naijiria lọ gba kaadi idibo wọn, ki wọn si dibo bi ẹmi ba ṣe dari wọn.
O ni ẹtan lasan ni gbogbo awọn to n sọ asọtẹlẹ bayii pe ẹni kan ni yoo bori ibo aarẹ n sọ.
“Ẹnikẹni to ba n sọ asọtẹlẹ bayii pe ẹni kan bayii ni yoo bori ninu ibo yii, n tan yin jẹ ni















