Tọkọtaya pàdánù ẹ̀mí wọn lẹ́́yìn tí wọ́n dáná èédú láti pa otútù ní Kano

Oríṣun àwòrán, others
Okùnrin kan, Sulaiman Idris ati iyawo rẹ Maimuna Halliru ni awọn ara agbegbe Kwa nipinlẹ Kano ṣawari oku wọn nínu yara wọn níbi ọjọ meji sẹyin.
Sulaiman, ẹni ọdun mejidinlọgbọn to jẹ oni keke lo ṣe igbeyawo pẹlu iyawo rẹ Maimuna, ẹni ogun ọdun ni oṣu mẹwaa sẹyin.
Iya Sule, Mallama Binta Muhammad salaye pe ohun ibẹru lo jẹ fun oun nigba to n gba ipe pe ọmọ ohun tí jade laye
"N ko le salaye bi ọrọ ṣe de bami, mo kọkọ ro pe boya wọn fun awọn ọmọ naa ni majele ni ṣugbọn mo ti gbọ ohun tó fa iṣẹlẹ naa.

"Wọn ní edu tí wọn tan lati fi pa otutu to mu lo ṣekupa wọn.
"Emi ati awọn tọkọtaya ko gbe apapọ niluu kana, mo sì ba wọn sọrọ níbi ọjọ mẹta sẹyin kí iṣẹlẹ naa to waye.
"Bíi pe wọn ti mọ ohun to fẹ sẹlẹ ni, niṣe ni wọn tẹnu mọ pe ki n ba awọn kí awọn aburo wọn.
"Sule ni akọbi mi to o sì ni aburo mẹsan an."
Iya iyawo, Maryam Muhammad pelu omije loju lo fi salaye pe oun ko ti igbagbọ pe irufẹ iṣẹlẹ naa waye to si gba ẹmi tọkọtaya.
Hussaini Zakiru, alabagbe ati ọrẹ Sulaiman sapejuwe oloogbe gẹgẹ bii ẹni to ni ẹran ifẹ lára.
O ni oun rí Sulaiman kí iṣẹlẹ naa to waye.
Kí ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ lori iṣẹlẹ naa?
Gẹgẹ bi ohun ti ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ, awọn tọkọtaya naa ni ko kuro ninu yara wọn lẹyin ti wọn dana edu naa ni ọjọ keji, oṣu kini, ọdun 2023,
to si jẹ pe iya agba ọkọ lo fipa ja ilẹkun, to si se alabapade oku tọkọtaya.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Abdullahi Kiyawa, ninu atẹjade to fi lede ni kete ti ileeṣẹ ọlọpaa gbọ si iṣẹlẹ naa ni wọn morile agbegbe naa.
Kiyawa ni ibi tí awọn ti ń gbe oku awọn tọkọtaya naa ni awọn kẹfin ina edu tí wọn dasilẹ, tí iwadii sì fihan pe ina edu naa lo sokunfa iku ojiji naa















