"Ṣeyi Makinde ni yóò kéde olùdíje fún ipò ààrẹ tí àwa Gomina G5 yóò ṣe àtìlẹ́yìn fún" - Wike

Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ti ṣe alaye wi pe Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ni yoo kede oludije fun ipo aarẹ orilẹede Naijiria ti apapọ ẹgbẹ awọn Gomina ẹgbẹ oṣelu PDP labẹ asia "G5" yoo ṣe atilẹyin fun ninu eto idibo ti yoo waye lọdun yii.
Saaju ni Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom ti o je alakoso ẹgbẹ G5 ṣe alaye fun ọgọrọ awọn eeyan ti o korajọpọ si ibi iṣide ipolongo ibo fun saa ikeji Ṣeyi Makinde ni gbagede Mapo, nilu Ibadan wi pe ẹgbẹ oṣelu PDP nikan ni awọn n kọ ibi ara si lọwọlọwọ bayii.
Bakan naa lo parọwa si awọn eeyan naa lati dibo fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP to n dije ninu eto idibo ti yoo waye lọdun yii, bẹrẹ lati ori oludije si ipo Gomina ati awọn to n dije du ipo ile igbimọ aṣofin, ṣugbọn ko sọ ohunkohun nipa ipo aarẹ orilẹede yii.

Lasiko ti Wike gba ẹrọ gbohungbohun, o kin ọrọ Ortom lẹyin wi pe gbogbo ẹni to n dije du ipo ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ni ki awọn eeyan dibo fun, pẹlu alaye wi pe Gomina Ṣeyi Makinde ni yoo kede oludije fun ipo aarẹ ti ẹgbẹ G5 yoo ṣe atilẹyin fun ninu eto idibo si ipo aarẹ.
Lẹyin ti Wike sọ eleyii ni ariwo nla sọ nibi ipejọpọ naa, ti pupọ ninu awọn ti o wọ aṣọ ipolongo ibo fun Makinde si bẹrẹ sini pariwo Atiku titi ti Wike gbe ẹrọ gbohungbohun silẹ.
Ọpọ awọn oloṣelu lo wa nibi ipejọpọ naa, bẹrẹ lati ori awọn Gomina ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọn pe ni G5(Nyesom Wike ti ipinlẹ Rivers, Okezie Ikpeazu lati ipinlẹ Abia, Samuel Ortom ti ipinlẹ Benue, Ifeanyi Ugwuanyi lati ipinlẹ Enugu ati Ṣeyi Makinde ti o jẹ olugbalejo.

Lara awọn ti o tun wa nibi ipejọpọ naa ni Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe, Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ondo, Oluṣegun Mimiko ati bẹẹbẹẹ lọ.
Gbajugbaja olorin Fuji, Saheed Osupa ati Taye Currency lo fi orin da awọn eeyan lara ya nibi ipejọpọ naa.
Àwọn gómìnà G-5 balẹ̀ sí Ibadan láti ṣíde ìpolongo ìbò sáà kejì Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Others
Lonii ni Gomina Ṣeyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ yoo ṣide ipolongo ibo fun saa keji.
Akanṣe eto naa yoo aye ni gbagede Mapo niluu Ibadan.
Nibi ti awon Gomina mẹrin mii ti wọn wa ninu ẹgbẹ kan naa, 'G5' pẹlu Makinde, Nyesom Wike ti ipinlẹ Rivers, Okezie Ikpeazu ipinlẹ Abia, Samuel Ortom ti Benue ati Ifeanyi Ugwuanyi ti ipinlẹ Enugu yoo ti peju pesẹ.
Ọkanojọkan aworan awọn Gomina naa lo fọn kaakiri igboro ilu Ibadan saaju abẹwo wọn l'Ọjọru.
Awọn Gomina Maraarun naa lo n tako oludije si ipo aarẹ orilẹede yii labe asia PDP, Atiku Abubakar, lori ẹsun wi pe o n gbe lẹyin alaga agbe naa, Iyorcha Ayu ti wọn fẹ ki o kọwe fi ipo silẹ.
Titi di asiko yii, awọn Gomina naa ko tii kede ẹni ti wọn fẹ fun ipo aarẹ orilẹede Naijiria.
Iroyin to n ja rainrain ni pe o ṣeeṣe ki ikede naa waye nilu Ibadan lonii.















