Ọrọ̀ ajé ọ̀pọ̀ orílè-èdè àgbáyé ni yóò dojúkọlẹ̀ ní 2023- IMF ṣe ìkìlọ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ọpọlọpọ orilẹede agbaye ni yoo dojukọ daku daji ọrọ aje ninu ọdun titun yii.

Ajọ to risi eto-ọrọ aje lgbaye International Monetary Fund lọ fi ikilọ yii sita.

Oga agba ajọ naa, Kristalina Georgieva sọ pe 2023 yoo “Lagbara” ju ọdun to kọja lọ fun orilẹede bii Amẹrika, EU ati China nitori wi pe ọrọ-aje wọn yoo lọra lọdun yii.

Eyi ko ṣẹyin ogun laarin Ukraine ati Russia, afikun to de ba awon eroja,ati itankale Covid ni China.

Ni Oṣu Kẹwa ọdun 2022 IMF ge iwọn idagbasoke eto-ọrọaje agbaye rẹ fun 2023.

Kristalina ni ireti wa pe idakan ninu idamẹta eto ọrọ aje lagbaye ni yoo doju kọ iṣoro.

Paapaa julo awọn orilẹ-ede ti ọrọ aje wọn dara naa yoo ni adojukọ tii awọn ọgọọgọrun miliọnu eniyan yoo ni iṣoro ninu eto isuna wọn lọdun yii.

Katrina Ell, onimọ-ọrọ aje ni Sydney so , fun BBC ninu ifọrọwerọ re nipa abajade igbelewọn rẹ nipa idagbasoke ọrọ-aje lagbaye.

O ni oko owo Yuroopu ati Amẹrika yoo ni ifasẹyin latari ọrọ aje ti yoo ṣe segesege

Ni ọjọ Abameta ọsẹto kọja,olori orilẹ-ede China Xi Jinping ninu ọrọ rẹ fun awọn ọmọ orilẹede China pe fun iforiti ati iṣọkan papa julọ bi orilẹede ohun se n wo inu iṣakoso titun.

Ọsẹsẹ kí owo awọn orilẹede ti ko lagbara sọ iyi rẹ nu latari ijamba ti yoo deba ọrọ aje lagbaye.

Arabinrin Georgieva kilọ pe China,ilu ti ọrọ aje rẹ tobijulo lẹyin orilẹede Amẹrika yoo ni adojukọ ninu eto-ọrọ aje rẹ ni ibeere ọdun 2023.