Ìjọba ti ibùdó epo bẹntiróòlù méje pa fẹ́sùn wí pé wọ́n ń ta epo ju iye tí ìjọba fọwọ́ sí lọ

Oríṣun àwòrán, Others
Ìjọba àpapọ̀ ti kéde pé àwọn ti ti àwọn ibùdó epo bẹntiróòlù méje káàkiri orílẹ̀ èdè yìí pa nítorí pé wọ́n ń ta epo bẹntiróòlù ju iye tí ìjọba ní kí wọ́n máa tà á lọ.
Ìjọba ní àwọn ibùdó náà ń lòdì sí òfin tó de epo bẹntiróòlù ọdún 2021 ní èyí tí wọ́n ní ó ń fa ọ̀wọ́n gógó káàkiri orílẹ̀ èdè yìí.
Adarí àjọ Nigerian Mainstream and Downstream Petroleum Regulatory Authority, Farouk Ahmed tó sọ̀rọ̀ náà fáwọn akọ̀ròyìn ní ìlú Abuja ṣàlàyé pé gbogbo àwọn lẹ́nulọ́rọ̀ lẹ́ka epo bẹntiróòlù ni àwọn ti bá jíròrò lórí ìgbésẹ̀ náà.
Ahmed ní lára àwọn tí àwọn bá jíròrò ní ẹgbẹ́ àwọn alágbàtà epo bẹntiróòlù, IPMAN, àwọn alágbàtà ibùdó epo bẹntiróòlù, DPPMAN àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ó ní pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ wí pé gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kan ni àwọn ti bá jíròrò àti pé ìjọba máa ń ṣe àmójútó ẹ̀ka epo bẹntiróòlù síbẹ̀ àwọn ibùdó epo bẹntiróòlù ń ta epo bẹntiróòlù fún àwọn alágbàtà ju iye tí ìjọba lọ́wọ́ sí lọ.
Ó fi kun pé ìjọba mọ̀ wí pé owó tí wọ́n fi ń gba ọkọ̀ tí wọ́n fi ń gbé epo bẹntiróòlù lọ sí ibi tí wọn yóò ti máa tàwọ́n ti gbé owó lórí si ju ti àtẹ̀yìnwá lọ síbẹ̀ àwọn ti ní àjọsọ pẹ̀lú àwọn alágbàtà náà lórí ọ̀nà tí wọ́n yóò gbà láti yanjú rẹ̀.
“Owó tí wọ́n ń fi le orí epo bẹntiróòlù ti wọ́n púpọ̀ jù bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iye tí wọ́n ń rà á lọ́wọ́ àjọ NNPC jẹ́ owó péréte.”
“Ati bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn alágbàtà epo yìí sọ̀rọ̀ lórí ọ̀nà àbáyọ sí ọ̀wọ́n gógó owó ọkọ̀ ṣùgbọ́n wọn ò gbọ́ tí wọ́n sì ń fi owó kún owó bẹntiróòlù ju bó ṣe yẹ lọ.”
“Ìdí nìyí tí a fi gbé ìgbésẹ̀ títi àwọn ibùdó ilé epo ta tì pa gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ná, ibùdó méje lá ti tì báyìí ná.”















