Mà á ri dájú pé gbogbo ètò ìdìbò 2023 kẹ́sẹjárí – Buhari

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Others

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti ní ọdún tó ṣe pàtàkì sí ìgbésí ayé àwọn ọmọ Nàìjíríà nítorí ọdún yìí ni ìjọba tuntun yóò tún gba ipò àti àkóso láti tún tukọ̀ Nàìjíríà fún ọdún mẹ́rin mìíràn.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni kú ọdún tuntun tí a wọ̀ lónìí ni ààrẹ Buhari tún sọ àrídájú rẹ̀ pé òun máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé ètò ìdìbò tó máa wáyé máa jẹ́ èyí tá gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwo bọ̀.

Buhari ní ètò ìdìbò náà kò ní ní kọ́nú-n-kọ́họ nínú rárá nítorí òun kò ní fi àyè gba ṣíṣe èrú ìbò ní gbogbo ààyè.

Bákan náà ló fi kun pé àwọn ọmọ Nàìjíríà gbọ́dọ̀ sa ipá wọn láti ri dájú pé ètò ìdìbò náà lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀ kì wọ́n sì yàgò fún àwọn ìwà tó le mú ètò ìdìbò náà ní ẹja ń bákàn nínú.

Ààrẹ tún rọ àwọn ènìyàn láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò láti lè ri dájú pé ètò ìdìbò náà kẹ́sẹjárí.

Gbogbo ìgbà ni mò ń gbàdúrà kí ẹni tí yóò gbapò lọ́wọ́ ṣe dada jù mí lọ - Buhari

Aworan Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Others

Aarẹ Muhammadu Buhari ni gbogbo agbara oun loun saa lati ṣe dada fun orilẹede Naijiria, to oun si n gba ladura pe ẹni ti yoo gba ipo lọwọ rẹ ṣe dada julọ.

Buhari sọ eleyi ninu atẹjade to fi ki awọn ọmọ orilẹede Naijiria ku orire ọdun tuntun, to si gba adura fun ilọsiwaju orilẹede naa.

Aarẹ ni oun tẹwọgba oriyin ati ebu ti awọn ọmọ Naijiria fi ransẹ si oun sugbọn gbogbo agbara oun ni oun saa lati ṣe dada fun orilẹede Naijiria,

“Gbogbo oriyin ati ebu tin ni mo tẹwọgba sugbọn mo fẹ ki gbogbo ọmọ Naijiria mọ pe mo saa gbogbo agbara mi lati sin orilẹede Naijiria, ti mo si gba ladura pe ẹni ti yoo gba ipo aarẹ lọwọ mi ko ṣe dada jumilọ.

“Ko si gbe orilẹede yii de ilẹ ileri rẹ, eyi ti yoo mu orilẹede Naijiria wa lara awọn orilẹede to n lewaju ni agbaye.”

Ẹ maa jẹ ki awọn oloṣelu kan lo yin fi da eto idibo ru

Bakan naa ni Buhari rọ awọn ọmọ Naijiria lati ma sọ arawọn di ohun ija fun awọn oloṣelu lati lo fi eto alafia ru,

Aarẹ ni o ṣe dandan ki gbogbo ọmọ ilẹ yii kopa ninu eto idibo, ki wọn si ri pe idibo ọhun waye lai si rogbodoyan kankan .

“Gẹgẹ bii ọmọ Naijiria , a gbọdọ ri daju pe a kopa ninu eto idibo to n bọ, ki a si ri pe o lọ ni irọwọrọsẹ, ti a ko si gbọdọ bawọn kopa ninu rogbodiyan kankan to da idibo ru lọdun to n bọ.”

“A ko gbọdọ jẹ ki awọn oloṣelu kan lowa fi da eto idibo ru lọdun to n bọ. Ti ijọba yoo si ri pe irufẹ isẹlẹ naa ko waye rara.

Aarẹ wa fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe oun yoo ri pe ajọ eto idibo ṣe isẹ takuntakun nini eto idibo to n bọ.