Irọ́ ni pé àṣìta ìbọn ló pa Bolanle Raheem, kò sí ohun tó ń jẹ́ àsìta ìbọn - Police PRO

Oríṣun àwòrán, others
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Olumuyiwa Adejobi, ti sọ pe irọ patapata ni, pe aṣita ibọn ọlọpaa lo pa oloogbe Bolanle Raheem, ti ọlọpaa kan pa nipinlẹ Eko.
Ọlọpaa ti wọn fi ẹsun iku oloogbe Raheem kan, ASP Drambi Vandi, sọ nile ẹjọ lọjọ Ẹti pe ọta ibọn to deede fo jade ninu ibọn oun lo ṣeku pa oloogbe naa lọjọ ọdun Keresi.
Ṣugbọn ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin amohunmaworan News Central, agbẹnusọ ọlọpaa, CSP Adejobi, sọ pe ko si nkan to n jẹ aṣita ibọn.
"Ko si bi ọta ṣe le fo jade ninu ibọn, lai jẹ pe ẹni to gbe ibọn dani ba ga ibọn, to si tẹ nkan to le mu ki ọta jade"
O ni ko si bi ọta ṣe le fo jade ninu ibọn, lai jẹ pe ẹni to gbe ibọn dani ba ga ibọn, to si tẹ nkan to le mu ki ọta jade.
“Nkan to ba fi mu ki eeyan ga ibọn rẹ, o tumọ si pe onitọhun ṣetan lati yinbọn ni.”
Bakan naa lo sọ pe olu ileeṣẹ ọlọpaa ti kọwe si ajọ to n mojuto ileeṣẹ ọlọpaa, lati da ọlọpaa ti wọn fi ẹsun iku Bolanle Raheem kan, ASP Vandi, duro lẹnu iṣẹ.
CSP Adejobi sọ pe eyi yoo fun ijọba ipinlẹ Eko ni anfaani lati ba a ṣe ẹjọ “nitori pe ko ṣe e ṣe fun agbofinro to ba si wa lẹnu iṣẹ lati jẹjọ nile ẹjọ kankan”.
Iléẹjọ́ sọ Ọlọ́pàá tó pa Bolanle Raheem sọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Oríṣun àwòrán, others
Ileẹjọ Magistrate ni Ipinlẹ Eko ti sọ ọlọpaa to ṣekupa Agbẹjọro obinrin, Bolanle Raheem sọgba ẹwọn.
Eyi waye lẹyin ti Agbẹjọro agba fun ijọba ipinlẹ Eko, Moyosore Onigbanjo, SAN ti kọwe ẹsun kan ASP Drambi Vandi, fun ẹsun pe o ṣekupa arabinrin Bolanle Raheem niluu Eko.
Vandi fi arahan ileẹjọ loni lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa buwọlu idaniduro lẹnu isẹ rẹ fun igba diẹ nitori ẹsun pe o ṣe ka Iyafin Raheem.
Iwe ẹsun naa ni, “Iwọ ASP Drambi Vandi, lọjọ kẹdọgbọn ni agbegbe opopona Ajah si Lekki ṣekupa obinrin kan, Omobolanle Raheem ni ọna aitọ, eyi to lodi si ofin ipinlẹ Eko ati orilẹede Naijiria.”
Lẹyin ti agbẹjọro agba ka ẹsun naa sita, o ni rọ ileẹjọ lati sọ Vandi sọgba ẹwọn titi iwadi yoo fi wa sopin lori isẹlẹ naa.
Onidajọ agba fun ileẹjọ Magistrate, Adeola Olatunbosun wa buwọlu ipe na, to si palasẹ pe ki Vandi lọ maa gba atẹgun lọgba ẹwọn Ikoyi
Bakan naa, Adajọ Olatunbosun ti sun igbẹjọ siwaju, si ọgbọnjọ, oṣu kini ọdun 2023.
















