NBC fọnmú lórí ìdásílẹ̀ Rédíò ìjàǹgbara fún ìpolongo Yoruba Nation

Ami idamọ redio Ijangbara

Oríṣun àwòrán, Ilana Omo Oodua

Àjọ tó ń mójútó ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní Nàìjíríà, NBC ti kéde pé iléeṣẹ́ rédíò tí ẹgbẹ́ Ilana Omo Oodua fẹ́ dá sílẹ̀ fun ipolongo Yoruba Nation, kò bá òfin mu rárá.

NBC nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta ní ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù Kejìlá ọdún 2022 ní àjọ náà kò ní fi ààyè gba iléeṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ kankan láti máa lo iléeṣẹ́ wọn yàlá nílẹ̀ yìí tàbí láti òkè òkun láti máa fi da àláfíà Nàìjíríà láàmù.

Ìkìlọ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí ẹgbẹ́ Ilana Omo Oodua Worldwide kéde pé òun máa bẹ̀rẹ̀ iléeṣẹ́ rédíò kan, tí yóò máa fi gbe ètò wọn jáde èyí yóò máa ṣiṣẹ́ láti orílẹ̀ èdè Dubai.

Àsíá ẹgbẹ́ Ilana Omo Oodua àti ti NBC

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àtẹ̀jáde tí NBC fi síta

Oríṣun àwòrán, NBC

"Ko si aaye fun ileesẹ agbohunsafẹfẹ loke okun tabi ni Naijiria lati sisẹ nilẹ yii lai gba asẹ"

Adarí NBC, Mallam Balarabe Shehu Ilelah, nínú àtẹ̀jáde náà ní àwọn ọmọ Nàìjíríà kò nílò àwọn nǹkan tó le máa fa inú fun, àyà fun ní àsìkò yìí pàápàá láti ọ̀dọ̀ ẹ̀yà kankan.

Ilelah ní àwọn kò ní sí ààyè fún iléeṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ kankan yàlá rédíò àmóhùnsáfẹ́fẹ́ tàbí orí ayélujára láti máa ṣiṣẹ́ ní Nàìjíríà láì gba àṣẹ àjọ náà.

Ó fi kun pé àwọn yóò túnbọ̀ máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ alààbò tó yẹ láti fojú àwọn iléeṣẹ́ tàbí ẹnìkọ̀ọ̀kan hàn, tí wọn bá ń gbèrò láti máa fi ètò ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ fún àǹfàní ara rẹ̀ tàbí ti ẹ̀yà kan, fa ìpínyà láàrín àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Bákan náà ló rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba lójúnà àti le è ní orílẹ̀ èdè tó wà ní ìṣọ̀kan àti láti lè ṣètò ìdìbò tó gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwo bọ̀ ní ọdún tó ń bọ̀.

Àkọlé fídíò, Adewale Alebiosu: Gbogbo wa lá pésẹ̀ ní àmọ́dún, ọdún ayọ̀ lá ṣe

Rédíò Ìjàǹgbara dé fún ìpolongo ìdásílẹ̀ Yorùbá Nation - Ilana Omo Oodua

Yoruba Nation

Ẹ o ranti pe a mu iroyin wa ṣaaju pe ẹgbẹ ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Ilana Omo Oodua (IOO) ti kede pe oun ti ṣe agbekalẹ Redio Ijangbara, ti yoo wa fun ipologo ohun ti ẹgbẹ naa da le lori, eyiun Yoruba Nation.

Ninu atẹjade ti alaga ati akọwe ẹgbẹ naa, Ọjọgbọn Wale Adeniran ati Ọmọwe Tunde Amusat fi lede ni eyi ti jẹyọ.

Atẹjade naa ni Redio Ijangbara yii ni yoo jẹ redio awọn ọmọ Yoruba nile-loko, bẹrẹ lati ọjọ kinni oṣu kinni ọdun 2023.

Adeniran ati Amusat ni gbogbo eeyan lo ni anfani lati tẹti gbọ redio naa lori ayelujara.

Wọn ni bakan naa lawọn ọmọ Yoruba yoo ni oju opo kan “APP” fun redio naa lori ẹrọ ibanisọrọ wọn.

Laipẹ yii ni olori ẹgbẹ ọhun, Ọjọgbọn Banji Akintoye kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii adari ẹgbẹ naa.

Atẹjade fun idasilẹ Redio Ijangbara

Oríṣun àwòrán, Ilana Omo Oodua

"A n pe gbogbo ajijagbara ọmọ Yoruba sibi ifilọlẹ Redio ijangbara lọjọ kini, oṣu kini ọdun 2023"

Atẹjade ọhun fikun pe Redio Ijagbanra ni yoo maa sọrọ lori afẹfẹ lati ilu Dubai lorilẹede United Arab Emirate.

“A n pe gbogbo ajijagbara ọmọ Yoruba sibi ifilọlẹ Redio ijangbara lọjọ kini oṣu kini ọdun 2023.

Redio yii ni awọn agba ẹgbẹ Ilana Omo Oodua gbe kalẹ fun lilo fun iponlogo Yoruba Nation,”

Bakan naa, ẹgbẹ naa kede pe Adebayo Orire ati Alhaji Alli Oyedeji ni yoo jẹ alakoso ti yoo maa mojuto bi Redio Ijangbara yoo ṣe ṣe ohun ti wọn fẹ ko ṣe fun Ilana ọmọ Odua.