Olu Falae, akọ̀wé ìjọba tẹ́lẹ̀ àti èèkàn ẹgbẹ́ Afenifere di ọba alayé

Oríṣun àwòrán, Ondo stae government
Akọwe ijba apapọ tẹlẹ lorilẹede yii, to tun ti figba kan ri jẹ Minisita feto isuna, Olu Falae ti di ọba alaye nipinlẹ Ondo.
Ọjọbọ ni Falae tẹwọ gba ọpa asẹ gẹgẹ bii olori Ilu-Abo akọkọ ti yoo tẹri gba ade.
Ijọba ibilẹ Ariwa Akure nipinlẹ Ondo si ni ilu naa wa.

Oríṣun àwòrán, Ondo state government
Ẹ mase jẹ ki agbega awọn olori ilu sipo ọba alade da wahala silẹ - Akeredolu
Nigba to n gbe ọpa asẹ fun Olu Falaye gẹgẹ bii Oluabo ti Ilu-Abo, gomina Rotimi Akeredolu salaye bi igbesẹ naa se waye.
O ni awọn ọmọ igbimọ to wa fun agbeyẹwo oye jijẹ ti Adajọ Ajama ko sodi, eyi ti ijọba to kogba wọle nipinlẹ naa gbe kalẹ, lo gbe awọn aba kan kalẹ.
Gomina ipinlẹ Ondo ni lara aba igbimọ naa ni pe ki agbega ba ipo olori Ilu-Abo si ti ọba lalaye ti yoo maa de ade.
Gomina Akeredolu, ẹni ti Olori osisẹ ni ọọfisi gomina, Gbenga Ale soju fun, wa rọ awọn ọba alaye jakejado ipinlẹ naa lati mase gba ki ilana atunto lọbalọba naa da ija silẹ laarin awọn ilu ati agbegbe to wa nipinlẹ Ondo.
“Ọba Olu Falae jẹ ọkan lara awọn ẹni ọwọ julọ ni Naijiria”
Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ igbọpa asẹ naa, gomina Akeredolu se apejuwe ori ade tuntun naa gẹgẹ bii agba awujọ to maa n sisẹ kara.
Bakan naa lo ni idagbasoke agbegbe rẹ jẹ ọba alaye tuntun naa logun , to si tun jẹ kan lara awọn ẹni ọwọ julọ nipinlẹ Ondo ati ni Naijiria lapapọ.
Akeredolu ni ayẹyẹ gbigba ọpa asẹ oriade naa jẹ isgun to ti n duro lati fara han fun ọjọ pipẹ ati aseyọri nla fun gbogbo awọn eeyan Ilu-Abo ati ipinlẹ Ondo lapapọ.

Oríṣun àwòrán, Ondo state government
“Ọba Olu Falae jẹ ọkan lara awọn ẹni ọwọ julọ ni Naijiria”
Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ igbọpa asẹ naa, gomina Akeredolu se apejuwe ori ade tuntun naa gẹgẹ bii agba awujọ to maa n sisẹ kara.
Bakan naa lo ni idagbasoke agbegbe rẹ jẹ ọba alaye tuntun naa logun , to si tun jẹ kan lara awọn ẹni ọwọ julọ nipinlẹ Ondo ati ni Naijiria lapapọ.
Akeredolu ni ayẹyẹ gbigba ọpa asẹ oriade naa jẹ isgun to ti n duro lati fara han fun ọjọ pipẹ ati aseyọri nla fun gbogbo awọn eeyan Ilu-Abo ati ipinlẹ Ondo lapapọ.
Mo setan lati mu idagbasoke to loori ba ilu mi - Ọba Falae
Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ igbọpa asẹ tuntun naa, oriade tuntun ọhun, Oluabo ti Ilu-Abo, Ọba Olu Falae ni oun setan lati sa ipa oun fun agbega ilu naa.
Bakan naa lo ni oun yoo fi ọwọsowọpọ pẹlu awọn eeyan naa lati ri daju pe ilu naa ko mẹẹri laarin awọn ilu yoku nipinlẹ Ondo.

Oríṣun àwòrán, Olu Falae
Ta ni Olu Falae to di ọba tuntun?
Ọjọ Kọkanlelogun osu Kẹsan ọdun 1938, eyiun ọdun marundinlaadọrun sẹyin ni wọn bi Ọba Olu Falae nilu Abo nipinlẹ Ondo.
Orukọ awọn obi rẹ ni Oloye Joshua Alekete ati Abigael Aina Falae.
Onisowo koko ni awọn obi rẹ amọ ọmọ ọdun mẹjọ pere ni Olu wa nigba ti iya rẹ ku lasiko to n rọbi ọmọ kan.
Iya iya rẹ lo tọ dagba, to si lọ sile ẹkọ girama Igbobi nilu Eko lẹyin to pari iwe alaksọbẹrẹ r tan.
Bakan naa lo kawe fasiti rẹ ni ẹka imọ nipa ọrọ aje nile ẹkọ fasiti Ibadan, to si bẹrẹ isẹ ọba.
Falae dije labẹ asia ẹgbẹ oselu Alliance for Democracy, AD lọdun 1999 gẹgẹ bii oludije sipo aarẹ
O ni igbega diẹ diẹ titi to fi di Akọwe agba fun ijọba Naijiria lọdun 1986, to si tun di Minisita feto isuna lọdun 1990 laye ijọba ologun Ibrahim Badamosi Babangiga.
Nigba to fẹyin ti lẹnu isẹ ọba lọdun 1990 naa, o dara pọ mọ eto iselu.
Nigba tijọba Sani Abacha da idibo ọdun 1993 ti Oloye MKO Abiola ti jawe olubori nu, o ju Falae sẹwọn amọ to gba ominira lọdun 1998 lẹyin ti Abacha ku tan.
Falae dije labẹ asia ẹgbẹ oselu Alliance for Democracy, AD lọdun 1999 gẹgẹ bii oludije sipo aarẹ pẹlu OloyeOlusegun Obasanjo, tẹgbẹ oselu PDP.
Lati igba naa si ni Olu Falae ti pada lọ joko si ilu abinibi rẹ, Ilu-Abo, o yẹ oye nibẹ, ko to wa di oriade nibẹ bayii.















