Kí ló fa ìfaǹfà láàrín Biola Adekunle, gbajúmọ̀ òṣèré àti alágbàtà fíìmù tó fi bú sẹ́kún?

Oríṣun àwòrán, Biola Adekunle/Instagram
Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Biola Adekunle ti ké gbàjarè sí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti gba òun kalẹ̀.
Ńṣe ni gbajúmọ̀ òṣèré náà bẹ̀rẹ̀ sí ní wa ẹkún mu nínú fídíò kan tó fi sójú òpó Instagram rẹ̀.
Ohun tó ń pa òṣèré náà lẹ́kún gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ nínú fídíò náà ni pé alágbàtà eré sinimá kan jẹ òun lówó láti bíi ọdún mélòó kan sẹ́yìn tí onítọ̀hún sì kọ̀ láti san owó náà padà fún òun.
"Alagbata fiimu naa ni ki n lọ se ohun ti mo ba fẹ se lori owo mi"
Ó ní alágbàtà eré náà ni òun ta eré kan tí òun ṣe ní ọdún 2018 fún àmọ́ tí onítọ̀hún kọ̀ láti san owó òun padà láti ìgbà náà.
Biola Adekunle ṣàlàyé pé nínú mílíọ̀nù kan náírà tí òun ta fíìmù náà fún alágbàtà ọ̀hún, ọdún tó kọjá ló tó san ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta náírà fún òun padà nígbà tí òun fi pípè dà á láàmú.
Ó ní gbogbo ìgbìyànjú láti gba owó òun padà ló já sí pàbó, tí alágbàtà náà sì ń sọ fún òun pé kí òun ṣe ohun ti òun bá fẹ́ ṣe.
"Ẹ bá bẹ alágbàtà fíìmù yìí pé kó sanwó mi torí ń kò fẹ́ ba jà"
Ó ní ìdí nìyí tí òun fi ń ké gbàjarè sí àwọn ọmọ Nàìjíríà láti bá òun bẹ alágbàtà náà kó san owó òun padà fún òun kí òun le rí fíìmù mìíràn gbé jáde láti ọdún yìí.
Yàtọ̀ sí owó tirẹ̀ ó ní gbajúmọ̀ òṣèré mìíràn tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ìyá Ibeji Ọmọ aráyéle náà kówó lé sinimá naa.
O ni òun ni òun dá owó náà padà fún wọn pẹ̀lú èlé nígbà tí alágbàtà náà kọ̀ láti san owó náà padà fún òun lásìkò.
Yàtọ̀ sí àwọn nǹkan tí Biola Adekunle sọ nínú fídíò náà, gbajúmọ̀ òṣèré náà tún kọ ṣojú òpó Instagram rẹ̀ pé òun kò fẹ́ jà ṣùgbọ́n kí wọ́n bá òun bẹ́ẹ̀ láti san owó òun padà.
















