Kí ló mú Portable sún sínú pòsí lọ sóde eré?

Portable jade ninu posi

Oríṣun àwòrán, Collage

Gbajumọ olorin takansufe nni, Habeb Okikiola, ẹniti gbogbo ẹniyan mọ si Portable Ọmọ Olalomi, lo tun ti gbe ara mi jade lẹyin to wọle si gbọngan ere ninu posi ni ile orin Fela niluu Eko.

Portable, ni asalẹ Ọjọru kọ ọrin fun awọn ololufẹ rẹ ni gbọngan Fela Shrine niluu Eko.

Ohun iyalẹnu ati ifoya lo bade nigba ti awọn ọkunrin mẹrin kan gbe posi wọle si gbọngan naa, ti Portable si jade lati ninu posi ọhun.

Ninu fidio fọnran kan to gba ori ayelujara kan, Portable lo gbe ara rẹ sinu posi, ti awọn ọkunrin mẹrin si gbe posi ọhun wa si gbọngan ti yoo ti ṣe ere fun awọn ololufẹ rẹ.

Eyi ki n ṣe igba akọkọ ti Portable yoo ṣe afihan ifẹ to ni si sisun ninu posi.

Se lootọ ni Portable fi sisun sinu posi lọ sode ere se etutu ọlà fun ipari ọdun?

Ọpọ awọn eeyan loju opo Twitter lo sọrọ lori iwuwasi Portable, bi awọn kan ṣe kan saara si ni awọn kan bu ẹnu atẹ lu bii o ṣe sun sinu posi.

Sweetness Spa ni; “ Etutu ipari ọdun ni bonkẹlẹ, to ba mọ ko mọ.”

Tolu Onyedikachi Gideon; “Eyi ni etutu ti Portable ṣe lati di olokiki ati ọlọla, awọn eletutu nikan lo ye.

Onyekwena Chuks; “Ẹni to mu Portable wọ awujọ awọn olokiki ni lati tọrọ aforijin lọwọ awọn ọmọ Najiria.

Chiamaka Favour Nnaeloka ni “Ti Portable ba ku ni ọla bayi, awọn eeyan maa kanu rẹ. Ki lo de to fi n sun ninu posi nigba to si wa laye.