Àdó olóró búgbàmù lọ́jọ́ tí Buhari ṣàbẹ̀wò sí Kogi, òkú sùn

Oríṣun àwòrán, @Orlando_jj
Ẹmi awọn eeyan kan ti bọ lasiko ti ado oloro bu gbamu ni agbegbe Okene nipinlẹ Kogi.
Isẹlẹ naa waye lowurọ Ọjọbọ niwaju aafin Oyinoyi ni ijọba ibilẹ Okenne nipinlẹ naa.
Isẹlẹ waye nigba to ku wakati diẹ ti Aarẹ Muhammadu Buhari yoo balẹ si ipinlẹ naa lati ṣe ifilọlẹ awọn akanṣe isẹ tijọba gomina Yahaya Bello ṣe, ni apa ariwa ipinlẹ Kogi.

Oríṣun àwòrán, @Orlando_jj
Awọn ọlọpaa ati awọn panapana ti balẹ si agbegbe ti isẹlẹ naa ti waye, to fi mọ awọn akọsẹmọsẹ nipa ado oloro.
Awọn agbofinro ni awọn ko ti le sọ pato iye eeyan to ba isẹlẹ naa rin.
Sugbọn ohun to fa ibugbamu ọhun lo ṣokunkun, ti awọn ọlọpaa si ni awọn yoo kede esi iwadi wọn ni aipẹ yii.
Gẹgẹ bii osojumikoro ṣe salaye fun ileeṣẹ BBC, o ni ibu gbamu naa waye nitosi mọsalasi to sọ mọ aafin naa.
Gbogbo akitiyan ileeṣẹ BBC lati kan si ileeṣẹ ọlọpaa lo jasi pabo.
Amọ ibugbamu ọhun ko da abẹwo Aarẹ Muhammdu Buhari si ipinlẹ naa duro.
Aarẹ Buhari si ti wa ni ipinlẹ Kogi bayii lnu abẹwo rẹ naa.















