Osun Assembly: Ilé aṣòfin yári pé òun yóò gbé agbaṣẹ́ṣe lọ sílé ẹjọ́ tí kò bá pahùndà lórí ẹ̀sùn tó fi kàn-án

Agbaṣẹ́ṣe fẹ̀sùn rìbá gbígbà kan ilé aṣòfin Osun, ọ̀rọ̀ di ariwo

Awọn ọmọ ile asofin ipinlẹ Osun

Oríṣun àwòrán, Osun House of Assembly

Onimọ ẹrọ to gba akanṣe iṣẹ omi Ilesa ni ipinlẹ Osun, Ẹnjinia Tawa William ti fi ẹsun kan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa pe wọn n beere miliọnu marun dọla lọwọ rẹ lọna aitọ lori iṣẹ naa.

Ẹnjinia William fi ọrọ naa lede lọjọbọ nilu Osogbo nigba to n dahun ibeere nipa akanṣe iṣẹ naa lori ẹrọ mohunmaworan kan nipinlẹ Osun.

Williams ni Alaga igbimo Ile aṣofin fọrọ ipese Omi lo beere owo naa eyi ti o to milliọnu marun dọla lorukọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa.

Ẹnjinia Wiliams ni ṣaaju ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa ti ṣe abẹwo si ibi iṣẹ naa, ti wọn si gbe osuba kare fun ile iṣẹ oun nitori iṣẹ ribiribi ti awọn ṣe.

Williams ni amọ iyalẹnu lọ jẹ nigbati wọn yi ohun pada, ti wọn si ṣeleri lati ba awọn oniroyin sọrọ nitori ile iṣẹ pe oun ko ṣe iṣẹ to kọju oṣuwọn.

Mo kọ jalè làti sàn riba miliọnu márùn-ún dọla - William

William ni oun kọ jalẹ lati fun awọn asofin naa ni miliọnu marun dọla owo riba ti wọn beere fun.

Bakan naa lo tun sọ pe ile ifowopamọ Islamic development Bank ati ẹka ìjọba to n ṣamojuto ohun alumọni inu omi pẹlu akọwe owo agba fun ijọba apapọ ati awọn ẹka ìjọba miran, lo ti ṣe abẹwo si ibi iṣẹ akanṣe naa, ti wọn si gbe osuba nla fun ile iṣẹ oun nitori iṣẹ ti awọn n ṣe.

 Onimọ ẹrọ Williams ni irọ ni wi pe ọkọ ayọkẹlẹ to to miliọnu marundinlọgọrin naira ni oun n gbe kiri gẹgẹ bi iroyin kan ti Gomina Adeleke gbe jade se fi lede.

O ni ọkọ akanṣe iṣẹ ti oun n lo ko ju miliọnu marundinladọta naira lọ.

Ilé ìgbìmò aṣofin fèsì

Wayi o, Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Osun, Timothy Owoeye, ti tako ohun ti Williams sọ.

Ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ iroyin rẹ, Kunle Alabi fi lede, Owoeye sọ pe " ile Igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun ko ni beere owo lọwọ ileeṣẹ ijọba tabi kongila kankan ṣaaju ki o to ṣe awọn iṣẹ to yẹ gẹgẹ bi ile aṣofin.

"Ile Igbimọ aṣofin labẹ akoso Timothy Owoeye ti fun Tawa Williams ni wakati mẹrinlelogun lati yi ohun pada lori ẹsun gbigba abẹtẹlẹ ti o fi kan ile igbimọ aṣofin.

To ba fi kuna lati ṣe bẹẹ laarin wakati mẹrinlelogun, awọn yoo gba ile ẹjọ lọ lati fọ ara awọn mọ nitori ẹsun wọnyi ko ni da ile igbimọ aṣofin duro lati ṣe ẹtọ wọn."

Àkọlé fídíò, Florence Ajimobi: Ọkọ mi fẹ́ ká rántí òun bíi Bàbá ìpínlẹ̀ Oyo tuntun
Lẹ́yìn ìkìlọ̀ Adeleke, olóṣèlú tó wà nípò tẹ́lẹ̀ dá dúkìá ìjọba padà l’Osun
Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Pupọ lara awọn osisẹ ọba tẹlẹ nipinlẹ Osun ni wọn ti bẹrẹ si ni ma da ọkọ ayọkẹlẹyo ati awọn dukia to jẹ ti ijọba ipinlẹ naa pada si ọfisi ijọba nipinlẹ Osun.

Eyi waye lẹyin ti Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke kede pe oun fun awọn osisẹ ijọba tẹlẹ ni gbedeke ọjọ meji lati da gbogbo dukia ijọba to wa isakoso wọn pada tabi ki ri ijiya labẹ ofin.

Adeleke kede lọjọ Aiku pe ki Gomina ana, Adegboyega Oyetola, iyawo rẹ, Kaafayat Oyetola ati awọn osisẹ ijọba tẹlẹ gbogbo dukia ijọba to wa lọwọ wọn pada ni kiakia.

Agbẹnusọ fun Gomina ipinlẹ Osun, Olawale Rasheed, fi idi ọrọ naa mulẹ, o ni awọn kọmisana tẹlẹ nipinlẹ Osun ti n da awọn ayọkẹlẹ ti ijọba ra fun wọn pada.

O ni awọn fun awọn osisẹ ijọba ti wọn kuna lati tẹle asẹ ijọba ipinlẹ ni gbedeke Ọjọru lati ṣe ohunnto tọ ti wọn ko ba fẹ ri ija ofin .

Awọn osisẹ ọba to kuna lati da dukia ijọba yoo ri ija ofin

Rasheed tẹsiwaju pe gbogbo awọn osisẹ ọba tẹlẹ to ba kuna lati da dukia ijọba pada ni awọn yoo fi ofin mu, ti yoo si ri ija ofin.

“Otitọ ni pe awọn kọmisana kan ti da ọkọ ayọkẹlẹ to jẹ ti ijọba pada si ọfisi ijọba nitori wọn ri pe nnkan ti wọn ṣe lọdi si ofin, iwa ọdaran ni .

“A si fun awọn yooku to kuna lati ṣe ohun to tọ laye lati gbogbo dukia ijọba to wa lọwọ wọn pada ni kiakia ti wọn ko ba fẹ ri ija ofin.

“A fun wọn di Ọjọru lati da awọn dukia naa pada si ọfisi ijọba pada.”

Olawale ni idi ti awọn fi ṣe ni dandan fun awọn osisẹ ijọba tẹlẹ lati da awọn dukia pada ni lati ma na owo ijọba si ọna aitọ nitori nnkan ti awọn fẹ fi owo ṣe pọ nipinlẹ Osun.

“A n sọ fun wọn pe ki wọn da awọn dukia yii pada nitori ijọba ko fẹ na owo miiran lori ọkọ ayọkẹlẹ nigba ti nnkan pupọ wa ti a fẹ owo ṣe.

“O to bilọnu mẹta naira ti a nilo lati fi ra awọn ọkọ ayọkẹlẹ miiran fun gbogbo awọn ẹka ijọba.”