Oyebamiji fìdí Segun Oni janlẹ̀ ní iléẹjọ́

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Ileẹjọ to n gbọ awuyewuye lori esi ìdìbo nipinle Ekiti ti wọgile ẹjọ ti Onimọẹrọ Segun Oni ti ẹgbẹ oṣelu SDP fi tako esi ìdìbò to waye losun diẹ sẹyin.

Idajọ naa waye lọjọru ọsẹ yii ni ile ẹjọ giga niluu Ado Ekiti.

Igbimọ ẹlẹni mẹta ti Onidajo Wilfred Kpochi lewaju kede Biodun Oyebanji ti ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bí ẹni tó jawe olubori ninu eto idibo gomina to waye lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹfa ọdun 2022.

Bakan na ni igbimọ ọhun tun wọgile ipe ẹgbẹ oṣelu SDP pe ki wọn yoo igbakeji gomina ipinlẹ nitori o lo ayederu iwe ẹri Waec. Ileẹjọ ni ẹjọ naa ko kuna to, ti wọn si wọgile.

Onidajọ Kpochi ni ko si nkan to buru mi gomina ipinlẹ Yobe ṣe buwọlu fọọmu ti Oyebamiji fi kede pe oun fẹ jẹ gomina.

Kpochi ni Gomina Mai Mala Buni jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, to si le soju alaga ẹgbẹ oṣelu naa .

Agbẹjọro Segun Oni ni ko tan sibẹ rara nitori idajọ naa ko tẹ awọn lọrun rara, ti awọn yoo si morilẹ ileẹjọ kotẹmilọrun laipẹ.

Abiodun Oyebamiji jawe olubori fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ekiti pẹlu ibo ẹgbẹrun mọkanlelọgọrun ati ẹẹdẹgbẹrin o le mẹta, (101703).