'Kò yẹ kí Ọlọ́run dá obìnrin sáyé rara'

Arábìnrin ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún

Oríṣun àwòrán, AFP

Arábìnrin ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Afghanistan ti ń fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn lórí bí ìjọba ṣe ń tàbùkù àwọn ọmọ obìnrin ní orílẹ̀ èdè náà.

Èyí kò ṣẹ̀yìn òfin tuntun tí ìjọba orílẹ̀ èdè náà ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé kalẹ̀ pé àwọn ọmọ obìnrin kò gbọdọ̀ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì mọ́ ní orílẹ̀ èdè náà.

Ọmọbìnrin náà pẹ̀lú omijé lójú sọ fún BBC pé bí wọ́n ṣe ń ṣe àwọn obìnrin ní orílẹ̀ èdè náà burú jáì ju bí wọ́n ṣe ń ṣe ẹranko lọ.

"Kí ni Ọlọ́run dá àwọn obìnrin fún gan?"

"Tó bá jẹ́ wí pé bí obìnrin kò ṣe ní jámọ́ nǹkankan nìyí, kò yẹ kí Ọlọ́run tilẹ̀ dá obìnrin rara".

"Bí wọ́n ṣe ń ṣe sí àwa obìnrin burú ju bí wọ́n ṣe ń ṣe sí àwọn ẹranko lọ."

Ó ní ó ṣeni láàánú pé àwọn ẹranko le jáde lọ síbi tó bá wù wọ́n àmọ́ èyí kò rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn obìnrin ní orílẹ̀ èdè àwọn nítorí àwọn obìnrin kò ní ẹ̀tọ́ láti jáde kúrò ní yàrá won.

Awon obinrin ni Afghanistan

Oríṣun àwòrán, AFP

UN bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ Taliban ní Afghanistan

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

 Ìgbìmọ̀ ètò ààbò àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN ti bu ẹnu àtẹ́ lu gbogbo ìgbésẹ̀, ìlànà àti ètò ìjọba Taliban tó ń lòdì sí ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin.

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni Taliban fi òfin de àwọn obìnrin wí pé wọn ò gbọdọ̀ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì mọ́.

Bákan náà ni wọ́n tún ní àwọn obìnrin kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn Iléeṣẹ́ elẹ́yinjú àánú tí kìí ṣe ti ìjọba mọ́.

UN ní gbogbo ìgbésẹ̀ tako àwọn obìnrin tó ń wáyé ní Afghanistan ni àwọn mọ̀ pátápátá tí akọ̀wé àgbà UN, Antonio Guterres sì ní gbogbo òfin náà ni kí ìjọba Taliban yípadà ní kíákíá.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí UN fi síta ni wọ́n ti pàrọwà sí ìjọba Afghanistan láti ṣí àwọn ilé ẹ̀kọ́ padà fún àwọn ọmọbìnrin.

Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ẹ̀dógún ọ̀hún ní òfin náà fi hàn pé ìjọba kò bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn rárá àti pé ó le dá àwọn ètò ìbójú àánú woni tó ń wáyé níbẹ̀ dúró.

Lẹ́yìn tí ìjọba kéde pé àwọn obìnrin kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn Iléeṣẹ́ elẹ́yinjú àánú mọ́ ní orílẹ̀ èdè náà ni àwọn NGO márùn-ún ti dáwọ́ iṣẹ́ dúró ní orílẹ̀ èdè ọ̀hún.

Iléeṣẹ́ Care International tó jẹ́ àjọ aṣàtìpó orílẹ̀ èdè Norway àti àjọ Save the Children ní àwọn kò lè ṣiṣẹ́ láì sí àwọn òṣìṣẹ́ àwọn tó jẹ́ obìnrin.

Àjọ Islamic Relief àti The International Rescue Committee náà ní àwọn kò le tẹ̀síwájú lórí iṣẹ́ tí àwọn ń ṣe ní orílẹ̀ èdè náà nítorí òfin ìjọba.

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni Taliban fi àwọn obìnrin márùn-ún kan sí àhámọ́ fẹ́sùn wí pé wọ́n kópa nínú ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn lórí òfin tí wọ́n fi de ètò ẹ̀kọ́ àwọn ọmọbìnrin.

Bákan náà ni wọ́n tún nawọ́ gán àwọn akọ̀ròyìn mẹ́ta.

Ọdún tó kọjá ni ikọ̀ Raji an gba àkóso ìjọba orílẹ̀ èdè Afghanistan tí wọ́n sì ti ń tẹ ẹ̀tọ́ àwọn ọmọbìnrin lójú mọ́lẹ̀.

Yàtọ̀ sí tí ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì, àwọn ilé ẹjọ́ gírámà kan ní orílẹ̀ èdè náà ló wà ní títì pa fún àwọn ọmọbìnrin.