N kò ní ìwé ẹ̀rí kankan, ojú mi rí tó níbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ń kò lówó láti gẹrún tàbí lọ sí fún ‘Rehearsal’ - Chatta

"N kò ní pẹ̀ fí àdàgbá iṣẹ́ tíátà rọ̀, iṣẹ́ àgbẹ̀ ló kàn"

Ibrahim Chatta

Oríṣun àwòrán, ibrahimchatta_lordthespis/Instagram

Gbajugbaja oṣere tiata Ibrahim Chatta, ẹniti o ṣẹṣẹ ṣe ajọyọ ọjọ ibi aadọta laipẹ yii ti kede pe o seese ki oun fi adagba ere ṣiṣe rọ laipẹ.

Ibrahim Chatta kede bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan to se laipẹ yii pẹlu ileesẹ iroyin ayelujara

Ibrahim Chatta ni ọdun marundinlogoji ni oun fi ṣe iṣẹ tiata, ninu eyi ti oun ti la ọpọlọpọ iṣoro kọja, papa julọ nigbati oun ṣẹṣẹ bẹrẹ ere tiata.

Chatta ni oun ko ni iwe ẹri ile ẹkọ kankan nitori oun kọ lo si ile ẹkọ ri.

Chatta ni lẹyin igbati oun di olokiki ninu ere tiata, ni oun ṣẹṣẹ ka iwe kẹfa tan, ti oun si wa ni ile iwe ti wọn ti ń ko nipa iṣe olukọni ni ilu Ikire.

Chatta ni Ọlọrun nikan lo gbe ori oun soke nitori pe lẹnu iṣẹ tiata ni oun ti di ilumọọka, ti oun si di olokiki.

aworan

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Chatta

"Ọpọ igba ni mo n gbe irun kunkun sori tori ko si owo ti maa fi gẹ irun"

Chatta fikun pe bo tilẹ jẹ wi pe ọmọ atapatadide ni oun, amọ ọpọlọpọ igba ni oun ma n lọ ṣe igbaradi ere tiata lai si owo lapo oun.

O ni koda nigba mii, iṣoro ati gẹ irun kikun ori oun maa n buru nitori aisi owo lapo oun.

Ibrahim Chatta ni "iriri aye kan o le ti ni titi, ko ti ni pa, ṣugbọn ọgbọn lo ma n fi kọ ni".

Osere tiata naa ni awọn iriri oun ninu ere tiata lo jẹ ki oun fẹ fi adagba ere ṣiṣẹ silẹ, ṣugbọn oun ko ni kuro ninu ere tiata patapata.

aworan

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Chatta/facebook

"O to akoko fun mi lati sinmi lẹnu isẹ tiata"

Ibrahim Chatta ni o ti to akoko ti oun gbọdọ sinmi nidi isẹ ere tiata, ti awọn ogo tuntun ti oun kọ niṣẹ tiata yoo si maa ṣe ere lọ.

O fikun pe idunnu oun ni lati ri wi pe ere tiata goke agba ni orilẹede yii.

Ibrahim Chatta tun tọka si awọn agba oṣere ti wọn ti fi adagba ere tiata rọ.

Fun apẹẹrẹ Olu Jacobs, Oga Bello, Jide Kosoko ati awọn miran ti wọn ko fi gbogbo ara ṣe sinima agbelewo mọ.

Ibrahim Chatta gun ori ẹsin

Oríṣun àwòrán, ibrahimchatta_lordthespis/iNSTAGRAM

"Mo ti dawọle isẹ agbẹ atawọn okoowo miran"

O ni lọwọlọwọ, iṣe agbẹ wa lara okoowo ti oun dawọ le, ti oun si ni ileesẹ ti oun ti n ya sinima.

Ibrahim ninu ifọrọwerọ naa ni "idunnu ọkan mi ni ki sinima agbelewo di nkan ti gbogbo agbaye yoo maa wo.

Sugbọn a gbọdọ ri pe awọn oṣere tuntun mọ ohun ti sinima ati ere tiata jẹ, nitori ọpọlọpọ awọn oṣere tuntun ni wọn ko se jina to lati ṣe ere tiata.