"Ọ̀pọ̀ èèyàn bo owó tí awakọ̀ ń fọ́n sílẹ̀ níbi Kánífà ló ṣokùnfà ikú ọ̀pọ̀ òǹwòran"

Iwàkuwà àti imúkúmú dírẹ́bà ló fá ìjàmbá Kánífà alálùpùpù ní Calabar - iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Cross Rivers, Irene Ugbo ti kede pe iwakuwa, ere asapajude ati imukumu awakọ lo fa ijamba to mu ẹmi eeyan mẹrinla lọ, ti ọpọ si farapa yanayan nibi ayẹyẹ kanifa alalupupu ni Calabar
Ugbo ni awakọ ọhun yara wọ arin ero lẹyin to sọ ijanu ọwọ ọkọ nu, ti iwadi si fihan pe o ti yoo fun ọti nigba to n kopa ninu ayẹyẹ naa.
O ni kete tawọn gbọ nipa isẹlẹ naa, ni awọn gbe awọn to farapa lọ si ile wosan ijọba to wa tosi agbegbe naa.

Ṣọọbu mi ni mo wa, nigba ti wọn pe mi pe ọmọ mi farapa nibi iwọde kanifa - Obi
Ọkan lara awọn ti Ọlọrun koyọ ninu ijamba to mu ẹmi ọpọ eeyan lọ naa, tun ba ileeṣẹ BBC sọrọ lori isẹlẹ naa.
Musa Mohammed Kutama, ẹni to jẹ baba ọkan lara awọn ọmọ to farapa, salaye pe sọọbu oun mi oun wa, nigba ti wọn ke si oun pe ọmọ oun wa lara awọn to farapa nibi iwọde kanifa naa.
Musa Kutama, ẹni ọdun mẹdogun ni ọkan lara awọn eeyan mẹrinlelogun to farapa nibi isẹlẹ naa.

"Awakọ n fi ọwọ mọto rẹ si ọtun ati osi, lo fa bo ṣe sọ ijanu rẹ nu"
Kutama salaye pe nigba ti ayẹyẹ naa n lọ lọwọ ni ọkan lara awọn awakọ wa ọkọ wa si arin ero, to si n fọn owo silẹ fun awọn eeyan.
“Bo se n fọn owo silẹ, ni awọn eeyan bo owo naa, sugbọn bo ṣe n fi ọwọ mọto rẹ si ọtun ati osi, lo fa bo ṣe sọ ijanu ọkọ nu.
O sare wọ arin ero, to si ṣekupa awọn eeyan to wa nibẹ.
Kutama ni ijọba ipinlẹ Cross River lo san owo itọju fun awọn eeyan to farapa nibi ijamba naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti kede pe awakọ ọhun ti wa ni atimolẹ awọn, ti igbagbọ si wa pe yoo fi oju ba ileẹjọ laipẹ.
Ọ̀mùtí awakọ̀ pa olóyún àti èèyàn mẹ́fà míì, àwọn mẹ́tàlá farapa ní Kánífà àwọn alálùpùpù ní Calabar

Ọjọ buruku, esu gbomi mu lọjọ Isẹgun jẹ nilu Calabar, tii se olu ilu Cross Rivers tori ijamba kan to waye lasiko ayẹyẹ iwọde opin ọdun ti wọn n pe ni Carnival.
Eeyan meje, to fi mọ oloyun kan, lo padanu ẹmi wọn lasiko ijamba naa eyi to waye ni agbegbe Bogobiri ni ilu calabar.
Bakan naa, eeyan mẹtala miran tun farapa yannayanna lasiko ijamba ọhun.
Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Cross River, Irene Ugbo, lo fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC lorukọ Kọmisana Ọlọpaa nipinlẹ naa, Balarabe Sule.
Ìran Kanifa la ni ka wo, ki iku ojiji to wọle wa - Onworan
Sule ni oun kọ le sọ pato iye eniyan ti o ba iṣẹlẹ naa lọ sugbọn oun fura oun ko awọn to farapa ati awọn to ba iṣẹlẹ na lọ si ile iwosan bi mẹta.
Iṣẹlẹ ọhun lo waye ni deede ago mẹrin irọlẹ ọjọ Isẹgun lopopona Mary Slessor nilu Calabar.
Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ni o le ni eniyan mẹwa to gbẹmi mi ninu iṣẹlẹ naa.
Ẹnikan ti ibatan rẹ padanu ẹmi rẹ nibi iṣẹlẹ naa ni iran ni awọn n wo nibi iwọde kanifa naa, eyi to ma n waye lọdọọdun ni ilu Calabar.
"Sadede ni ọkọ ajagbe sọ ijanu rẹ nu ti o si kọlu awọn ero iworan ati awọn olutaja lẹgbẹ opopona ti kanifa naa ti n waye.
Gomina Ayade wọgile asa fifi kẹkẹ alupupu ṣere nibi iwọde kanifa
Gomina Ben Ayade ti pe fun iwadii lori iṣẹlẹ naa, ninu atẹjade ti alukoro rẹ fisita
Ninu ọrọ ikẹdun rẹ, Ayade ni iṣẹlẹ naa jẹ eyiti o ṣe ni laanu nitori iyalẹnu lọ jẹ wi pe ọkọ ajagbe naa raye wọ opopona ti iwọde kanifa naa ti waye.
Gomina Ayade wa wọgile asa fifi keke alupupu ṣere nibi ayẹyẹ kanifa naa lati bu ẹyẹ fun awọn to padanu ẹmi wọn ninu ijamba naa.
Ayade ti paṣẹ pe kí awọn ẹsọ alabo mu ẹni to jẹbi isekupaniyan naa lẹyin to ti kọkọ na papa bora nigbati iṣẹlẹ naa waye.
















