Alukoro ọlọ́pàá faraya lórí ọlọ́pàá kan tó ń fa igbó pẹ̀lú àṣọ iṣẹ́

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Olumuyiwa Adejobi ti bu ẹnu atẹ lu aworan ọlọpaa kan to dabi ẹni pe o n fa igbo pẹlu aṣọ ọlọpaa lọrun rẹ.

Aworan naa si lo ti gba ori ayelujara kan eyi to n kọ awọn ọmọ Naijiria lominu.

Ọmọ Naijiria kan lo fi aworan naa ransẹ si oju opo ayelujara Adejobi lati beere fun irufẹ ijiya to tọ si ọlọpaa to n fa igbo naa.

Lẹyin to se iwadi nipa aworan naa tan, Adejobi ni irufẹ iwa bẹẹ ko jẹ itẹwọgba lẹnu iṣẹ ọlọpaa.

Alukoro fun ileesẹ ọlọpaa ilẹ wa naa lo fi ọrọ ọhun lede lasiko to n ba awọn araalu sọrọ loju opo Twitter rẹ.

Ọlọpaa to n we igbo ati alukoro ileesẹ ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Prince Olumuyiwa Adejobi @Princemoye1

"Alukoro ọlọpaa ni Kwara, tete wa osisẹ ọlọpaa to n fa igbo jade fun ijiya to yẹ"

Agbẹnusọ ọlọpaa naa ni oun gbagbọ pe ipinlẹ Kwara ni iṣẹlẹ ọhun ti waye, o si ke pe agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara lati ṣawari ọlọpaa ọhun jade fun oun.

O ni ohun ti ọlọpaa ọhun ṣe, kan oun gbọngbọn, gẹgẹ bo ṣe kan awọn araalu, ileeṣẹ ọlọpaa Kwara si gbọdọ fi ọlọpaa ọhun ṣọwọ siluu Abuja.

Adejobi wa n kọminu pe “Bawo ni ọlọpaa yoo ṣe maa fa igbo lẹnu iṣẹ pẹlu aṣọ iṣẹ lọrun rẹ?”

Àkọlé fídíò, Quest University Ghana: Ìyá àti ọmọ bọ́ sọ́wọ́ gbájúẹ̀ fásitì torí ìyanṣẹ́lódì ASUU

"Iru iwa bayii ko ni nnkan ṣe pẹlu ileesẹ ọlọpaa amọ ifẹ ọkan osisẹ ọlọpaa kọọkan"

“Mo gbagbọ pe ọlọpaa ipinlẹ Kwara ree.”

“Mo fẹ ki agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Kwara ṣawari ọkunrin yii, ko si fi ṣọwọ si ọọfisi mi ni kankan.”

“Mo ti maa n sọ tẹlẹ pe iru iwa bayii ko ni ṣe pẹlu ileesẹ ọlọpaa amọ ohun ti eeyan n fẹ lati ṣe fun ifẹ ara rẹ ni.”

“Bawo ni ọlọpaa yoo ṣe maa fa igbo lẹnu isẹ pẹlu aṣọ ọlọpaa lọrun rẹ, heee."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Nibayi, ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n di ẹbi iwa ika ti ọpọ ọlọpaa n hu ru igbo ati ọti mimu.

Bẹẹ ba gbegbe, ọjọ Keje osu Kejila ọdun 2022 ni osisẹ ọlọpa kan yin ibọn lu ọkunrin kan ni agbegbe Ajah nilu Eko.

Ọsẹ meji lẹyin igba naa si tun ni osisẹ ọlọpaa miran yinbọn lu agbẹjọro kan lọjọ ọdun keresimesi ni Ajah bakan naa.

Ara awọn iwa ipaniyan ọlọpaa laibikita yii si lo sokunfa iwọde Endsars to waye lọdun 2020 lati tako iwa ika awọn ọlọpa Naijiria.