Ọ̀pọ̀ èrò ya bo ilé Tinubu lọ́jọ́ Kérésì, ọmọ Nàíjíríà figbe ta

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Fidio kan to n ja ranyin-ranyin lori ayelujara bayii n ṣe afihan bi omilẹgbẹ awọn eeyan kan se to si iwaju ile oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu nilu Eko.
Ohun kan to n lọ lori fidio naa n sọ pe wọn wa tọrọ owo ni eyi si ti mu ki ọpọ ọmọ Naijiria maa sọ ẹhonu wọn lori rẹ.
Bi o tilẹ jẹ wi pe kii ṣe ohun tuntun mọ lati maa ri awọn eeyan ti wọn n to si iwaju ile awọn eekan lawujọ lawọn asiko ọdun bii Keresimesi, ọdun tuntun, ileya ati bẹẹbẹẹ lọ.
Sibẹ ọpọ to n sọrọ lori fidio naa lo n bu ẹnu atẹ lu igbe aye awọn mẹkunnu lorilẹede Naijiria to n buru si lojoojumọ.
Ero awọn eeyan kan si ni pe isẹlẹ yii lo n fun awọn to wa nipo kan tabi omiran lanfani lati tubọ maa jẹ gaba lori awọn mẹkunu.

Oríṣun àwòrán, Instagram/officialasiwajubat
Bi o tilẹ jẹ wi pe ko tii si ọrọ kankan lati ọdọ awọn agbẹnusọ fun Bọla Tinubu lori eyi, awọn ọlọpaa han ninu fidio naa nibi ti wọn ti n ṣọ awọn to n to naa.
Bi awọn kan ṣe n tabuku ohun to ṣẹlẹ ninu fidio naa pe ara awọn ọgbọn ti awọn oloṣelu maa n lo niyii lati rii pe awọn mẹkunu n ba buruburu lẹsẹ wọn.
Awọn miran n sọ pe o fihan pe oninure ati ẹlẹyinju aanu ni oludije naa ni.
Ki ni Tinubu sọ ninu ọrọ ikini ku ọdun keresimesi rẹ?
Amọṣa oludije fun ipo aarẹ orilẹede Naijiria labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC naa, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti rọ awọn ọmọ Naijiria lati fọwọsowọpọ, ki wọn si gba alaafia laaye fun iṣọkan orilẹede Naijiria.
Tinubu ni asiko arojinlẹ ni asiko Keresimesi jẹ fun awọn Kristẹni atawọn ti kii ṣe Kristẹni lati maa fi ifẹ han si Ọlọrun wọn atawọn ọmọlakeji wọn.
“Mo ki gbogbo awọn agbẹ, awn akẹkọọ, awọn oṣiṣẹ, awọn oniṣẹ ọwọ, awọn amuludun, awọn olukọ, awọn ọlọpaa, awọn iyalọja, awọn ologun, ati gbogbo ọmọ Naijiria lapapọ.”
Bakan naa lo tun ki gbogbo awọn ti wọn jijọ n dije fun ipo aarẹ pẹlu. O ni ko si bi iyatọ ṣe lee wa lori ilana oṣelu wọn, sibẹ Naijiria kan ṣoṣo naa ni wọn n ja a fun.















