Kí ló le mú kí òṣèré tíátà gbẹ̀mí ara rẹ̀ níbùdó tí wọn ti ń ya sinimá?

Oríṣun àwòrán, Tunisha Sharma/instagram
Awọn ọlọpaa tesan Waliv ti fi oṣere ilẹ India kan, Sheezan Mohammed Khan si atimọle, lati se iwadii boya o lọwọ ninu iku Tunisha Sharma, ọrẹbinrin rẹ tẹlẹri.
Tunisha Sharma lo n kopa ninu ere oniṣe 'Alibaba Dastan E Kabul' ṣaaju ki wọn to kede iku rẹ.
Nigbati awọn ayaworan n ya ọkan ninu awọn oṣere sinima naa 'Alibaba' lọwọ, ni wọn kẹfin pe Sharma, ẹniti o ti wọ yara baluwẹ tipẹ tipẹ, ko ti jade sita.
Lẹyin ti wọn ja ilẹkun yara baluwẹ ni wọn ri, ti wọn si gbiyanju lati doola ẹmi rẹ ki awọn dokita ile iwosan to fidi rẹ mulẹ pe o ti jade laye.
Iya Sharma, nigba to n ba awọn ọlọpa sọrọ ni ọrẹ kunrin ọmọ oun, Sheezan Khan, lo jẹ ki ọmọ oun gbẹmi ara rẹ.
Ninu ọrọ ti iya Sharma sọ, o ni ọmọ oun ati Sheezan jẹ ọrẹ wọle-wọde, ki aarin wọn to daru.
O fikun pe ifẹ ti ọmọ oun Sharma ni si ọrẹkunrin rẹ, Sheezan, lo jẹ ki o gbẹmi ara rẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
"A gbe Sharma lọ ile iwosan tori aisan arokan, o ni Sheezan fi ọbẹ ẹyin jẹ oun nisu"
Ile ẹjọ ti fi Sheezan si ẹwọn ọlọjọ mẹrin, ki awọn ile-iṣẹ ọlọpa le waadi iṣẹlẹ naa bo ti tọ ati bo se yẹ.
Ẹgbọn ologbe Tunisha, Pawan Sharma ni lati igba ti sinima 'Alibaba Dastan E Kabul' ti bẹrẹ, ni aburo oun ati oṣere Sheezan, ti di ọrẹ kori kosun.
O ni bi i ọjọ mẹwa ṣẹyin, ni wọn gbe Sharma lọ si ile iwosan latari aisan arokan.
O ni se ni Sharma sọ fun oun pe Sheezan fi ọbẹ ẹyin jẹ oun nisu, Pawan ni nkan ti ẹbi awọn fẹ ni ki ẹni ti o jẹbi fojuba ile ẹjọ.

Oríṣun àwòrán, _tunisha.sharma_/instagram
Ta ni Tunisha Sharma?
Tunisha Sharma jẹ ọmọ ogun ọdun, oṣere tiata agbelewo ni orilẹede India,
O ti kopa ninu sinima "Fitoor" eleyii to jade ni ọdun 2016, bẹẹ naa lo ti ṣere pẹlu oṣerebirin Vidya Balan ninu ere ti wọn pe ni Kahaani.
Oriṣiriṣi ere agbelewo ni Sharma ti kopa ninu rẹ bii,"Internet wala love, Ishq Suballah, Ghayab ati bẹẹ bẹẹ lọ.














