"₦900,000 ni mo fi rán ọmọ mi lọ fásitì kan ní Ghana, àṣé gbájú ẹ̀ ni"

Àkọlé fídíò, Quest University Ghana: Ìyá àti ọmọ bọ́ sọ́wọ́ gbájúẹ̀ fásitì torí ìyanṣẹ́lódì ASUU
"₦900,000 ni mo fi rán ọmọ mi lọ fásitì kan ní Ghana, àṣé gbájú ẹ̀ ni"

Quest University Ghana: Ìyá àti ọmọ bọ́ sọ́wọ́ gbájúẹ̀ fásitì torí ìyanṣẹ́lódì ASUU

Ọba oke jọọ mase jẹ ka bọ sọwọ alagbeda ni adura to yẹ ki gbogbo ẹbi maa gba lojoojumọ nitori oniruuru ọna lawọn ẹda kan fi n lu jibiti bayii.

N jẹ ẹ mọ pe awọn gbajuẹ tun n lu jibiti lilọ ile ẹkọ fasiti bayii?

Bi ẹ ko ba mọ, ẹ wa gbọ iriri mọlẹbi kan to bọ sọwọ awọn onibiti to wa ni Ghana, ti wọn si gba obitibiti owo lọwọ wọn.

Isẹlẹ yii si ni o ti n di lemọlemọ bayii, paapaa nilu Ibadan, tii se olu ilu ipinlẹ Oyo nibi ti ọpọ obi ti bọ sọwọ awọn gbajuẹ tori iyansẹlodi ẹgbẹ olukọ fasiti ni Naijiria.

Akẹkọọ, iya rẹ ati ẹgbọn akẹkọọ

Osu marun ni mo fi wa ni ahamọ awọn gbajuẹ, mama mi ro pe fasiti ni mo wa ni Ghana - Akẹkọọ

Akẹkọọ kan to bọ sọwọ awọn onijibiti to n tan awọn ọmọ Naijiria lati wa si ileẹkọ fasiti ni Ghana salaye ohun ti oju rẹ ri ati bi isẹlẹ naa se waye fun BBC Yoruba.

Akẹkọ ọhun, ta fi orukọ bo ni asiri salaye pe akoko ti iyansẹlodi awọn olukọ ileẹkọ fasiti ni Naijiria n waye, to si ti n pẹ ju, ni oun bọ sọwọ awọn onijibiti naa.

Akẹkọọ naa ni oun ti wa ni fasiti kan lorilẹede Naijiria amọ iyansẹlodi ẹgbẹ ASUU ti mu ki ile su oun, to si tun n fi akoko oun sofo, ni oun ba ni ki oun da bi ọgbọn.

O ni ọrẹ oun kan lakoko iyansẹlodi ASUU naa, lo wọ ileẹkọ Quest University ni Ghana, to si n ransẹ pe oun pe ki oun naa maa bọ wa sile ẹkọ naa.

O salaye pe lara ọrọ to fi tu oun loju ni pe ọdun kan soso ni oun yoo lo ni Ghana, ti wọn yoo si ko awọn lọ si oke okun lati lọ pari iwe awọn.

"Idi ree ti mo fi sọ fun mama mi nipa igbesẹ naa, ti wọn si fara mọ, apapọ owo ta si san fun owo ẹkọ ati owo baalu to gbe mi lọ si Ghana jẹ ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrun naira.

"Inu ile kan ni wọn fi wa pamọ si laisi ounjẹ tabi ibusun, ahamọ ni mo wa fun osu marun"

Akẹkọọ naa tẹsiwaju pe ẹnu ya oun nigba ti oun de si Ghana, ti wọn si wa pade oun ni papakọ ofurufu.

O ni wọn gbe oun lọ sinu ile kan to jẹ ile ilẹ, ti oun si dara pọ mọ ọpọ awọn akẹkọọ to ti wa ni ahamọ nibẹ.

"Orukọ ile ẹkọ fasiti tawọn gbajuẹ naa fi boju lati tan mi wa ni wọn pe ni Quest University, AD-245-2430 si ni koodu rẹ.

Agbegbe Kejetia to wa nilu Kumasi si ni adirẹsi tawọn gbajuẹ n lo pe ile ẹkọ fasiti Quest naa wa.

Ori ilẹ la n tẹ asọ si lati sun, wọn gba gbogbo owo ti mo ko de ibẹ, owo diẹ ni wọn sẹ ku fun mi lati jẹun.

Gbogbo asọ tuntun ti mama mi ra fun mi lati ko wa si Ghana ni wọn gba, ti n ko si ri ounjẹ ẹẹmeji jẹ lojumọ.

Mo ru kan egungun, ti n ko ni anfaani lati salaye fun mama mi nipa oun to n sẹlẹ si mi nitori awọn onijibiti naa maa n wa pẹlu wa ta ba fẹ gba ipe lori foonu.

Nibẹ ni mo si ti ri pe wọn maa n ko diẹ lara wa diẹ diẹ ni aarin oru l silu Port-Novo, lọ silẹ Libya lati lọ fi wọn se ẹru tabi ta ẹya ara wọn.

Ọlọrun ọba ati mama mi lo jẹ ki n mori wale , akoko ti mo pada wọle naa si ni ASUU fopin si iyansẹlodi wọn, ti mo si pada sile ẹkọ mi ni Naijiria."

Ori redio kan ni mo ti gbọ pe eke fasiti ni ọmọ mi wa ni Ghana - Mama Akẹkọọ

Nigba ti oun naa n ba BBC Yoruba sọrọ nipa bi ori se ko ọmọ rẹ yọ lọwọ awn onijibiti to tan lọ si Ghana, mama akẹkọ naa ni isẹlẹ naa buru jai.

O ni oun lọ ya owo tuulu, ti apapọ rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrun naira (₦900,000) lati ran ọmọ lọ sile ẹkọ ni Quest University, Ghana lai mọ pe gbajuẹ lasan ni.

Mama akẹkọ naa ni bi o tilẹ jẹ pe oun si n san gbese naa lọwọ lyin ti ọmọ oun pada de amọ oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ẹmi ọmọ oun ko bọ sinu isẹlẹ naa.

"Lẹyin ti ọmọ mi de Ghana, nigba to de bii osu marun, ni wọn seto kan lori redio, ti awọn eeyan kan to kopa ninu rẹ si sọ iriri bi wọn se bọ sọwọ awn onijibiti ni Ghana.

Wọn darukọ fasiti ti ọmọ mi wa ni Ghana pe awọn onijibiti lo fi n tan eeyan jẹ lati igba naa si ni ọkan mi ko ti balẹ mọ.

Mo fi ọrọ naa to ẹgbọn rẹ leti, ta si bẹrẹ si ni se iwadi nipa fasiti naa, to si ba wa lọkan jẹ pe ko si fasiti to n jẹ orukọ bẹẹ nilẹ Ghana.

Lati igba naa la ti n gbinyanju lati pe ọmọ mi pada sile sugbọn wọn ko jẹ ko da wa lohun, ọpẹlọpẹ adura ni wọn se fi silẹ lọjọ kan."

Bakan naa ni ẹgbọn akẹkọọ naa ba BBC Yoruba sọrọ, to si mẹnuba ipa to ko lati jẹ ki aburo rẹ bọ lọwọ awọn onijibiti to fi si ahamọ lorilẹede Ghana.