Àwọn gbajúmọ̀ tó ṣe ìgbéyàwó lọ́dún 2022

Aworan awọn igbeyawo mẹta kan

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/@MERCYCHINWO/@TIMGODFREYWORLD/@CHIOMAKPOTHA

Lagbo igbeyawo lọdun 2022, awọn gbajumọ ilumọọka lorilẹede naa ni awọn asiko ayọ igbeyawo tiwọn pẹlu.

Ọpọ ẹbi ara ati ọrẹ lo peju ba ọpọ awọn gbajumọ to jẹ ololufẹ wọn dawọ idunnu agogo isopọ to lu lọdẹdẹ wọn lọdun 2022.

Diẹ lara awọn eekan gbajumọ to ṣe igbayawo lọdun 2022 lorilẹede Naijiria niwọnyii:

Rita Dominic pẹlu Fidelis Anosike

Rita Dominic ati ọkọ rẹ Anosike

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/@RITADOMINIC

Gbajumọ oṣere tiata Nollywood, Rita Dominic pẹlu gbajumọ alakoso ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ, Fidelis Anosike so yigi ifẹ wọn loṣu kẹrin ọdun 2022.

Ayẹyẹ Idana wọn waye ni Aboh Mbaise to jẹ ilu Rita Dominic ni ipinlẹ Imo, lẹkun ila oorun gusu Naijiria.

Nigba to di ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2022 ni wọn ṣe igbeyawo igbalode wọn ni Selby Abbey, North Yorkshire lorilẹede England.

Lara awọn ẹbi ara ati ọrẹ to wa nibi ayẹyẹ igbeyawo naa ni Kate Henshaw, Chioma Akpotha, Tokẹ Makinwa, Michelle Dede atawọn eekan ilu miran.

Kẹmi Adetiba ati Oscar Heman-Ackah

Kẹmi Arotiba ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/@KEMIADETIBA

Gbajumọ oludari ati olotu sinima agbelewo, Kẹmi Adetiba ati gbajumọ ọmọ Ghana kan, Heman-Ackah gbe ara wọn niyawo loṣu kẹrin ọdun 2022.

Lara awọn to wa nibi ayẹyẹ igbeyawo wọn ni Ṣọla Ṣobọwale, Banky W ati iyawo rẹ Adesua Wellington, Ebuka Obi-Uchendu atwọn miran.

Tim Godfrey ati Erican Katrina Jones

Tim Godfrey ati iyawo rẹ Erica Katrina Jones

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/@TIMGODFREYWORLD

Gbajumọ akọrin ẹmi, Tim Godfrey gbe ololufẹ rẹ, Erica Katrina Jones niyawo ni Culpeper, VA lorilẹede Amẹrika loṣu kẹrin ọdun 2022.

Awọn eekan to wa nibi ayẹyẹ igbeyawo naa ni Phil Thompson, Todd Dulaney ati Dee Jones.

Loṣu kẹfa ni wọn wa ṣe eto idana wọn.

Tim Godfrey fi fidio kan nipa igbeyawo rẹ naa sori ayelujara Instagram rẹ pẹlu akọle

“Mo ṣeleri lati fẹ ọ titi aye ati nigba gbogbo!”

Mercy Chinwo ati Blessed Uzochikwa

Mercy Chinwo ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/@MERCYCHINWO

Gbajumọ akọrin ẹmi, Mercy Chinwo ati afẹsọna rẹ, Pasitọ Blessed Uzochikwa ṣe igbeyawo wọn loṣu kẹjọ ọdun 2022.

Eyi waye lẹyin ti gbajumọ akọrin ẹmi naa ti kọkọ ya awọn ololufẹ rẹ lẹnu lọjọ kẹtalelogun oṣu kẹfa ọdun 2022 nigba to kede irinajo ifẹ laarin oun ati Blessed Uzochikwa to jẹ oluṣọaguntan ijọ Waterbrook Church nilu Eko.

Awọn eekan ilu to wa nibi ayẹyẹ igbeyawo naa ni banky W, Adesua Wellington, Waje, Chigurl, Joe Praize atawọn miran.

MI Abaga ati Ẹniọla Mafe

MI ati ololufẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/@ENIOLAMAFE

Gbajumọ akọrin takasufe, Jude Abaga ti ọpọ mọ si MI ṣe igbeyawo pẹlu ololufẹ rẹ Ẹniọla Mafe ni oṣu kẹsan an ọdun 2022.

Ọjọbọ, ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹsan an ni wọn ṣe idana wọn.

Awọn ilumọọka to wa nibi ayẹyẹ igbeyawo wọn ni Banky W, IK Osakioduwa, Basketmouth, Jesse Jags atawọn miran.