Wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré Yorùbá tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yà míì àti orílẹ̀èdè míì

Awọn Oṣere

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Lagbo oṣere Yoruba, ẹ o le ṣai ma gbadun oniruuru nnkan to maa n waye, latori awọn fiimu wọn titi de awọn iroyin ati iṣẹlẹ nipa igbe aye wọn ti ko farapamọ fun araalu.

Ara ọtọ ni agbo Tiata Yoruba to bẹẹ to jẹ wipe ẹ ko tilẹ le kọkọ maa wa ilu ibi ti eeyan kan ti wa tori ọpọlọpọ wọn lo dantọ ninu oniruuru iṣẹ wọn.

Koda o fẹ to bẹẹ to faaye gba ẹnikẹni lati maa kopa ti awọn to n ṣe iṣẹ miran gan tun n fi iṣẹ Tiata kun iṣẹ wọn ti wọn si tun ko ipa oniruuru ninu aye awọn ololufẹ wọn.

Agba iyalẹnu ibẹ ni pe ko tun ki n ṣe dandan ki awọn oṣere naa wa lati ilu Yoruba kan pato, kikii ki wọn ṣaa ti mọ iṣẹ daadaa ki wọn si lee sọ ede to da gbogbo wọn papọ.

Lorilẹede Naijiria, ọpọlọpọ oṣere ti ko wa lati ẹya kan pato wa lara awọn to n gberi gan nibẹ. Wọn ti bẹrẹ tipẹ ti ẹsẹ wọn si ti mulẹ. Lara wọn ni:

Oṣere

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Faithia Williams

Fathia Balogun

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Odu ni Fathia Williams kii ṣe aimọ fun oloko lagbo oṣere Yoruba amọ ọpọ ni ko mọ rara pe kii ṣe ọmọ Yoruba.

Urhobo ni ipinlẹ Delta ni Fathia ti wa amọ o ti goke agba ninu agbo fiimu Yoruba to bẹẹ ti ọpọ n kọ iṣẹ latara rẹ.

O fi igba kan jẹ iyawo ile gbajumọ oṣere mii, Saidi Balogun amọ wọn ti tuka.

Ibrahim Chattah

Ibrahim Chattah

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ko si ẹni to lee fọwọ rọ Ibrahim Chattah sẹyin lagbo oṣere Yoruba tori bo ti wu ko ri, o ti ṣe iṣẹ rẹ silẹ.

O n kọrin, o n dari ere, o n kọ ere. Chattah bẹrẹ ere itage gẹgẹ bi ọdọ langba to si ti lo ọpọlọpọ ọdun lagbo oṣere Yoruba bayii.

Bi o ṣe wa gbọ ede Yoruba to to si n lo ninu iṣẹ, ọmọ bibi ẹya Nupe ni Chattah, wọn bi i ninu Oṣu Kẹwa Ọdun 1970 eyi to tumọ si pe o ti pe ọdun mejilelaadọta lọdun 2022.

Regina Chukwu

Regina Chukwu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Regina Chukwu jẹ ọmọ ipinlẹ Enugu amọ ti wọn mọ ọ fun ọpọlọpọ ipa to ti ko ninu fiimu Yoruba to si ti di gbajugbaja laarin wọn ju awọn ọmọ Yoruba mii gan lọ.

Agbegbe Iyana Ipaja ni Eko ni wọn ti bi Regina ni Eko lọdun 1980 amọ ọmọ Enugu lawọn obi rẹ.

Regina ka ile ẹkọ Girama ni Alimosho Grammar School to si pada ka ẹkọ giga ni ile ẹkọ gbogboniṣe ti ipinlẹ Eko.

Ẹni ọdun mejilelogoji ni Regina. Ọdun 2003 ni Regina darapọ mọ awọn oṣere to bẹrẹ gẹgẹ bii aṣoju loge.

Bo tilẹ jẹ ọmọ Igbo, ọpọlọpọ fiimu rẹ lo jẹ ede Yoruba.

Kelvin Ikeduba

Kelvin Ikeduba

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ọmọ ipinlẹ Delta ni oṣere Kelvin Ikeduba amọ to ti di eeyan nla sinu agbo fiimu Yoruba nigba to kọkọ kopa ninu ere lọdun 2000.

Kia lọdun 2014, o ti gba ami ẹyẹ Oṣere to wa lati ẹya mii.

Toyin Abraham

Toyin Abraham

Oríṣun àwòrán, OTHERS

“World Best” tabi “Queen of Box Office” wa lara awọn inagijẹ ti wọn maa n pe gbajugbaja oṣere Toyin Abraham.

Olutoyin Aimakhu gangan ni orukọ abisọ rẹ, wọn si bii ni ilu Auchi ni ipinlẹ Edo ṣugbọn o lo igba kekere rẹ ni ilu Ibadan to si tun dagba si ilẹ Yoruba.

Lọdun 2013 ni Toyin di gbajumọ lagbo oṣere nigba to kọkọ gba ami ẹyẹ funipa to ko ninu ere “Ebi mi ni”. O wa lara awọn ti wọn n pe ni ni to mọ iṣẹ rẹ daadaa bayii lagbo oṣere.

Orukọ ọkọ rẹ ni Kolawole Ajeyemi ti oun naa jẹ oṣere Yoruba ti wọn si ni ọmọ kan papọ.

Rachael Oniga

Oloogbe Rachael Oniga

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ilu Eku ni ipinlẹ Delta ni gbajumọ oṣere to ti di oloogbe bayii, Rachael Oniga ti wa to si jẹ oju mimọ lagbo awọn oṣere elede Gẹẹsi ati ti Yoruba.

Oniga gbọ ede Yoruba de bi pe o n ṣe ere abule.

Fiimu Yoruba to gbe e jade ni “Owo Blow” lọdun 1993.

Clarion Chukwura

Clarion Chukwura

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Clarion Chukwura jẹ ọmọ ipinlẹ Anambra to si maa n kopa ninu fiimu Yoruba ati ti Ede Gẹẹsi naa daadaa.

Liz DaSilva Elizabeth Tekovi Da-Silva

Liz Da Silva

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Liz DaSilva kii ṣe ọmọ Naijiria raa, ọmọ ilẹ Togo ni amọ o n ko ipa gidi ninu fiimu Yoruba. Lọdun 2016, o gba ami ẹyẹ City People Movie Award. O si n kopa ninu ọpọlọpọ ere tiata Yoruba.

Adunni Ade

Adunni Ade

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Inu Oṣu Kẹfa Ọdun 1976 ni wọn bi gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba to n jẹ Adunni Ade.

Adunni Adewale gangan ni orukọ rẹ amọ pẹlu irisi rẹ, ọpọlọ n ro o pe kii ṣe ọmọ Yoruba.

Bẹẹ ni, Adunni Ade ko fi gbogbo ara jẹ ọmọ Yoruba tori pe ọkan lara awọn obi rẹ jẹ ọmọ orilẹede Germany.

Ẹwẹ, Adunni Ade jẹ ọkan lara awọn arẹwa oṣere obinrin ti awọn eeyan fẹran lati maa wo fiimu to ba ti kopa gidi gan.

Lara awọn oṣere mii ti kii ṣe ọmọ Yoruba amọ ti wọn ti mọ ile saarin awọn oṣere Yoruba ni: Mercy Aigbe Rose Odika Nkechi Blessing Doris Simeon Rykardo Agbor