Yekini Ajileye lo gbe èmi Tamotiye, Abeniagbon àti Akeekee síta nígbà náà- Alirat Atowule

Àkọlé fídíò, Yekini Ajileye lo gbe èmi Tamotiye, Abeniagbon àti Akeekee síta nígbà náà

Ẹja tí kò gbọ́njú mọ ìyá rẹ̀ àti ọbẹ̀ ìgúnpa ni àwa eèyàn 30 tó jọ n sun ìyará ń jẹ́ lọ́dọ̀ọ́ Alhaji Ajileye nígbà náà.

Alirat Atowule ti ọpọ mọ si Tamotiye ni agba oṣere lati aye ere itage pẹlu awọn agba ọjẹ bii Alhaji Yekini Ajileye, Abeni agbon, Akeekee, Oyiboyi ati Koledowo.

O royin diẹ lara ohun oju ri ki oṣere yii to goke agba bayii.

Tamotiye sọrọ nipa irinajo aye rẹ lati ibẹrẹ niagb to n kọ iṣẹ owo amunidara aranṣọ titi de inu iṣẹ oṣere.

Tamotiye

Bakaa naa lo gab awọn oṣegbe akegbe rẹ lati maa ṣora ṣe lai sare kọja kadara ki wọn ma lọ sare mọto fi kọlu kẹkẹ.

O tun ni ki wọn maa kọ ololufẹ won lékọ iwa omoluwabi pẹlu iwa rere.