Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, Iyabo Ojo fojú olólùfẹ́ rẹ̀ hàn

Iyabo Ojo ati Paul Okoye

Oríṣun àwòrán, Iyaboojofespris

Gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba, Iyabo Ojo ti ṣi aṣọ loju ẹnibiọkan rẹ to n fi owe sọrọ nipa rẹ lati ọjọ yii.

Bi o ṣe n ṣe ayẹsi ayajọ ọjọ ibi ọdun karundinlaadọta ti o pe loke eepẹ lo ṣe ikede yii lati ṣaami ọjọ ibi rẹ to si fi oju ololufẹ rẹ han fun araye.

Ninu atẹjade to fi sita, Iyabo Ojo fi fọto oun ati Oludasilẹ ati adari ileeṣẹ Upfront and Personal Management, Paul Okoye ti ọpọ mọ si “Paulo” han sita gẹgẹ arakunrin to ti n da lọrun lati ọjọ yii.

Lọpọ igba ṣaaju ọjọ ibi rẹ ni oṣerebinrin yii ti maa n bun awọn araalu gbọ diẹ diẹ pe “iyawo Igbo” ni oun to si ṣeleri lati fi oju rẹ han nigba ti akoko ba to.

O wa jọ pe lakoko ọjọ ibi rẹ gaan ni akoko to to si ọpọ fidio ati aworan oun ati Paulo hande loju opo Instagram rẹ.

"Ezenwanyi mi - Olori gbogbo awọn obinrin"

Iyabo ati Paulo

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ninu akọle to kọ sori awọn nnkan to fi sita yii ni bi o ṣe Paulo ni “Obim”, eyi tii ṣe ede Igbo to tumọ si “ọkan mi” lede Igbo.

Eyi to wa dee lade gaan ni ti oju opo Instagram ti Paulo funrarẹ to ti ṣe ayẹsi ololufẹ rẹ ẹni to juwe gẹgẹ bii “Ezenwanyi, itumọ eyi to jẹ “Olori gbogbo awọn obinrin” lede Igbo.

Paulo fi fọto oun ati Iyabo Ojo sita to si kọ akọle pe “O ku ayẹyẹ ọjọ ibi “Ezenwanyi” mi. A ba ẹ yọ lonii. Asiko wẹjẹwẹmu dee... Ọkan to mọ! Ẹwa to mọ!”

Odu ni arakunrin yii naa, Paulo laarin awọn olorin ati gbajumọ adanilaraya. O maa n ṣiṣẹ pẹlu ọpọlọpọ wọn bii Marie Chike to kopa ninu eto agbelewo Big Brother Naija, Olorin Kizz Daniel ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ọpọlọpọ awọn gbajumọ ati ololufẹ rẹ lo ti n ki Iyabo Ojo ku oriire bo ṣe fi oju ọkọ afẹsọna rẹ han.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ololufẹ mejeji yii ko tii sọ pato igba ti ifẹ wọn bẹrẹ, laipẹ yii ni Iyabo Ojo ti maa n sọrọ nipa ibaṣepọ wọn eyi to bẹrẹ si ni sọrọ nipa rẹ nibẹrẹ Oṣu Kọkanla.

O ni “Ọmọkunrin Igbo yii ti gba gbogbo ọkan mi so”.

Bakan naa lo ti sọ fun awọn oniroyin pe oun ni afẹsọna ti awọn yoo si to ṣe igbeyawo.

O ti sọ ri fun awọn oniroyin pe: “Bẹẹ ni mo fẹ dan igbeyawo wo, mo ti yo ifẹ. O ni ọmọkunrin Igbo kan lapa ibi kan to ti ji ọkan mi lọ.”

Ta ni Paul Okoye to gba ọkan Iyabo Ojo so?

Iyabo ati Paulo

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gbajumọ adanilaraya ni Paul Okoye to si tun jẹ apolongo eto tabi iṣẹ ọpọlọ bii orin.

Oun ni Ọga agba ati oludasilẹ ileeṣẹ “Upfront and Personal Management” ti wọn n ṣiṣẹ nipa fiimu, orin, ere idaraya ati idanilaraya. O maa n ba ọpọ gbajugbaja ṣiṣẹ ni Naijiria ati kaakiri Afirika.

Bakan naa, Paulo ni o ṣe agbekalẹ akanṣe eto idaranilaraya kan, “One Africa Music Fest,” ti wọn maa n ṣe lọdọọdun lati ṣe ayẹsi ẹka orin Afrobeat.