Gómìnà Adeleke gbé ìgbìmọ̀ kalẹ̀ fún pínpín ìrẹsì ọdún l'Osun

Aworan gomina Adeleke pẹlu akojọpọ awọn apo irẹsi

Oríṣun àwòrán, twitter/Adegboyega oyetola/ademola adeleke

Àkọlé àwòrán, Apo irẹsi to wa ninu aworan yii kii ṣe eyi ti Adeleke fẹ pin o

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke ti gbe igbimọ kan kalẹ fun pinpin irẹsi ọdun fun awọn eeyan ipinlẹ naa.

Gẹgẹbi atẹjade kan ti agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Ọṣun, Rasheed Ọlawale gbe sita, eto pinpin irẹsi naa ko niiṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu tabi ilu tabi ohunkohun.

Ijọba ipinlẹ Ọṣun ni ogoji apo irẹsi ti iye ọkọọkan rẹ jẹ naira mejilelọgbọn (N32, 000) ni wọn yoo pin fun wọọdu kọọkan.

Pẹlu agbekalẹ eto idibo ipinlẹ Ọṣun to kọja, wọọdu ọdunrunlemejilelọgbọn lo wa ni ipinlẹ Ọṣun.

Eyi tumọ si pe ẹgbẹrun mẹtala ati ọrinlelugba (13,280) apo irẹsi ni ijọba ipinlẹ Ọṣun fẹ pin.

Awọn wo lo wa ninu igbimọ naa?

Atẹjade naa ko sọ igba ti pinpin irẹsi naa yoo bẹrẹ ni ipinlẹ naa.

Awọn meje ti yoo wa ninu igbimọ naa ni:

  • Ọmọ igbimọ awọn Imaamu nipinlẹ Ọṣun
  • Ọmọ ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi, Can
  • Ọmọ ẹgbẹ ẹlẹsin abalaye kan
  • Ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP kan
  • Ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC kan
  • Oṣiṣẹfẹyinti kan
  • Ati aṣoju awọn obinrin kan