Germany ti dá àwọn ohun ìsẹ̀ǹbáyé Benin tí wọ́n kó lọ ní ayé àtijọ́ padà fún Nàìjíríà.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Minisita fun Ilẹ okeere ti Germany Annalena Baerbock ti gbẹ awọn ohun-ọṣọ ogun ti wọn jigbe ni ọdun pipe pada si Nigeria ni ayẹyẹ kan ti o waye ni olu ilu Naijiria,Abuja.

Idapada awọn ohun idẹ iyebiye yii ko ṣẹyin adehun kan ti ijọba orilẹ-ede yii ati orilẹede Germany ni nii ibẹrẹ ọdun yii nibiti ti wọn o ti da ẹgbẹrun kan awọn ere iyebiye pada si orilẹ-ede Naijiria.

Ninu Oṣu Keje ọdun yii ni adehun na waye ti o si jẹ igba akọkọ ti orilẹ-ede Yuroopu se iru adehun naa.

Ms Baerbock sọ pe ibaṣepọ yii je awọn igbiyanju orilẹ-ede Germany lati paa awọn itan iwa imunisin tọ waye tẹlẹri rẹ.

Lara awọn ohun ti wọn da pada ni ̀ ori ere iyebiye ti ilu Benin ati awọn ere to gbajugbaja ni ilu Benin.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ere idẹ Benin n tọka si ẹgbẹẹgbẹrun awọn ere idẹ, awọn okuta iranti ati awọn ohun-ọṣọ ti a ṣe laarin 15th Century àti 19th century ti awọn ọmọ ogun Ilu Gẹẹsi ti ji ni ọdun 1897 ni ilu Benin, ni ipinlẹ Edo.

Awọn ere idẹ wọnyi ni wọn jẹ ohun elo pataki fun awọn ara ilu Benin. Lati 19th Century ni wọn ti ko wọn lọ sí ile gẹẹsi ti awọn oniṣowo ìle Germany ra ọpọlọpọ awọn idẹ iyebiye naa.

Ninu atẹjade ti ẹka to n risi awọn ohun-ọṣọ ti Orilẹ-ede Naijiria filede kesi awọn ilu ti wọn ni awọn ohun ọṣọ idẹ wọnyi lati da wọn pada.

Ni ọdun 2026, ijọba ilu Benin n gbero lati si gbangan ibi ti awọn akojopo ohun ọsọ iyebiye yoo wa fun wiwo awọn araalu ti ayaworan lati ilu Ghana David Adjaye wa nidi yiya aworan ile naa.